Ṣé India ń gbèrò láti yí orúkọ padà sí Bharat?

Ère Mahatma Gandhi

Oríṣun àwòrán, Getty

Àkọlé àwòrán, Ọmọ India tó jà fún òmìnira, Mahatma Gandhi jà pé kí wọ́n má pe India ní Hindu nation lẹ́yìn tí wọ́n gba òmìnira lọ́wọ́ Britain.
    • Author, Written by Swminathan Natarajan, subbed and approved by Aine Gallagher
    • Role, Global Digital

"India, ìyẹn Bharat, "yóò jẹ́ àkójọpọ̀ àwọn ìpínlẹ̀," ni ohun àkọ́kọ́ tó wà nínú ìwé òfin. Àṣamọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé: Àwa, ènìyàn India..."

Bharat ni wọ́n máa ń lò láti fi júwe India ní èdè Hindi àmọ́ tí ọ̀rọ̀ bá di sísọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, India ni wọ́n máa ń lò.

Ìṣèjọba Narendra Modi ti ń mú àyípadà bá èyí. "Ààrẹ Bharat" ló wà lórí ìwé ìpè tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí àwọn ènìyàn tí wọ́n pè síbi àpèjẹ oúnjẹ alẹ́ níbi àpérò G20 tí yóò wáyé lọ́jọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹsàn-án.

Bákan náà àtẹ̀jáde nípa àpérò náà tún júwe Narendra Modi gẹ́gẹ́ bí Olóòtú ìjọba Bharat.

Kí ni Bharat?

Lítíréṣọ̀ Hindu júwe ilẹ̀ tó wà láàárín Himalaya àti àwọn òkun bíi "Bharatvarsh".

Modi kópa níbi ìpàdé Rashtriya Swayamsevak Sangh (RSS) ní 2009

Oríṣun àwòrán, Getty

Àkọlé àwòrán, Narendra Modi darapọ̀ mọ́ ikọ̀ RSS láti ọmọdé

Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ Hindu, Bharata jẹ́ Ọba Hastinapura tí wọ́n ń pè ní Hastinapur, tó wà ní ìlà oòrùn Delhi nísìnyí.

Òun ló gbà gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀ tí wọ́n sì gbà á ní ọba tó tọ́.

Nínú ìwé Hindu tó pẹ́ jùlọ, Rig Veda, wọ́n dárúkọ Bharata bíi orúkọ àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn kan.

Bharata nínú Sanskrit tún túmọ̀ sí ilẹ̀ tó máa ń máa ń pèsè tó sì mọyì. Ó le túmọ̀ sí àṣà.

Olóòtú ìjọba India tẹ́lẹ̀ rí, Jawaharlal Nehru kọ lọ́dún 1927 pé India ni Bharata, ilẹ̀ mímọ́ àwọn Hindu àti pé ìdí nìyí tí wọ́n fi gbé àwọn ààyè pàtàkì Hindu sínú India.

Àmọ́ Bharat kìí ṣe onítàn ènìyàn.

Onímọ̀ kan tó ń gbé ní Paris, Catherine Clementin-Ojha kọ lọ́dún 2014 pé "Bharata jẹ́ ọ̀rọ̀ lórí ààyè ṣùgbọ́n tí kò fi ààyè gba rírí ààyè náà.

Kí ni ó bí orúkọ India àti Hindustan?

Àwọn ará Persia máa ń pe odò Indus ní Hindu ní èyí tó di India ní èdè Látìn.

Orúkọ "India jẹ́ orúkọ àbáláyé fúnra rẹ̀.

Abala àkọ́kọ́ ìwé òfin India

Oríṣun àwòrán, By Arrangement

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Àwọn Mùsùlùmí Mughals tí wọ́n dárí ilẹ̀ náà fún igba ọdún máa ń fi ara wọn yangàn bíi "Badshah ti Hindustan", olùdarí Hindustan.

Orúkọ Hindustan náà wáyé láti ọ̀dọ̀ àwọn ará Persia. Nítorí náà, India àti Hindustan jẹ́ àwọn orúkọ tó ti pẹ́ ṣáájú kí àwọn òyìnbó amúnisìn tó bẹ̀rẹ̀ ní India lẹ́yìn ìdíje Bengal lọ́dún 1757.

