Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sàfihàn Alfa tó dúnkokò mọ́ àwọn Oníṣẹ̀ṣe nílùú Ilorin

Alfa Ayodeji Salah

Ileeṣẹ Olopaa ipinle Kwara ti ṣafihan Alfa Ayodeji Salah ti wọn fẹsun kan pe o dunkoko mọ awọn Onisẹẹṣe kan ni ile itaja wọn.

Iwadi wa fidi rẹ mulẹ pe awọn mọlẹbi ọmọkunrin yii lo wa a jade, ti wọn si lọ fa a le ọlọpaa lọwọ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu yii.

Ninu iforowanilenuwo, Salah Ayodeji rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ Naijiria wi pe ki won dariji oun, o ni oun ko mọ pe ọrọ naa maa di bayii.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ni ọjọ diẹ sẹyin ni iroyin jade pe ileeṣẹ ọlọpaa n wa arakunrin yii tori pe o korajọ pẹlu awọn Alfa mii ni Ilorin lati lọ fi tipatipa le arakunrin Tajudeen ati iyawo rẹ kuro nibi ti wọn ti n ta ọja tori wọn ni pe wọn n ṣe iṣẹṣe nibẹ.

bakan naa ni Alafa Ayodeji tun ni ki awọn to gba ṣọọbu lọwọ wọn naa le e danu ki wọn ma jẹ ko lo ibẹ mọ.

Ẹwẹ, nibi ti ọlọpaa ti n fi oju rẹ han lẹyin ti ọwọ tẹ ẹ, o fikun un pe ija ẹsin ko ni itumo rara ṣugbọn a nilo ifẹ pẹlu ọmọlakeji.

Bakan naa ni o tun rawọ ẹbẹ si Ọgbẹni Tajudeen, ẹni to pe ni ọrẹ rẹ wipe ki o dariji oun, pe oun kan wa lati fa a leti ni lai mọ pe ibi to maa ja si niyi.

Tajudeen, to jẹ Musulumi, ninu ọrọ rẹ bẹ awọn ọmọ Naijiria pe ki wọn ba oun bẹ idile Ayodeji Salah pe ki wọn fi oun lọrun silẹ.

O fi kun un pe oun mọ pe oniṣeṣe ni iyawo oun lootọ ti oun naa si mọ nipa awọn nnkan Yoruba bo tilẹ jẹ pe Musulumi ni oun, o ṣalaye pe eniyan le sin ẹsin to ba wu u nitori Eledumare ni yoo ṣe idajọ, kii ṣe eniyan.

Ki lo sẹlẹ ṣaaju?

Lọjọ Aje ọṣẹ yii, ni CP Ẹbunoluwarotimi Adelesi, kede Sala Ayọdeji, to lọ dunkooko mọ Tajudeen ati iyawo rẹ ni ṣọọbu ti wọn ti n ta Tẹlifiṣan lagboole Alaran, niluu Ilọrin pe awọn n wa a.

Lara ọrọ idukoko to sọ fun wọn to da rogbodiyan naa silẹ ni, "ma wa ibi mọ, tẹẹ ba fẹ ṣe mitinni, ẹ kọja si jinna rere re.

Ẹyin ile Alaran, ẹ le wọn kuro nibi, ẹ sanwo wọn fun wọn o, Ọlọrun kẹ ẹ yin ju kẹẹ maa gba iru owo ṣọọbu bayii lọ, ẹ le wọn kuro nibi, taa ba ba wọn nibi lọjọ mẹjọ, ko ni rọrun o".

Bakan naa lo tun sọ pe: "Kọmisana Ileeṣẹ Ọlọpaa mọ si gbogbo ohun ta n ṣe yii, gbogbo irin-ajo yin la ti mọ, ẹ kuro nibi, ẹ maa lọ sẹyin ilu, taa ba ba yin nibi lọjọ mẹjọ, bi awa la nilu ni, bi ẹyin lẹ nilu ni, ẹ jẹ ka jọ dan-an wo.

Emi Sala Ayọdeji, lo ni a o gbọdọ ba yin nibi lọjọ mẹjọ ."

Ni bayii, Alfa naa ti wa lakata awọn ọlọpaa.