Ẹ̀rù àbájáde ètò ìdìbò kò jẹ́ kí àwọn olùdásílẹ̀ iṣẹ́ ńláńlá wà sí Nàìjíríà lásìkò yìí- Osinbajo

Yemi osibajo

Oríṣun àwòrán, Others

Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo sọ wi pe eto idibo to rọrun ṣẹ pataki nitori o jẹ opo ati atilẹyin fun awọn ara ilu lati gbe gberọrun ati lati ni aaye iṣẹ.

Ọjọgbọn Yemi Osinbajo ti o sọ eyi ni Ọjọ iṣegun nibi Apejọ kan ti wọn ṣe fun awọn adari.

Osibajo sọ wi pe ole lati ṣe idoko-owo ṣaaju eto idibo ati wi pe awọn ara ilu naa nbẹru lati na awọn owo wọn to wa ni ipamọ nitori ibẹru oun ti o le ṣẹlẹ lẹyin eto idibo.

Osinbajo sọ fun awọn olukopa na pe oun to dara julọ ni wi pe ki awọn oniṣowo nisuru di ẹyin eto idibo ki wọn to dokowo nitori ti ijoba ti ko mo nipa ọrọ oko owo ba dori oye oseṣee ko ṣe akoba fun ọrọ aje.

O sọ siwaju pe awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria mọ ninu akọọlẹ to tẹlẹ awọn eto idibo ti orilẹ-ede yii ti se tẹlẹ wi pe,

Ọpọlọpọ iṣẹlẹ lo ma n tẹlẹ eto idibo papa julọ awọn eto idibo ti o ni ariyanjiyan.

O sọ pe eyi nigba miran ma n mu ki awọn aralu baa awọn ohun-ini Ijọba ati ti awọn aladani je.