Ìjọba ní tí àwọn bá ṣe àyípadà orúkọ náà sí Bharat yóò jẹ́ kí àwọn gbàgbé nípa àwọn òyìnbó tó mú àwọn sìn fún ìgbà díẹ̀.

Mínísítà fún ètò ẹ̀kọ́ India, Dharmendra Pradhan ní lílo "Bharat" jẹ́ ohun ńlá láti fi gbé ọkàn àwọn kúrò lórí àwọn tó mú àwọn sìn.

Àmọ́ láti ọdún tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ni wọ́n ti ń lọ India.

Onímọ̀ ìtàn ọmọ Greece, Megasthenes tí wọ́n bí ní ọdún 350BC nínú àkọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti rí ìdárúkọ India tó pẹ́ jùlọ. Ìwé mẹ́rin ló kọ ní orúkọ "Indica".

Gbajúmọ̀ akọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, William Shakespeare náà dárúkọ India nínú àwọn iṣẹ́ rẹ̀.

"Adé mi wà nínú ọkàn mi, kìí ṣe ní orí mi, wọn kò tó òkúta àti wúrà India mọ," ní Ọba Henry sọ nínú ìwé Henry VI apá kẹta, èyí tí ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n kọ ní ọdún 1591 sí 1592.

Àwọn oníṣòwò ilẹ̀ Britain wọ India ní ọdún 1600 láti dá ilé iṣẹ́ ìlà Òòrùn India kalẹ̀.

Ìwé mímọ́ Bíbélì tí King James kọ́kọ́ kọ náà pe orílẹ̀ èdè náà ní 'Indie'. Gbogbo èyí ló wáyé kí Britain tó mú India sìn.

Ìbẹ̀rù àti àtakò

Láti ọdún 2014 ni Olóòtú ìjọba Narendra Modi ti ń darí India tó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Bharatiya Janata Party (BJP) èyí tó wà ní ìjọba ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpínlẹ̀.

Ẹgbẹ́ òṣèlú náà ló ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Rashtriya Swayamsevak Sangh tí wọ́n gbàgbọ́ pé 'Hindu nation' ló yẹ kí India máa jẹ́.

Láti kékeré ni Narendra ti darapọ̀ mọ́ RSS tó sì dàgbà sínú rẹ̀.

Ẹ̀ẹmẹ̀ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti fòfin de RSS lẹ́yìn tí India gba òmìnira. Àkọ́kọ́ ni ìgbà tí àwọn kan pa Mahatma Ghandi lọ́dún 1948 tí wọ́n sì fẹ̀sùn kan RSS pé àwọn ló wà nídìí rẹ̀.

Àwọn RSS ń yan bí ológun ní Jaipur

Oríṣun àwòrán, Getty

Àkọlé àwòrán, Wọ́n fẹ̀sùn kan àwọn RSS pé wọ́n ń gbógun ti àwọn Mùsùlùmí

Ìjọba Modi ti pè fún ìjókòó pàtàkì nílé aṣòfin orílẹ̀ èdè náà láàárín ọjọ́ Kejìdínlógún sí ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kẹsàn-án.

Àwọn alátakò àtàwọn míì ní ó le jẹ́ láti pa orúkọ orílẹ̀ èdè náà dà ní ìjókòó náà wà fún.

Ìjókòó ni àkọ́kọ́ tí yóò wáyé ní ilé aṣòfin tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ní èyí tí wọ́n fi àsíá Greater Bharat sí.

Ile aṣòfin India tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty

Àkọlé àwòrán, Ìjókòó àwọn aṣòfin India ní ilé aṣòfin tuntun le mú àyípadà bá orúkọ orílẹ̀ èdè náà

Àwọn lámèyítọ́ ní ẹgbẹ́ òṣèlú BJP máa ń lo àwọn èèkàn àṣà Hindu gẹ́gẹ́ bí ohun ìtàn àti pé àwọn alátakò ti ṣetán láti gbéná wo ojú wọn lórí ìgbésẹ̀ tuntun yìí.

Ọmọ ilé aṣòfin kan láti ẹgbẹ́ òṣèlú Indian National Congress Party, Shashi Tharoor kọ sí ojú òpó X rẹ̀ pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sì òfin tó tako pípe India ní Bharat, òun rò wí pé ìjọba kò ní sọ orúkọ India tí orílẹ̀ èdè náà ti ń jẹ́ tipẹ́ nù bẹ́ẹ̀.