Ọlẹ̀ Ìbejì ń gbé bíi kòkòrò nínú ọmọ ìkókó

Shazia n sun ibusun ni ile wosan- aa fi nikan boju rẹce is blurred to conceal her identity

Oríṣun àwòrán, Sheikh Zayed Medical College

Àkọlé àwòrán, Ara Shazia ti lẹyin ti wọn yọ ibeji rẹ kuro ni ikun rẹ
    • Author, By Zubair Azam & Ahmen Khawaja
    • Role, BBC World Service

Nigba ti Dokita Mushtag Ahmed isẹ abẹ fun ọmọ oṣu mẹwaa lati yọ kokoro kan ti o n da laamu, iyalẹnu lo jẹ fun un lati ri ẹsẹ ọmọ mii ninu rẹ.

"Emi ati awọn yooku mi n reti pe a yoo ba kokoro ninu ikun ọmọ oṣu mẹwaa yii, to si n sukun ninu inira fun ọpọlọpọ oṣu .

Sugbọn bi a ṣe si inu ọmọ naa, a bẹrẹ si ni ma ri ita ọmọ ẹsẹ. N ko le sọ tan.

"N ko ti ba irufẹ nnkan bayii pade ri lati ọdun mẹẹdogun ti mo ti n ṣe isẹ abẹ."

Bi o ṣe salaye, Dokita Mushtaq ni oun ati awọn yooku ri pe awọn n wo oyun ibeji ninu ikun Shazia.

O ni o dabi pe bi ọsẹ mẹjọ si mẹsan an si oyun kọ lati dagba si

"A n wo bi awọn kinni yii ṣe n dagba, a ri nnkan to jọ oju ati ẹsẹ."

Isẹ abẹ ti wọn ṣe lati yọ awọn kokoro yii lo waye ni Pakistan, ni ile wosan Sheikh Zayed ni Rahim Yar Khan, ni guusu agbegbe Punjab.

Esi ayẹwo ikun Shazia's

Oríṣun àwòrán, Dr Mushtaq Ahmed

Àkọlé àwòrán, Esi ayẹwo Shazia's ti awọn dokita fi gbagbọ pe awọn kokoro ni ikun rẹ sugbọn wọn ri pe ibeji rẹ lo wa rẹ

Oyun ninu oyun

Ninu aye iṣegun, ko wọpọ lati ri oyun ni oyun, ni bi oyun ọmọ kan yoo wa ninu ikeji rẹ.

Eyi sa ba maa n waye ni ibẹrẹ oyun, ti ọkan lara ibeji yoo we mọ ikeji .

Ti wọn ko ri idagbasoke, wọn ma di kokoro, ti wọn si mu ẹjẹ ikeji rẹ lati le wa laye . Irufẹ awọn ibeji bẹ ma jade laye ki wọn to bi wọn.

Gẹgẹ bi American Academy of Paediatrics ṣe sọ ni ọdun 2000, o ni irufẹ nnkan bayii sọwọn pupọ

O to ọpọlọpọ igba ti isẹlẹ yii ti waye ni agbaye.

Babab Shazia's n ba awọn akọroyin

Oríṣun àwòrán, Sheikh Zayed Medical College

Àkọlé àwòrán, Baba Shazia's sọ pe awọn gbe lọ si ọdọ awọn dokita ni ilu wọn, Sadiqabad sugbọn iyatọ ko de ba.

Ẹkun Shazia

Ọmọ ikoko Shazia's ni iku bẹrẹ si ni ma tobi laarin oṣu kan ti wọn bi. Awọn obi rẹ ni o ma sukun fun ọpọlọpọ igba, to si ma fa inira fun un.

"A ko mọ nnkan to n sẹlẹ sugbọn ikun rẹ le lati tẹ"/ eyi ni ọrọ baba Shazia, Muhammed Asif.

Alabaru to tun sisẹ loko ni Asif ati iyawo rẹ, ti wọn si tun ni ọmọ meji, wọn gbw Shazia lọ si ọdọ ọpọlọpọ dokita mi ilu wọn ni Sadiqabad. Sugbọn ipenija bi ko si ẹrọ iṣegun igbalode ni agbegbe naa ko jẹ ki wọn ri ojutu.

"Nigba ti Aisan Shazia ko ṣe mu mọra mọ, lọjọ kẹdọgbọn, oṣu kẹjọ, wọn pinnu lati rin irinajo lọ si ile iwosan Sheihk Zayed ni Rahim Yar Khan.

Lẹyin isẹju diẹ, wọn pade Dokita Mushtaq.

