‘’Ẹbí kan náà ni ọ̀gágun Nguema tó gbàjọba ní Gabon àti Ààrẹ Ali Bongo’’

Oríṣun àwòrán, AFP
Bo tilẹ jẹ wi pe awọn ologun ti gbajọba Aarẹ Ali Bongo lorilẹede Gabon, eleyii ko ni fopin si iṣejọba ẹbi Bongo lorilẹede naa.
Ẹnikan to sun mọ Aarẹ Bongo ti ko fẹ ki a da orukọ rẹ lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC.
Ẹbi Aarẹ Bongo tawọn ologun doju ijọba rẹ bolẹ ti ṣe ijọba orilẹede Gabon fun ọdun marundinlọgọta.
Ẹni to fidi ọrọ yii ṣalaye pe ẹbi kan naa ni ọgagun Brice Oligui Nguema ti i ṣe olori awọn ọmọgun to gbajọba Aarẹ Bongo jẹ.
O wa rọ awọn eeyan orilẹede Gabon lati ma yọ ayọ ju tori pe nkan le ma yi pada kiakia bi wọn ṣe lero.
Kete ti ajọ eleto idibo kede Aarẹ Bongo pe oun lo jawe olubori ninu ibo aarẹ orilẹede Gabon ni awọn ologun gbajọba orilẹede naa.
Ni bayii, Aarẹ Bongo ti wa ni gbaga awọn ologun.
Ẹwẹ, ijọba ologun orilẹede Gabon kede lọjọ Abamẹta pe awọn yoo ṣi ẹnu ibode orilẹede naa lẹyin ti wọn gbe wọn ti pa ni kete ti wọn gbajọba l’Ọjọbọ.
Bakan naa, ọrọ ti ẹni yii sọ fun BBC ṣe deedee pẹlu ohun ti olori awọn ọmogun ọlọtẹ, Albert Ondo Ossa naa sọ fu ileeṣẹ iroyin AFP nigba to so pe ẹbi Aarẹ Bongo naa si ni ọgagun Nguema to gbajọba.
Ọgbẹni Ossa ni ọgbọn ni ẹbi Bongo n da lati maa tẹsiwaju ṣiṣe ijọba orilẹede Gabon lọ.
Awọn ẹgbẹ kan ti orukọ wọn n jẹ Alternation 2023 ti wọn kede lọjọ Abamẹta awọn lo jawe olubori ninu eto idibo Gabo ti kepe ajọ orilẹede agbaye lati ri pe awọn ologun da ijọba pada fun awọn alagbada.
Ile aṣofin agba orilẹede Gabon, awọn orilẹede to yi Gabon ka ati orilẹede Faranse to ko Gabon lẹru ni wọn ti bẹnu ẹtẹ lu iditẹgbajọba to waye ni Gabon.
Ajọ awọn orilẹede ilẹ Afirika, AU ti jawe gbeleẹ fun Gabon ninu ajọ naa.
Lootọọ ni Ọgagun Nguema sọ pe ijọba ologun yoo gbe ijọba pada fun ijọba awaraawa, amọ ko sọ asiko ti eleyii yoo waye.
Omar Bongo jẹ aarẹ Gabon fun ọdun mọkanlelogoji ki ọmọ rẹ Ali to gori aleefa lọdun 2009 lẹyin ti baba ku.












