UAE gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà ọmọ Nàìjíría lẹ́yìn àbẹ̀wò Tinubu

Tinubu ati Al Nahyan

Oríṣun àwòrán, BOLA AHMED TINUBU/TWITTER

Orilẹede United Arab Emirates(UAE) ti gbẹsẹ kuro l'ori ofin to fi de iwe irinna ọmọ Naijiria si orilẹede naa.

Igbesẹ yii waye lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu ṣepade pẹlu aarẹ UAE, Sheikh Mohamed bin Zayed Al Nahyan niluu Abu Dhabi tii ṣe olu ilu orilẹede ọhun.

O ti pe oṣu mẹwaa bayii ti ijọba UAE ti fofin dé awọn arinrinajo lati Naijiria eleyii to sì ti ṣakoba fun idokowo ọpọ eeyan.

Ninu atẹjade ti oludamọran aarẹ lori ọrọ iroyin, Ajuri Ngalale fisita, o ṣalaye pe ipade Tinubu pẹlu awọn alaṣẹ UAE so eso rere.

Ngelale sọ ninu atẹjade ọhun pe Aarẹ Mohamed bin Zayed Al Nahyan fẹnu ko pẹlu Tinubu lori awọn koko kan ti yóò mu ilọsiwaju ba ọrọ aje Naijiria.

Agbẹnusọ aarẹ ni ileeṣẹ ọkọ ofurufu Etihad ati ti Emirates ti wọn ti dawọ iṣẹ duro tẹlẹ ni Naijiria ti bẹrẹ iṣẹ pada.

"Pẹlu iwe adehun ti Tinubu ati aarẹ UAE buwọlu lonii, ọpọ idokowo ẹlẹgbẹlẹgbẹ biliọnu owo dọla ni yoo tibẹ jade ni Naijiria.

Ẹka ileeṣẹ ologun, eto at'awọn ẹka ileeṣẹ ijọba mii naa yoo jẹ anfaani adehun tuntun laarin Naijiria ati UAE," Ngelale ṣalaye.

Bakan naa ni Tinubu tun buwọlu iwe adehun pẹlu ijọba UAE lori eto pasipaarọ owo ti orilẹede mejeeji yoo maa kede rẹ laipẹ.

Lakotan, Tinubu gboṣuba fún aarẹ Al Nahyan fun ipinu rẹ lati fọwọ sowọpọ pẹlu Naijiria fun anfaani orilẹede mejeeji.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Kí ni èrèdí tí Dubai ṣe wọ́gilé físà àwọn ọmọ Naijiria sí ilẹ̀ rẹ̀?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọdun to kọja ni ijọba ilẹ Dubai fofin de awọn ọmọ Naijiria lati ma le ṣabẹwo silẹ naa mọ.

Ninu atẹjade ti Dubai fi lede, wọn ko sọ eredi pato ti wọn ṣe gbe igbesẹ naa, wọn kan sọ pe ko si aye fun awọn ọmọ Naijiria lati wa silẹ Dubai mọ ni.

Igbesẹ yii waye lẹyin ọsẹ diẹ ti wọn kọkọ kede awọn ofin tuntun kan nipa iwe irinna ilẹ naa fun awọn ọmọ Naijiria.

Lasiko naa ni wọn sọ pe awọn ko ni fun ọmọ Naijiria ti ọjọ ori rẹ ba kere ju ogoji ọdun lọ ni fisa, paapaa awọn to n lọ lati gbafẹ.

O ti le ni ọdun kan abọ ti Naijiria ati Dubai ti n fori gbari lori awọn ọrọ kan.

Ninu oṣu Kẹjọ ọdun to kọja, ẹnikan loju opo Twitter rẹ ṣafihan bi wọn ṣe ti awọn ọmọ Naijiria kan mọ inu yara ni papakọ ofurufu Dubai.

Ẹni naa ni wọn ko ṣe daadaa si awọn ọmọ Naijiria bo tilẹ jẹ pe iwe wọn pe perepere.

Amọ ijọba Naijiria, lati ẹnu adari ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa sọ pe niṣe ni awọn ọmọ Naijiria naa ko tẹle ofin to rọ mọ fisa ọwọ wọn.

O ni “Awọn eeyan naa gba fisa to yẹ ki wọn fi rinrinajo pẹlu awọn mọlẹbi wọn amọ lọ lai mu ẹbi wọn kankan dani.”