Ta ni Afolabi Ghandi Olaoye, pásítọ̀ ìjọ Redeemed tí Seyi Makinde kéde gẹ́gẹ́bi Soun Ogbomosho tuntun?

Oríṣun àwòrán, others
Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ti buwọlu Ọmọọba Afolabi Ghandi Olaoye gẹgẹ bii Soun ilu Ogbomoso.
Iroyin to jade lati ọfiisi gomina ipinlẹ Oyo sọ pe lati Ọjọbọ to lọ ni Makinde ti fi ontẹ lu Ọmọba Olaoye gẹgẹ bi ori ade tuntun ilu Ogbomoso.
Kọmoiṣọnna fun ijọba ibilẹ àti ọrọ oye jijẹ nipinlẹ Oyo, Họnọrebu Olusegun Olayiwola ṣalaye ninu atẹjade ti kọmiṣọnna eto iroyin ati ilanilọyẹ, Ọmọba Dotun Oyelade buwọ́lu pe Makinde gbe igbesẹ yii lẹyìn ayẹwo tó waye labẹ ofin.
Họnọrebu Olayiwola sọ pe Makinde ti ki Ghandi kú oriire leyin to buwọlu iyansipo rẹ tan.

Oríṣun àwòrán, others
O ni iyansipo Ghandi gẹgẹ bii Soun tuntun ilu Ogbomoso jẹ ọna lati mu iṣọkan ati igbọra ẹni ye múlẹ sii laarin awọn eeyan ilu Ogbomoso.
Bakanna ni kọmiṣọnna naa rọ awọn eeyan ilu Ogbomoso lati ṣiṣẹ pọ pẹlu Soun tuntun bi o ṣe n gori apere awọn baba nla rẹ.
Lọjọ Abamẹta, ọjọ keji oṣu kẹsan an ni iroyin kanti kọkọ jade pe o ṣeeṣe ki Makinde ti fontẹ lu Ghandi gẹgẹ bii Soun tuntun.
O ti le ni ọdun kan ti Soun ana, Ọba Jimoh Oladuni Oyewumi, Ajagungbade kẹta ti waja.
Lati igba naa ni gbọnmi sii, omi o to ti n waye laarin awọn idile ọlọba niluu Ogbomoso lori ẹni ti ọba kan.















