Wọn rí òkú akẹ́kọ̀ọ́ Fásitì FUOYE tí wọn ń wá níbi ti wọn sin-ín sí lẹ́bàá yàrá ìkàwé

Aworan Modupe Atanda Deborah

Oríṣun àwòrán, Facebook

Awọn alasẹ ile ẹkọ fasiti ijọba apapọ to wa ni Oye-Ekiti(FUOYE), lọjọbọ kede iku ọkan lara akẹkọọ rẹ, Modupe Atanda.

Akọwe ile ẹkọ naa, Ọgbẹni Mufutau Ibrahim lo kede ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede niluu Oye Ekiti.

Atanda Modupe Deborah lo jẹ akẹkọọ to n kọ ẹkọ nipa imọ Nọọsi ni Fasiti FUOYE ni

“Saaju ni awọn alasẹ gbe atẹjade kan jade pe a n wa oloogbe, ti a si jẹ ko di mimọ pe iwadi ti bẹrẹ lai sawari ibi ti akẹkọọ naa wa.

“Sugbọn iroyin to tẹ wa lọwọ lati ọdọ awọn ẹsọ alabo fasiti wa ni pe akẹkọọ ti a n wa ti dologbe.

“Fasiti ba awọn mọlẹbi akẹkọọ naa kẹdun, ati pe iwadi ti bẹrẹ lati mọ ohun to waye ati awọn to lọwọ ninu iku akẹkọọ naa.

“A n rọ gbogbo akẹkọọ lati ma se kaya soke

FUOYE ni ki awọn akẹkọọ kuro ni ayika fasiti

Aworan Atẹjade lati FUOYE

Oríṣun àwòrán, FUOYE

Bakan naa ni awọn alasẹ ile ẹkọ naa ti palasẹ fun akẹkọọ fasiti lati kuro ni ayika ati agbegbe fasiti.

Ile ẹkọ naa salaye pe ọrọ iku akẹkọọ naa ti de ileeṣẹ ọlọpaa, ti iwadi si ti bẹrẹ ati pe ọwọ ti awọn eeyan kọ kan to le mọ nipa ohun to ṣekupa akẹkọọ naa.

“Pẹlu awọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe ti bẹrẹ , a n palasẹ fun gbogbo awọn akẹkọọ wa pe ki wọn ko kuro ni agbegbe fasiti ni kiakia.

“O se pataki ka jẹ ko dimọ pe awọn ọlọpaa ti de si ile ẹkọ, lati bẹrẹ iwadii.

“A fẹ ko di mimọ pe gbogbo igbesẹ ni a yoo gbe lati ri pe ọwọ tẹ awọn eeyan to lọwọ ninu iku akẹjọọ, ti yoo si oju ba ileẹjọ.”

Ọwọ ti afurasi mẹwaa lori iku Modupe Atanda- Ileeṣẹ ọlọpaa

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti ni ọwọ ti tẹ afurasi mẹwaa lori iku akẹkọọ fasiti Oye Ekiti.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, DSP Abutu Sunday lo gbe ikede yii jade lori opo ayelujara Twitter.

Sunday salaye ni akẹkọọ ọhun di awati lọjọ karun un oṣu kẹsan an ọdun 2023.

O ni awọn sawari oku Deborah ni ile asalẹ kan toto kilo ọgbọn meter si gbọngan yara igbakọ.

“Eyi ni latin sọ fun gbogbo eeyan ipinlẹ Ekiti pe Kọmisana ileeṣẹ ọlọpaa, CP Ogundare Dara ti palasẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori ohun to ṣekupa, Atanda Modupe Deborah, akẹkọọ onipele keji ni fasit FOUYE , ẹni ti o kan sadede jade kuro ni ile to si di awati ni agbegbe fasiti lọjọ karun un oṣu kẹsan an sugbọn ti wọn ri oku rẹ ni bi ti wọn gbe sin si ni bi ọgbọn kilo meta si gbọngan yara igbẹkọ.”

O ṣe ileri pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo ri pe ọwọ tẹ awọn ọdaran naa, ti wọn si foju ba ile ẹjọ

“A n gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lati ṣe suuru , Kọmisana ti ṣe ileri pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo sa gbogbo ipa lati ṣe awari awọn ọdaran naa.

O salaye pe awọn ti gbe oku oloogbe naa lọ si ile igbe oku si fun ayewo , ti afurasi mẹwaa si ti wa ni akata awọn ọlọpaa.