Olúbàdàn dá ìlẹ̀kẹ́ oyè padà fún Mọ́gàjí tí wọ́n rọ̀ lóye

Mogaji

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun ti darijin Oloye Olawale Oladoja, Mogaji ti wọn rọ loye lori aawọ ilẹ ni agbegbe Labi, nilu Akinṣọla n'ijọba ibilẹ Akinyẹle, ipinlẹ Ọyọ lẹyin ọsẹ meji ti wọn ti gba ilẹkẹ lọrun Mogaji naa.

Ikede lati da ilẹkẹ pada fun Mogaji naa waye lẹyin ipade ti awọn aṣoju igbimọ Olubadan ṣe pẹlu rẹ ni aafin Olubadan ti ilẹ Ibadan.

Laipẹ yii ni iroyin gbode wi pe Oloye Oladọja ko awọn agbofinro lẹyin lọ si Labi nilu Akinṣọla, nibi ti wọn ti sọ agadagodo si awọn ile ati ilẹ ti o le ni igba lori ẹsun wi pe gbogbo wọn ra ilẹ naa lọna aitọ, eyii lo mu ki ile ẹjọ paṣẹ wi pe ki wọn lọ sọ asọyepọ pẹlu idile ti oni awọn ilẹ naa pẹlu atilẹyin ofin.

Wọn ti fi ọrọ yii to Olubadan leti ki o to di pe Mogaji ko awọn eeyan lẹyin lati lọ ti awọn ile naa pa. Igbesẹ ti Mogaji gbe lai duro de ọna ti Olubadan fẹ gbe ọrọ naa gba lo mu ki Ọba Balogun da sẹria fun un.

Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ lẹyin ti wọn daa pada si ipo, Oloye Olawale Oladoja dupẹ lọwọ ẹbi ati ara fun aduroti wọn lasiko ti rogbodiyan naa ṣẹlẹ, pẹlu alaye wi pe oun yoo tẹsiwaju lati maa tẹwọgba alaafia ati itẹsiwaju ilẹ Ibadan.

A kan si awọn ti Oloye Oladoja le kuro ni agbegbe naa lati mọ iha ti wọn kọ si igbesẹ Olubadan, ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa, Arakunrin Mouroof Adeogun ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe gbogbo awọn ti Mogaji le kuro nile ti pada si ile wọn pẹlu aṣẹ Olubdan.

O ni Olubadan ti paa laṣẹ fun Mogaji naa pe ko gbudọ dun koko mọ awọn olugbe agbegbe naa mọ. Adeogun fi kun ọrọ rẹ wi pe lati igba ti Olubadan ti pa aṣẹ naa ni onikaluku wọn ti padi si ile. Gbogbo agadagodo to n bẹ ni ẹnu ọna ile wọn si ni wọn ja kuro.

O ni, "Nigba ti o jẹ pe Ọba lo nilẹ ati ile ati oko. Ọba si ba lori ohun gbogbo ni.

Wọn ti fun un ni gbedeke, oun naa si i tọwọ bọ iwe nibẹ pe oun ko ni da ẹni kankan wa laamu mọ".

Mogaji

Oríṣun àwòrán, OTHERS