Gbogbo àwọn olùdíje sípò ààrẹ ní tiwa, a kò ya Tinubu sí ọ̀tọ̀– Ìjọba Buhari dá El-Rufai lóhùn

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ijọba apapọ lorilẹede Naijiria ti da gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai lohun lori ẹsun to fi kan ijọba aarẹ Buhari pe wọn n ṣiṣẹ tako oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir El-rufal fi ẹsun kan ijọba arẹ Buhari pe awọn kan wa ni ileeṣẹ ijọba, Aso Rock ti wọn ṣiṣẹ tako ki ẹgbẹ naa di ipo aarẹ to n bọ mu.

Ninu ọrọ rẹ, Minisita fun ọrọ iroyin ati aṣa, LAI Muhammed lo fun El-Rufai ni esi lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ileeṣẹ aarẹ lẹyin ipade ajọ amuṣeya fun aarẹ Buhari, FEC.

Aarẹ Buhari to ṣakoso ninu ipade naa ni Lai Mohamed ni o sọ pe oun ko ṣiṣẹ fun oludije ẹgbẹ oṣelu kankan, ẹni ti awọn araalu ba ti dibo fun ni oun yoo balọ.

Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, gbogbo awọn oludije ni ijọba apapọ n ṣe atilẹyin fun lai fi ti ọrọ oṣelu ṣe.

‘'A kọ mọ boya ẹnikẹni n ṣiṣẹ tako Bola Tinubu ni ileeṣẹ aarẹ’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

O fikun un pe eto idibo ti ko ni magomago ni aarẹ Buhari yoo ri pe o leke ni eto idibo sipo aarẹ to n bọ naa.

‘’Lai sẹ ere tabi awada, ohun kan ti mo le fi da yin loju ni pe ijọba aarẹ Buhari yoo ri pe eto idibo yii ko ni ọwọkọwọ ninu.

Ẹni kan to ṣe pataki ni aarẹ Buhari o si ti fi ero rẹ han to fi mọ iṣe rẹ pe eto idibo ti ko ni magomago ni yoo jọba.

Ohun ti eto idibo ti ko ni magomago tun mọ si ni pe ko ni si ẹnikankan ti yo jẹ aayo fun aarẹ Buhari.’’

‘’Aarẹ fihan ni Daura ni opin oṣẹ to kọja pe oun ko wa fun ẹnikẹni.’’

Bakan naa ni o fikun un pe ijọba aarẹ Buhari ko mọ ẹnikẹni to n ṣiṣẹ tako oludije sipo aarẹ, Bola Tinubu.

Ètò àyípadà owó àti ọ̀wọ́ngógó epó fihàn pé àwọn kan níjọba Buhari ń fẹ́ ìṣubú Tinubu àti APC ní ìbò ọdún 2023

Gomina NAsir El-Rufai

Oríṣun àwòrán, @ElRufai

Gomina Nasir El-Rufai ti sọrọsoke lori eto idibo to m bọ.

El Rufai ṣalaye pe Aarẹ Buhari ti fi awọn ọmọ ẹyẹ kan si abẹ aṣọ gbin ọka.

O ni pẹlu bi awọn kọlọransi kan ni iṣejọba Aarẹ Buhari ṣe n sa gbogbo ipa wọn fun iṣubu ẹgbẹ oṣelu APC ati Tinubu to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu naa fun ipo aarẹ ni ibo ọdun 2023.

Gomina El-Rufai ni yiyọ owo iranwọ kuro lori epo nigba ti ijọba Buhari n buṣe ati wọ ati eto ayipada ati paṣipaarọ owo ti banki apapọ Naijiria n gunle bayii.

‘Awọn kọlọransi kan n fẹ ka padanu ibo yii nitori pe nnkan ti wọn fẹ ko bọ si wọn lọwọ ‘

Gomina NAsir El-Rufai, Bola Tinubu atawọn eekan ẹgbẹ Oṣelu APC nibi ipolongo ibo kan

Oríṣun àwòrán, @El Rufai

Gomina ipinlẹ Kaduna naa ṣalaye pe gbogbo awọn igbesẹ kan to n waye bayii ko ṣẹyin awọn kan ninu iṣejọba Buhari.

Awon naa ni inu n bi lori bi Tinubu ṣe bori ni idije fun oludije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC.

Nasir El-Rufai ni awọn eeyan wọnyi lo n sọ ọrọ di bi adiyẹ da mi loogun nu maa kuku fọ ọ lẹyin.

“Wọn ni oludije ti wọn nifẹ si lati gba aṣia ẹgbẹ fun ipo aarẹ, oludije wọn ja kulẹ lasiko idibo abẹle fun yiyan oludije,

Mo si roo pe awọn eeyan yii ṣi n ṣiṣẹ takuntakun fun wa lati padanu idibo yii, wọn si n sa si abẹ ilakaka aarẹ lati ṣe awọn nnkan to ro pe o dara.”

‘Igba akọkọ kọ niyi ti Buhari yoo yi owo pada, ṣugbọn...’

Gomina El-Rufai ati Aṣiwaju Bọla Tinubu

Oríṣun àwòrán, @EL Rufai

Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe lori eto mohunmaworan ileeṣẹ Channels Television ni Gomina Nasir El-Rufai ti rọjo ọrọ wọnyii silẹ.

O ni gbogbo wọn ni wọn panupọ sọ pe o di dandan ki wọn yọ owo iranwọ kuro lori epo lorilẹede Naijiria ṣugbọn asiko ti awọn kan wa n gbimọ ati ṣe e si mu ifunra dani.

“Bawo ni owo ti ijọba ya sọtọ fun atunṣe awọn ọna yoo jẹ igba biliọnu Naira ti ijọba kan naa yoo wa maa naa tiriliọnu meji fun owo iranwọ ori epo rọbi. Mo ba aarẹ sọrọ lati ṣe afihan idi ti owo iranwọ subsidy fi gbọdọ dopin.”

Gomina El-Rufai ati aare Buhari

Oríṣun àwòrán, @El Rufai

El Rufai ni apẹrẹ keji ni ti ayipada owo ti banki apapọ CBN gbe kalẹ.

O ni bi o tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo n da ẹbi le ori banki apapọ CBN, ṣugbọn bi eeyan ba wo atimaaṣebọ aarẹ Buhari yoo mọ pe igba akọkọ ti ijọba Buhari yoo yi owo pada kọ leyi.

O woye pe nigba iṣejọba ologun Buhari laarin ọdun 1983 si ọdun 1985, o yi owo Naira pada ni ikọkọ lọna ati lee mu awọn to ko obitibiti owo aitọ pamọ nigba naa.

Amọṣa El-Rufai ni asiko ti wọn wa gbe e si lo mu ifura dani nitori o mu ki ẹnu maa kun ẹgbẹ oṣelu APC ṣaaju idibo ọdun 2023.

“Eto rere ni eto naa. Inu aarẹ mọ lori rẹ. Ṣugbọn akoko ti wọn gbe e kalẹ yii ati iye akoko ti wọn fi silẹ fun un ko mu ọgbọn wa rara, yala nipa ti oṣelu tabi ọrọ aje.”