Àlàyé lórí bí ayẹyẹ ọdún Ọlọ́runbọrùn Udiroko ṣe lọ lónìí rèé nílùú Ado-Ekiti

Oríṣun àwòrán, bbc
Gómìnà Ekiti nigba kan ri, Ayodele Fayose ati gómínà ipinlẹ Gombe tẹlẹ, Ibrahim Dankwambo tí wọn jẹ ọkan lára àwọn olóyè Ado náà wá níbi ayẹyẹ Ọdún náà.
Ètò ọ̀hún gbérasọ nígbà tí Ọba Rufus Adeyemo Adejugbe Aladesanmi lll, Ewì tí Ado Ekiti jáde bí ayẹyẹ náà ni àwọn olórí Kabiyesi jáde sí gbàgede pẹ̀lú àwọn ìlú iṣẹnbaye tó wà láàfin láti ṣe oro fún Kabiyesi àlàyélúwà.

Oríṣun àwòrán, bbc
Lẹ́yìn ìgbà náà ni àwọn olóyè gbogbo àti àwọn àgbò ilé tó wà ní ìlú Ado tí wọn jọ tẹ̀dó ìlú náà bẹ̀rẹ̀ sí ní kí Kabiyesi ewì Ado lẹgbẹlẹgbẹ fún àdúrà ọdún tuntun.
Ewi Ado Ekiti fi akoko ọdun naa ki awọn ọmọ Naijiria ku irọju ti ọrọ epo bẹntiro to gbowo lori.

Oríṣun àwòrán, bbc
Kí ni igi Ìrókò níí ṣe pẹ̀lú ayẹyẹ Ọdún "Ọlọ́runbọrùn Udiroko" tó ń wáyé nílùú Ado-Ekiti rèé

Oríṣun àwòrán, Wikipedia
Udiroko jẹ ọdún pàtàkì tí gbogbo àwọn ọmọ Ado Ekiti ma ń ṣe ni ọdọọdún tí ó sì tún jé àyẹ́sí ọdún tí wọn de si ìlú náà.
Gégé bí olóyè Aladeloye ọrùnwọn tí Ado Ekiti ṣe ṣàlàyé fún ikọ BBC News Yoruba pé ní gbàtí àwọn Baba ńlá wọn de sì ìlú Ado ni wọn gbé ifá janlẹ láti mọ bóyá ibí tí wọn dé dúró dára láti tẹ̀dó sí lábé igi ìrókò lọ́jọ́ náà lọ́hùún.
Gbogbo àwọn tí wọn rìn ìrìnàjò lojo náà de ilu Ado ni wón kó ara wọn jó lábẹ́ igi ìrókò tí ifá wọn sì fọ ire pé wọn tí de ibi tí wọ́n yóò tẹ̀dó sí, tí inú gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ si ni dùn pẹ̀lú ìjọ àti ayọ̀.

Oríṣun àwòrán, bbc


Ewì Ado jẹ alágbára jagunjagun tó ní agbára gàn pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogún lorisirisi àti àwọn olóyè pẹlu àwọn ẹrú tí wọn rún ẹrù s'ori tẹle wọn de ilu Ado Ekiti.
Abẹ́ igi ìrókò tí wọn tí koko ṣe ìpàdé dá ifá tí gbogbo wọn ti ṣe àjọyo ni wọn sọ di Udiroko ọdún Ọlọ́runbórùn tí ó jé ọjọ́ kìíní ọdún gbogbo ọmọ Ado ni ipinlẹ Ekiti.
Láti ìgbà náà ni wọn ti ń ṣe ayẹyẹ Ọdún náà gẹ́gẹ́ bí àṣà àti ìṣe wọn tí wọn yóò sì ṣe àfihàn gbogbo àwọn ohùn ìṣeńbáyé láti orí gbogbo adé tí ó wà nínú ààfin tí gbogbo àwọn jagunjagun àti àwọn olóyè yóò sì wà ma kira fún Ọba Alayeluwa tó wà lórí ìtẹ́ bàbà rẹ.

Lára ìgbàgbọ́ wọn ní pe gbogbo ọmọ Ado laaro kùtùkùtù gbọ́dọ̀ kó ara wọn jọ pẹ̀lú mọ́lẹ̀bí láti ṣé àdúrà pé ojú wọn rí ọdún túntún láyọ̀ àti àlàáfíà láti bèrè fún òun ti tún lọ́wọ́ elédùmarè.
Lẹyin ìgbà náà ni gbogbo ọmọ Ado yóò gbéra lọ sí ààfin ewì Ado láti lọ ṣe àjọyo pẹ̀lú Ọba àlàyélúwà Rufus Adeyemo Adejugbe Aladesanmi kẹta(111) Ewi of Ado-Ekiti.















