Ifá kọ́ ló n yan gbogbo Ṣọun Ogbomoso torí náà...

Àkọlé fídíò, Ogbomoso Kingship:Ifá kọ́ ló n yan gbogbo Ṣọun Ogbomọṣọ
Ifá kọ́ ló n yan gbogbo Ṣọun Ogbomoso torí náà...

BBC Yoruba kan si awọn alẹnulọrọ ni Pgbomosho lori awuyewuye ipo Soun Ogbomosho ati ọmọọba Afolabi Ghandi Laoye to jẹ pe ijọba ni oun ni Ade tọsi

Araba ilu Ogbomoso,awọn aṣoju ọmọ ilu to fi mọ awọn olori idile to n jẹ ọba la kan si ninu fọnran fidio yi.

Olori bi idile Laoye to jẹ idile ti ọmọọba Afolabi Ghandi ti wa jẹ ọkan lara awọn to sọ nipa ohun to n da awuyewuye silẹ lori fifi Ghandi jẹ Soun Ogbomosho.

Alhaji Garba Lawal Tewogbola ṣalaye pe awọn gbe fọọmu sita fawọn ọmọ idile Laoye to ba nifẹ si ipo Soun.

Ninu alaye rẹ o ni gbedeke tawọn gbe kalẹ fun gbigba fọọmu naa ti pe ki Mogaji ile ti Ghandi ti wa to pada lọ tẹ fọọmu mi fun Ghandi.

Koda ni afikun si ọrọ yi, akọwe mọlẹbi Laoye to yẹ ko buwọlu fọọmu naa iyẹn Ọmọọba Sakariyau Laoye ni oun ko mọ si bi Ghandi ṣe gba fọọmu tirẹ.

O ni baba Mogaji ile awọn Ghandi lo yan akọwe miran to si n da eto ṣe fun Ghandi lai bun apapọ idile Laoye gbọ nipa ọrọ naa

Eleyi tunmọ si pe Olori ẹbi ati Mogaji ile awọn Ghandi ko kọkọ fẹnu ko lori fifa Ghandi silẹ lati dije dupo Soun.

Ghandi nikan kọ lo forukọ silẹ lẹyin gbedeke-Mogaji Laoye

Amos Olawole Olaoye to jẹ Mogaji mọlẹbi Laoye fesi si ọrọ yi to si ni oun ko lagbara lati tako ọmọọba to ba ṣetan lati gba fọọmu lati du ipo Soun.

O ni lọjọ ti awọn peju si gbọngan,Ghandi Laoye nikan kọ ni ọmọọba to wa lati gba fọọmu pe oun ṣetan lati du ipo Soun.

''Nigba taa tun de gbọngan, lai gba fọọmu lai gba nkankan awọn meji mii tun wa lati forukọsilẹ pe awọn fẹ du ipo Soun.O ṣoju awọn to wa lati kansu lọjọ naa''

Ọrọ ti de ile ẹjọ lori iyansipo Soun-idajọ yoo waye ni oṣu kẹwa

Akọwe idile Laoye fi to BBC leti pe ko si eyi ti ko loun lẹtọ si jijẹ oye ninu awọn to du ipo Soun.

O ni bi Ghandi ṣe n sọ pe Olorun lo ran oun wa lati jẹ Soun bẹẹ lawọn miran naa n sọ pe Ọlọrun lo ran awọn naa wa lati wa jẹ ipo Soun.

Lafikun, o ni ọrọ yi ti de ile ẹjọ ati pe adajọ ti ni ki gbogbo awọn to pẹjọ naa pada wa ni ọjọ kẹta ati ọjọ Kejila oṣu Kẹwaa lati wa gbọ idajọ lori ọrọ yi.

Olori ẹbi Laoye naa fidi rẹ mulẹ pe ẹjọ wa ni iwaju ile ẹjọ lori ọrọ oye yi.

Bẹẹ lo sọ pe awọn ko fẹ da Gomina laamu nitori pe o ti ni''oun kọ fẹ nkan ti yoo da idile tabi ilu ru''

Amọ o gba Gomina ni imọran wi pe ko ma ṣe jẹ ki wọn fi Ghandi jẹ oye nitori kii ṣe ọmọ oye gidi fun ilu Ogbomosho.

Akọwe ididl

Ki ni Ifa wa sọ lori iyansipo Soun?

Alao Opeyemi Ifamakinde to jẹ Araba ilu Ogbomosho sọ pe awọn ko gburo lati idile Laoye ki ikede to waye pe ijọba ti fi Ghandi jẹ Soun.

O ni bi eeyan ba si ti de ori ipo naa yala bo ṣe pe idile lo yan an si tabi ijọba lo kede rẹ, iru ẹni bẹẹ ti ṣetan lati di oniṣẹṣe niyen nitori ade Soun kii ṣe ti ''Makkah'' tabi ''Jerusalem''

O ni awọn ko tako ki ẹlẹsin miran de ori ipo ṣugbọn iru ẹni bẹẹ ni lati bọwọ fun iṣẹṣe nitori iṣẹ́ṣe lo bi awọn ẹsin yoku.