Ìwé ẹ̀rí mi kìí ṣe ayédèrú, á dára kí adájọ Tribuna wá sọ ibi tó ti rí pé ayédèrú nìwé ẹ̀rí mi - Gómìnà Adeleke

Oríṣun àwòrán, Twitter/@AAdeleke_01
Gomina ipinlẹ Ọṣun ni gbogbo iwe ẹri oun lo duro deede ko si si ayederu ninu wọn gẹgẹ bi alaga igbimọ igbẹjọ idibo sipo gomina nipinlẹ Ọṣun ṣe gbe e kalẹ ninu idajọ to gbe kalẹ lọsẹ to kọja.
Igbimọ naa ninu idajọ to gbe kalẹ mẹnu ba iwe ẹri Gomina Adeleke pe ko kun oju iwọn.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina Adeleke, Mallam Ọlawale Rasheed fi sita lọjọru, O ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ti gbe idajọ kalẹ lori ọrọ iwe ẹri Gomina Adelek lọdun 2018 to si wẹ Adeleke mọ ninu gbogbo ẹsun yiyi iwe ẹri ti wọn fi kan an.
Adeleke ni gbogbo ohun ti Alaga igbimọ to gbọ ẹjọ esi idibo gomina Ọṣun sọ nipa iwe ẹri oun ko lohun meji ninu ju ọna lati ta ẹrẹ ba orukọ oun.
O ni aṣiṣe ọjọ to wa lori iwe ẹri oun lawọn alaṣẹ ileewe oun ti jẹjọ niwaju ile ẹjọ pe aṣiṣe lati ọdọ awọn ni kii ṣe Ademọla Adeleke lo yi iwe naa.
Atẹjade naa wa n rọ alaga igbimọ naa lati wa ṣe alaye bi o ṣe tun pada de ori idajọ pe ayederu ni iwe ẹri gomina Adeleke nigba ti ile ẹjọ kotẹmilọrun ti daju lọdun marun sẹyin pe ko si ohun to ṣe iwe ẹri naa.








