'Ìdí tí a fi pàṣẹ pé kí olórin yìí fa ìpénpéjú ojú rẹ̀ yọ kó tó yá fọ́tò ìwé ìrìnà rèé'

Ayra Star

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ileeṣẹ to n ri si ìwọlé-wọde lorileede Naijiria ti ṣàlàyé idi ti wọn ṣe pọn ọn ni dandan fun to ba lo ipenpeju to gun lati yọ ọ kuro lasiko ti wọn ba fẹ ya fọto pelebe to maa n wa ninu iwe irina lọ oke okun.

Eyi waye lẹyin ti olorin ọmọ Naijiria kan kọminu gidi gan loju opo Twitter rẹ lori bi wọn ṣe mu u ni ọranyan pe ko yọ ipenpeju rẹ danu.

Ileeṣẹ to n ri si ìwọlé-wọde arinrinajo tun ṣàlàyé pe ofin to kari ile kari oko lorileede Naijiria ti gbogbo ènìyàn gbudọ tẹle ni eyi lai fi ti ipo ẹnikẹni ṣe.

"Gẹgẹ bo ṣe jẹ ofin gbogbogboo lai wo ipo ti wọn wa, bi ẹnikẹni ba ti wa fun foto iwe irina yiya, a saba maa n gba wọn nímọ̀ràn, fi to wọn leti, a o tun bẹ wọn ki wọn gbìyànjú láti wa bi Ọlọrun ṣe da ojú wọn ni ìwọ bá ti wọn ba lee ṣe.

"Gbogbo akoko fun gbigba àkọsílẹ̀ ati foto arinrinajo kii ju isẹju mẹwa péré lọ; amọ eyi kii ri bẹẹ bayii."

Wọn fi kun un pe ofin ni ofin n jẹ o si de gbogbo eniyan.

Tori eyi, wọn tọrọ aforijin lọwọ Ayra Star fun inilara ti wọn ba ti fa fun un.

Iru imura wo ni ofin tẹle fun ẹni to ba lọ fun àkọsílẹ̀ iwe irina?

Iwe irina

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Lori ọrọ ipenpeju ti ọpọlọpọ eeyan to lọ si ọfiisi wọn n kùn nipa rẹ, Ileeṣẹ BBC kan si àjọ to n ri si ìwọlé-wọde (NIS) lori ohun ti awọn eeyan ni lati mọ.

Tony Akueneme to jẹ agbenuso fún Ileeṣẹ náà sọ fun wa pé;

Alakalẹ ofin to de irina ofurufu to si kan awọn iwe irina bákan naa.

Iwe irina yii jẹ ọna idanimọ kaakiri agbaye to si gbe ọpọlọpọ iyi lori bẹẹ si ni kii ṣe nnkan ti ijọba yoo fi ṣere rara.

Ọgbẹni Tony tẹsiwaju lati ṣalaye diẹ lara awọn nnkan ti ofin ko gba fun ẹni to ba fẹ lọ ya fọto ati akọsilẹ iwe irina.

Oruka Imu

“Ami afikun kankan ti ko ba ti si lara bi Ọlọrun ṣe da ọ lodi si ofin ami idanimọ lagbaye. A ko nilo nnkan afikun kankan.

Fun apẹrẹ, bo ba ṣe ila kikọ̀ ni, o lẹ mo oju ni o si wa ni oju rẹ ni gbogbo igba ṣugbọn to ba ti jẹ oruka imu ni, a o faaye gba a, o lee ṣi eeyan lọkan toripe o le yọ ọ nigbakuugba.”

O fi kun un pe ilana yii kan naa ti gbogbo agbaye n tẹle ni Naijiria naa n tẹle to si ni ẹnikẹni lee lọ si oju opo ajọ agbaye to n ri si irina ofurufu lati lọ yẹ awọn ilana agbaye naa wo.

Awọn ọkunrin to di irun

Nipa awọn ọkunrin to n di irun wọn, Ọgbẹni Tony ni wọn ko fi aaye gba eyi rara fun akoko yiya fọto.

“Ki awọn ọkunrin to maa n di irun ma wa ki wọn tun maa reti wa lati gba bẹẹ. Ofin ko faaye gba a.”

Irun lilọ bii ti Dada

Awọn to ni irun bii ti Dada Awuru lori, Ọgbẹni Tony to ba jẹ eyi ti wọn mu wa latọrun ni, ko sewu amọ bi kii ba ṣe bẹẹ, wọn ko ni faaye gba a.

“Ti kii ba ṣe amutọrunwa, ofin ko faaye gba a.”

Awọ Aṣọ

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Akuneme ṣe sọ ọ, “awọn eeyan nilo lati mọ pe ki wọn ma wọ aṣọ funfun dipo bẹẹ ki wọn wọn awọn aṣọ ti awọ wọn fẹ jọ mọ dudu tori awọ nla ti yoo wa lẹyin wọn gẹgẹ bi ilana alakalẹ ti agbaye naa ni funfun ohunkohun ti ko ba si ti tako funfun ko ni gbe aworan to dara jade.”