Wo ìrìn-àjò Afolabi Ghandi Olaoye láti orì pẹpẹ ìjọ RCCG si orì ìtẹ́ Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, RCCG JESUS HOUSE/YOUTUBE
Ori ti yoo d’ade, ko ni ṣalai de ade, ori ti yoo ba si jọba, ko ni ṣalai de ipo ibọ.
Bẹ gan an lọrọ ṣe ri pẹlu Afolabi Ghandi Olaoye ti Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ṣẹṣẹ kede gẹgẹ bi Soun Ogbomoso tuntun ṣe ri.
Bi Olaoye ṣe di ọba yatọ si bi ọpọlọpọ ṣe jẹ ọba nitori o jẹ ọkan lara awọn ori ade nilẹ Yoruba ti wọn ti fi igba kan ṣiṣẹ iranṣẹ gẹgẹ bi alufaa ijọ ri.
Gẹgẹ bi akọsilẹ ti ri, Ghandi kẹkọọ gboye ninu ede Gẹẹsi ni Naijiria ki o to rinrin ajo lọ si oke okun lati tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ nibi to tii kẹkọọ sii nipa ibaṣepọ laarin awọn oṣiṣẹ ati ileeṣẹ.
Ọdun 1992 ni Ghandi di pasitọ ijọ Redeemed, ko da ohun ti a gbọ ni pe kii ṣe ifẹ ọkan rẹ gan an lati jẹ ọba bi o tilẹ jẹ pe ipo naa tọ si i.
Idile Olaoye tii ṣe idile Ghandi jẹ ọkan lara awọn idile marun un ti wọn maa n jẹ Soun Ogbomoso.
Ohun ti a gbọ ni pe Olaoye sọ fun oludari ijọ Redeemed, Pasitọ Enoch Adeboye, nipa ero rẹ pe ko nifẹ si ọba jijẹ.
Lẹyin naa ni a gbọ pe pasitọ Adeboye sọ fun un pe o ni wa ni akọsilẹ pe o maa jọba laye.
Amọ, Olaoye pada sọ fun ijọ rẹ ni orilẹede Amẹrika laipẹ yii pe oun gba lati jẹ Soun Ogbomoso lẹyin ti oun ba ọpọ eeyan sọrọ.
Ero Ghandi tẹlẹ ni pe ki o fẹhinti ti o ba pe ọmọ ọgọta ọdun.
Amọ, riro ni ti eniyan, ṣiṣe ni ti Eleduwa, ati pe ayanmọ o gboogun, ori ni ẹlẹjọ.