"Nigba ti mo ṣe ayẹwo ọmọ naa, mo fi ọwọ tẹ lati ri pe o di nnkan sinu rẹ sugbọn ero ko tiẹ lọ si bi ohun ti a ri ."

Ninu fọnran, ohun ti wọn yọ kuro ninu ikun Shazia s is blurred out lying next to cloth after it was removed from Shazia

Oríṣun àwòrán, Sheikh Zayed Medical College

Àkọlé àwòrán, Nini fọnran, aworan ibeji Shazia ti a fi nnkan bo lẹyin ti wọn yọ kuro ni ikun rẹ

Awọn obi Shazia ko ni agbara owo lati ṣe ayẹwo MRI, ti ko ba ti wọn ohun ti a n fẹ. Dokita Mushtaq gba ni imọran pe sise isẹ abẹ nikan lo ọna abayọ.

"Eyi dẹrun bawọn- wọn ko gbọ mi ye lori idi ti ọmọ ikoko fi nilo lati ṣe isẹ abẹ.

Awọn obi Shazia kọ lati ṣe isẹ abẹ, ti wọn si gbe ọmọ naa pada si ile.

Sugbọn wọn pada wa lẹyin ọjọ diẹ, ti wọn si ni awọn ṣetan lati ṣe ohunkohun lati ran ọmọ wọn lọwọ.

"Awọn mọlẹbi koni owo lọwọ sugbọn ile wosan fun wọn ni adikun ninu iye owo ti wọn fẹ san, lati fi ṣe iranlọwọ fun ọmọ naa." Dokita Mushtaq salaye.

Lọjọ kọkandinlọgbọn,lasiko isẹ abẹ, awọn ikọ mi ri ohun iyalẹnu, ti wọn ri si ibeji Shazia, ti wọn ko bi sita ninu rẹ, wọn ri pe a gbọdọ isẹ abẹ lati fi yọ ibeji naa.

"O yawalẹnu lati ri oku ibeji rẹ ti ko dagba, to ti n gbe kiri."

Ibeji ti b gbe ninu rẹ bi kokoro, to si mu ẹjẹ rẹ, to ki si fun ni anfani lati ri ere ounjẹ to n jẹ lati ṣe ara lore.

Dr Mushtaq Ahmed

Oríṣun àwòrán, Mushtaq Ahmed

Àkọlé àwòrán, Dr Mushtaq Ahmed ni oun ko ti ri nnkan irufẹ isẹlẹ yii lati mẹdogun ti oun ti bẹrẹ isẹ isẹ abẹ.

Dokita Mushtaq salaye pe ara Shazia bẹrẹ si ni ya lẹsẹkẹsẹ to pari isẹ abẹ, to si ti dagba si

"Ko sunkun mọ ati pe a ripe iyatọ ti de ba lẹyin isẹ abẹ naa."

Shazia kuro ni ile wosan lọjọ kẹrin oṣu kẹsan an, ọjọ kẹrin lẹyin isẹ abẹ.

Igbimọ yoo tunbọ lati ma ṣe ayẹwo si Shazia, ti wọn yoo si gbe abọ iwadii silẹ

Iroyin Ofege nipa pe ọmọ ikoko loyun

Pẹlu bi isẹlẹ ṣe jẹ ohun ti ko ki n waye , eyi ti da nnkan silẹ laarin awọn akọroyin, nitori pe wọn nifẹ si iroyin. Baba Shazia ti lu foonu rẹ pa lati ma le gbe ipe ti wọn yoo bere lọwọ rẹ.

"Ileeṣẹ iroyin, ileeṣẹ momaworan n pe lati mọ nnkan to waye si oyun ikoko, ti wọn si n bere ibeere ti ko yẹ ki wọn bere.," o salaye.

Igbimọ ile wosan ni awọn ti pese atẹjade fun awọn akọroyin, ti awọn si ti gba awọn obi ni iyanju, nitori awọn ibere naa kọ wọn lominu lori iroyin ofege to n lọ kiri.

Olori ilewosan , Dokita Nadeem Akhtar ti mu lọkunkundun lati salaye pe ohun to sẹlẹ si Shazia ko jọ mọ oyun nini.

"Awọn akọroyin n gbe iroyin ofege , ti wọn si ni isẹlẹ yii jọ mọ oyun nini ko ni imọ nipa ohun to isẹlẹ. Ọrọ yii bi awọn mọlẹbi ninu pupọ." Ọjọgbọn Akhtar.

Oloyun to fi ọwọ mejeeji di oyun mu

Oríṣun àwòrán, PA

Àkọlé àwòrán, Isẹlẹ yii ko wọpọ ninu oyun nini