Èdè Yorùbá di ọ̀kan lára àwọn èdè fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọkọ̀ wíwà nílẹ̀ Amẹrika

Oríṣun àwòrán, @Yorubaness
Ijọba ipinlẹ Maryland, nilẹ Amẹrika ti fi ede Yoruba kun ara awọn ede ti yoo maa lo fun ẹkọ awọn to ba fẹ gba iwe ẹri moyege ọkọ wiwa nipinlẹ naa.
Ileeṣẹ iroyin CBS jabọ pe lọwọ yii, ede Gẹẹsi, Spanish, French, Korean, Chinese ati Vietnamese ni wọn gba laaye.
Ni bayii, wọn ti fi ede Yoruba kun ara awọn ede ti wọn yoo maa lo.
Igbesẹ yii lo n waye ni bi wọn ṣe n fi awọn ede tuntun kun eto naa.
Yatọ si ede Yoruba, awọn ede tuntun mii ti wọn fi kun eto naa ni Tagalog, Amharic, Arabic, Russian, Urdu, Hindi, Farsi, Portuguese, ati American Sign Language.
Bẹrẹ lati inu oṣu Kẹsan an yii, awọn eeyan ipinlẹ Maryland yoo lanfani lati lo ede Yoruba atawọn ede tuntun naa fun idanwo iwe ẹri mo yege ọkọ wiwa wọn.
Agbẹnusọ ileeṣẹ Motor Vehicle Agency to n ri si ọrọ iwe ẹri naa, Chrissy Nizer, ṣalaye eredi ti wọn ṣe fi Yoruba kun awọn ede ọhun.
O ni awọn ṣe awọn iwadii kan, awọn si ri pe ede Yoruba jẹ ọkan pataki lara awọn ede ti awọn eeyan n sọ ju ni Maryland.
Nizer sọ pe “O ṣe pataki fun wa lati lo ede ti awọn to n kọ bi wọn ṣe n wa ọkọ gbọ daadaa ni Maryland to jẹ ilu ti oniruru ede pọ si.”
Wayi o, ọpọ awọn Naijiria, paapaa awọn to gbọ, ti wọn si n sọ ede lo ti kan sara si igbesẹ naa, ti wọn si n sọ pe o yẹ ki irufẹ igbẹ bayii waye ni Naijiria to jẹ orisun ede Yoruba.








