PDP tako ìgbésẹ ìjọba láti fi Benue sára ìpínlẹ̀ tí gàá Fulani yóò wà

Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Benue ti tako bi ijọba apapọ ṣe fi ipinlẹ Benue sara awọn ipinlẹ ti gaa Fulani yoo wa.

PDP APC

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹwẹ, ẹgbẹ naa ti kepe gomina Benue, Faada Hyacinth Alia lati rí pe ipinlẹ Benue kuro lara àwọ̀n ọhun nitori ewu nlá ni igbesẹ naa yoo fa wahala fawọn eeyan Benue.

PDP sọrọ yii ninu atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ naa, Bemgba Lortyom buwọlu niluu Makurdi.

PDP ni "o le tọna lati ni gaa Fulani l'awọn ipinlẹ kan ni Naijiria papaa julọ nibi t'awọn Fulani ba ti pọ sí tẹlẹ.

Amọ, ipinlẹ Benue kii ṣe ibi t'awọn Fulani ti jẹ ọmọ onilẹ ti wọn ti le da gaa wọn sílẹ.

Kò ní boju mu lati da gaa Fulani silẹ nipinlẹ tàwọn Fulani yii kan naa ti n ba awọn nkan amayedẹrun jẹ.

Gomina Benue ti wa ṣe ileri fawọn eeyan ipinlẹ naa pe oun yoo wa ojutuu sí eto aabo to mẹhẹ nipinlẹ naa.

Rogbodiyan laarin awọn agbẹ at'awọn Fulani darandaran ti n waye ti pẹ eleyii ti mu ọpọlọpọ ẹmi lọ.