Ka nípa àwọn orílẹ̀-èdè ti UAE wọ́gilé físà àwọn ọmọ ìlú wọn sí ilẹ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Orileede United Arab Emirates (UAE) ti gbẹsẹ le fifun awọn ọmọ orileede marun din lọgbọn kan ni iwe irina visa wọ ilẹ wọn.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita, awọn alaṣẹ ni''a ko ni faaye gba iwe irina Visa ọlọgbọn ọjọ fawọn ọmọ orileede yi bẹrẹ lati ọjọ Kejidinlogun oṣu Kẹwaa 2022''
Gẹgẹ bi alaye, wọn ni awọn iwe irina tawọn eeyan wọnyi n ṣeto ko lọ lori ẹrọ kọputa tabi ki kọmputa si wọgile wọn..
Amọ iroyin kan ti a koribi fẹsẹ rẹ mulẹ sọ pe iwọgile yi to kan awọn ọmọ Naijiria ko ṣẹyin bawọn eeyan kan lati Naijiria ṣe n lo kọja akoko to wa lori iwe irina wọn.
Bẹẹ lawn mii n duro silẹ naa lọna ẹburu nitori ki wọn baa le wa iṣẹ lalae sọ igbelu wọn di ohun to wa ni ibamu pẹlu ofin.
Orukọ awọn orileede ti UAE wọgile Visa fun un
Yatọ si Dominican Republic ti kii ṣe orileede Afrika ṣugbọn ti wọn wọgile Visa fun ọmọ ilu wọn, awọn ogun jẹ orileede lati ilẹ Afrika ti UAE ko faaye gba wọn lati gba Visa wọ ilẹ wọn.
Ninu wọn la ti ri:
- Ghana
- Sierra Leone
- Sudan
- Cameroon
- Nigeria
- Liberia
- Burundi
- Republic of Guinea
- Gambia
- Togo
- Democratic Republic of Congo
- Senegal
- Benin
- Ivory Coast
- Congo
- Rwanda
- Burkina Faso
- Guinea Bissau
- Comoros
- Uganda
Kí ni èrèdí tí Dubai ṣe wọ́gilé físà àwọn ọmọ Naijiria sí ilẹ̀ rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, NIDCOM
Ijọba ilẹ Dubai ti fofin de awọn ọmọ Naijiria lati ma le ṣabẹwo silẹ naa mọ.
Ninu atẹjade ti Dubai fi lede, wọn ko sọ eredi pato ti wọn ṣe gbe igbesẹ naa, wọn kan sọ pe ko si aye fun awọn ọmọ Naijiria lati wa silẹ Dubai mọ ni.
Igbesẹ tuntun yii lo n waye lẹyin ọsẹ diẹ ti wọn kọkọ kede awọn ofin tuntun kan nipa iwe irinna ilẹ naa fun awọn ọmọ Naijiria.
Lasiko naa ni wọn sọ pe awọn ko ni fun ọmọ Naijiria ti ọjọ ori rẹ ba kere ju ogoju ọdun lọ ni fisa, paapaa awọn to n lọ lati gbafẹ.
Kilode ti Dubai ṣe fofin iwe irinna de Naijiria?
O ti le ni ọdun kan abọ ti Naijiria ati Dubai ti n fori gbari lori awọn ọrọ kan.
Ninu oṣu Kẹjọ ọdun to kọja, ẹnikan loju opo Twitter rẹ ṣafihan bi wọn ṣe ti awọn ọmọ Naijiria kan mọ inu yara ni papakọ ofurufu Dubai.
Ẹni naa ni wọn ko ṣe daadaa si awọn ọmọ Naijiria bo tilẹ jẹ pe iwe wọn pe perepere.
Amọ ijọba Naijiria, lati ẹnu adari ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa sọ pe niṣe ni awọn ọmọ Naijiria naa ko tẹle ofin to rọ mọ fisa ọwọ wọn.
O ni “Awọn eeyan naa gba fisa to yẹ ki wọn fi rinrinajo pẹlu awọn mọlẹbi wọn amọ lọ lai mu ẹbi wọn kankan dani.”
Ọjọ Aiku to kọja yii ni Naijiria ko ẹẹdẹgbẹta eeyan pada wa sile lati Dubai.
Ki ni ijọba Naijiria sọ si ofin ti Dubai fi de fisa awọn eeyan rẹ?
Lootọ ni ijọba Naijiria ko tii fesi si igbesẹ tuntun ti ijọba Dubai gbe yii, amọ wọn ti sọ ṣaaju pe awọn ọmọ Naijiria gbọdọ maa bọwọ fun ofin orilẹ-ede ti wọn ba lọ.
Abike Dabiri-Erewa sọ nigba kan ri pe iṣe ile to ba awọn ọmọ Naijiria di ita lo jẹ ki oju wọn maa ri irikuri lawọn orilẹ-ede bii Dubai ati Malaysia.
Ẹwẹ, ọpọ araalu lo gbagbọ pe igbesẹ ti ijọba Dubai gbe yii ko ṣẹyin ija igboro ti awọn ọmọ Naijiria to n ṣe ẹgbẹ okunkun n ja ni Dubai, atawọn iwa mii bii jibiti ori ayelujara ti wọn n wu.












