Wo ìdí tí Canada ṣe fààyè gbàwọn àjòjì láti ṣiṣẹ́ di 2025

Embassy

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìjọba orílẹ̀ èdè Canada ti kéde pé àwọn àjòjì tó ń gbé orílẹ̀ èdè náà tó ti gbàwé àṣẹ láti máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ ti ní àǹfàní láti lè fi ọdún méjì kún ọdún tí wọ́n le fi ṣiṣẹ́ báyìí.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn àjòjì, àwọn tó ń ṣe àtìpó àti ìwé ìgbélùú Canada, IRCC fi léde lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ní àwọn àjòjì le gbàwé àṣẹ láti ṣiṣẹ́ di ọdún 2025 láì fi orílẹ̀ èdè náà sílẹ̀.

Àwọn àjòjì tó ti forúkọ sílẹ̀ lábẹ́ ètò yìí, tí wọ́n sì ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ láàárín oṣù méjìlá sẹ́yìn ni wọn tún lè tẹ̀síwájú láti gbàṣẹ láti tètè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn tuntun.

Lásìkò Covid-19 ni wọ́n kọ́kọ́ gbé irú ètò yìí kalẹ̀ láti fi rán orílẹ̀ èdè náà lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ ìpèníjà ọrọ̀ ajé.

Ìdí tí ìjọba Canada fi gbé ètò yìí kalẹ̀ ní láti jẹ́ kí àwọn àjòjì báwọn ṣiṣẹ́ nítorí bí kò ṣe sí àwọn tó tó iye tí wọ́n nílò ní orílẹ̀ èdè náà pàápàá lásìkò tí wọ́n ń gbèrò láti mú ìgbòrò bá ètò ọrọ̀ ajé wọn.

Kí ni ètò yìí túmọ̀ sí?

Kí orílẹ̀ èdè Canada tó kéde ètò tuntun yìí, ẹni tó bá ń wá ìwé àṣẹ láti ṣiṣẹ́ ní Canada tẹ́lẹ̀ yóò ti kọ́kọ́ gba ìwé àṣẹ kó tó wọ orílẹ̀ èdè náà.

Bákan náà tó bá jẹ́ wí pé àṣẹ àjòjì ni ènìyàn gbà láti wọ Canada, tó wá ń bèèrè ìwé àṣẹ láti ṣiṣẹ́ níbẹ̀, onítọ̀hún ma kọ́kọ́ kúrò ní Canada ná, kí wọ́n tó buwọ́lu ìbéèrè rẹ̀.

Àmọ́ pẹ̀lú ètò tuntun yìí, èèyàn kò nílò láti kúrò ní Canada mọ́ kó tó gbàwé àṣẹ.

Ta ló le jẹ àǹfàní ètò yìí?

Kí ènìyàn tó ní àǹfàní láti forúkọ sílẹ̀ fún ètò yìí, ó gbọ́dọ̀ ní àwọn nǹkan yìí:

  • Ní ìwé àṣẹ gẹ́gẹ́ bí àjòjì ní Canada lásìkò tó ń forúkọ sílẹ̀
  • Ní iṣẹ́ èyí tí ètò iṣẹ́ LMIA orílẹ̀ èdè náà faramọ́
  • Fi orúkọ sílẹ̀ fún iṣẹ́ kan pàtó èyí tí kò gbọdọ̀ kọjá ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2025.
  • Ní gbogbo àwọn ìwé àṣẹ mìíràn tí wọ́n nílò láti fi gbà wọ́n síṣẹ́.

Orílẹ̀ èdè Canada nìkan kọ́ ló ti ṣàgbéyẹ̀wò òfin tó de àwọn àjòjì ni orílẹ̀ èdè wọn.

Láìpẹ́ yìí náà ni orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà mú àtúnṣe bá òfin tó de àwọn àjòjì tó ń wọ orílẹ̀ èdè wọn láti Nàìjíríà.

Amẹ́ríkà sọ Físà àwọn àjòjì di ọdún márùn-ún dípo ọdún méjì

Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà náà ti mú àlékún bá iye ìgbà tí àwọn àjòjì le lò ní orílẹ̀ èdè wọn láti ọdún méjì di ọdún márùn-ún láì fi àlékún owó kankan kun.

Èyí wà fún àwọn ọmọ Nàìjíríà tó bá lọ sí Amẹ́ríkà láti najú tàbí láti ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀, kí wọ́n tó ṣe ìwé ìgbélùú wọn.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí Iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà ní Nàìjíríà fi síta, wọ́n ní èyí jẹ́ àdínkù bá iye ìgbà tí àwọn ènìyàn fi ń dúró láti ri ìwé wọ Amẹ́ríkà gbà.

Iye owó tí àwọn ènìyàn máa sọ kò ní lé kún $160 tí wọ́n ń san tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú àlékún yìí síbẹ̀.

Ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹta ọdún 2023 ni ìlànà tuntun yìí yóò bẹ̀rẹ̀.

Bákan náà ni kò ní sí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún àwọn tó bá fẹ́ mú àlékún bá ọjọ́ tí wọ́n fi ń kẹ́kọ̀ọ́.

Àwọn ìlànà tó rọ̀ mọ́ kí ènìyàn má ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò láti ṣe àtúnṣe ìwé láti wọ Amẹ́ríkà

  • Ó gbọ́dọ̀ wà ní Nàìjíríà
  • Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni wọ́n ti kọ́kọ́ fún ènìyàn ni visa
  • Nǹkan kan náà ni visa tí ènìyàn gbà tẹ́lẹ̀ àti tuntun tó fẹ́ gbà
  • Visa tẹ́lẹ̀ rẹ kò ní wúlò mọ́ láàárín oṣù mẹ́ta sígbà tó fi ń béèrè òmìíràn
  • Ní ìwé ìrìnnà tó fàyè gba gbogbo ìgbà tó ti lò tẹ́lẹ̀ àti ìgbà tuntun tí ò ń bèèrè fún
  • Wọn kò ì tíì mú ènìyàn tàbí ṣe ẹ̀wọ̀n rí ní Amẹ́ríkà fún ìwà ọ̀daràn.
  • O kò ṣiṣẹ́ ní Amẹ́ríkà rí láì gba ìwé àṣẹ tàbí kọjá iye ìgbà tí wọ́n fún ẹ ní Amẹ́ríkà.