Mo pàdánù ìyàwó àti ọmọ ọkùnrin mẹ́ta nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì Morocco-Abdou

Aworan Abdou Rahman ati ọkan ninu awọn ọmọ rẹ

Inu ibanujẹ ohun ipaya lawọn olugbe abule Tafeghaghte,abule kan to jina ni iwọn mẹẹli mẹtadinlogoji si Marrakesh wa.

Ko si sẹyin bi eeyan aadọrun ninu awọn eeyan igba to n gbe ni abule naa ṣe padanu ẹmi wọn ninu ijamba ilẹ riri to waye ni Morocco.

Ọkan ninu awọn to padanu mọlẹbi ninu iṣẹlẹ yi ni Abdou Rahman wa.

Awọn eeyan n ba arawọn daro ṣugbọn ti Abdou Rahman yatọ si tawọn iyoku.

Idi si ni pe iyawo rẹ ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin mẹta lo ba iṣẹlẹ naa lọ.

''Oke nibẹyẹn ni ile wa wa''

Bẹẹ lo nawọ si ibi ti ile naa gbe duro si tẹlẹ.

Ni bayii, ile naa ti parẹ mọ ebutu to gba gbogbo agbegbe naa kan.

''Ẹ le foju ri awọn aṣ idabora wa ati awọn pako to wa ninu ile naa.Gbogbo nkan ini wa pata lo ti parẹ''

Abdou Rahman sọ pe niṣe loun sare kilomita mẹta de ile lati ile epo toun ti n ṣiṣẹ nigba toun gburo ilẹ riri naa.

O ni oun bẹrẹ si ni pariwo orukọ awọn ọmọ oun ṣugbọn ko si ẹnikankan to fọhun pada.

''Lana yi la sin oku awọn ọmọ naa.''

O tẹsiwaju pe ''nigba taa pada ri oku wọn,niṣe ni gbogbo wọn dimọ ara wọn.Awọn mọ mẹtẹẹta ti sun lọ.Wọn ba ilẹ riri naa lọ ni''

Awọn okuta ati bulọọku aye atijọ ti wọn fi kọ awọn ile wọnyi ko lagbara lati gba ilẹ riri yi duro.

Gẹgẹ baa ṣe sọ ṣaaju o sunmọ idaji awọn ara abule yi to ba iṣẹlẹ ilẹ riri to ti mu ẹmi to le ni ẹgbẹrun meji lọ ni Morocco bayii.

Hassan to jẹ ọkan lara awọn olugbe abule yi ṣalaye pe ibatan oun kan ṣi ha sabẹ ile to ri ninu iṣẹlẹ yi.

O ni awọn ko ni ireti pe awọn yopo ri yọ laaye.

Ko si ẹnikankan to ni irinṣẹ ti wọn le lo lati fi yọ eeyan kuro tabi wọ okuta kuro lori awọn ile to wo.

Iranwọ ti wọn n reti lati ita ko si tii de.

''Allah lo mu wa. A si dupẹ lọwọ rẹ fun gbogbo ohun to ṣẹlẹ.Ṣugbọn bayi a nilo iranwọ lati ọdọ ijọba wa.Wọn pẹ pup lati wa ṣe iranwọ fawọn eeyan''

Hassan fikun ọrọ rẹ pe o yẹ kawọn alaṣẹ Morocco tẹwọgba gbogbo eyikeyi iranwọ to ba wa lati ita.Amọ o ni igberaga le ma jẹ ki wọn ṣe bẹẹ.

Wọn ta tẹẹnti nla kan lẹba oju ọna ti o so abule yi pọmọ awọn to ba n bọ latti ita.

Nibi lawọn aimọye ẹbi kora jọ si.

Kikan kikan lawọn eeyan n sunkun ti wọn si n ṣe idaro nibi taa n sọ yi.

Ohun to mu ki ariwo naa pọ si lasiko taa de ibẹ ni pe wọn ri oku ọmọ obinrin ọdun mẹwa kan Khalifa,gbe jade kuro labẹ ilẹ to ri yi.

O kọja afẹnusọ.

O binrin kan daku lọ gbọrangandan ti ẹlomiran naa si wo lu aga to bẹrẹ si ni sunkun.

Abule yi nikan kọ ni ibanujẹ ati idaro yi ti n waye.

Jakejado awọn abule tọrọ kan ni Morocco ni nkan ko ti rọgbọ.

Ṣaaju asiko yi, awọn abule to wa ni agbegbe yi ko jara mọ pe ki awọn araata da si ọrọ wọn.

Ṣugbọn pẹlu nkan to der bawọn yi, wọn nilo iranwọ eyi ti wọn ko tiẹ ni bikita ibikibi to ba ti wa.

Ni kiakia si ni wọn nilo aranṣe lati ọwọ awọn ẹlẹyinju aanu.

Obinrin kan padanu ọmọ rẹ obinrin ẹni ọdun mẹwaa Khalifa