Olólùfẹ́ méjì fí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá júrá nítorí wọ́n n jó láàrín ìgboro

Awọn ololufẹ meji kan ti ri ẹwọn ọdun mẹwaa he ni orilẹede Iran nitori wọn jo ni aarin igboro.
Ileẹjọ ni wọn jẹbi ẹsun ṣiṣe agbatẹru fun iwa ibajẹ, owo naabi ati sisọrọ tako ijọba.
Fidio ti wọn fi lede lo ṣafihan bu awọn mejeeji ṣe n jo ti wọn di mọ ara wọn ni agbegbe Tehran Azadi (Freedom) Tower.
Iṣẹlẹ yii n waye lasiko ti ijọba n ran awọn eniyan lọ si ẹwọn ni ọgọọrọ nitori wọn darapọ mọ ifẹhọnuhan to waye nitori obinrin to ku si agọ ọlọpaa lorilẹede naa.
Ẹsun ti wọn fi kan obinrin to ku to fa ifẹhọnuhan naa ni pe ko bo ori rẹ ni awujọ.
Amọ awọn lọkọ-laya naa ni fidio awọn ko niiṣe pẹlu fiẹhọnuhan to n waye lorilẹede naa.
Iwadii ti BBC ṣe fihan pe lẹyin ti awọn ololufẹ naa fi fidio ọhun si oju opo ikansiraẹni Instagram wọn ni ijọba he wọn.
Awọn ololufẹ mejeeji naa ni eniyan to lẹ ni miliọnu meji to n tẹle wọn.
Kini ẹṣẹ awọn ololufẹ meji ti wọn ran ni ẹwọn ọdun mẹwaa?
Ẹsun ti wọn fi kan arabinrin Astiazh Haqiqi ati afẹsọna rẹ Mohammed Ahmadi ni pe wọn n ṣe igbelarugẹ asakasa, iwa ibajẹ ati iwa isẹkusẹ lawujọ.
Awọn agbofinro ni iroyin fi lede pe wọn ṣigun lu ile arabinrin Haqigi, to jẹ aṣaraloge ki wọn to fi panpẹ ọba mu.
Gbogbo iye ọdun ti ẹnikọọkan wọn maa lo ni ẹwọn ko i tii han si gbangban amọ ẹwọn ọdun mẹwaa ati aabọ ni wọn fun wọn.
Awọn ololufẹ yii ni wọn ṣi ni fun ni ẹwọn to pọju nitori ifẹhọnu han naa.
Gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, bakan naa ni wọn ko ni lee lo oju opo ayelujara fun ọdun meji.
Kilo fa ifẹhọnuhan kaakiri orilẹede Iran
Ifẹhọnuhan kaakiri orilẹede Iran n waye kaakiri orilẹede naa lẹyin ti orabinrin ẹni ọdun mejilelogun kan gbẹmi mi ni agọ ọlọpaa.
Osu Kẹsan an, ọdun to kọja ni iṣẹlẹ naa waye.
Obinrin naa ni wọn fi panpẹ ọba mu lori ẹsun pe o tapa si ofin to de ki obinrin maa bo iru rẹ lorilẹede naa pẹlu hijab tabi ohun ibori.












