Àjọ̀dún ọmọ Ohori Ije ní tilé toko gbérasọ ní orílẹ̀-èdè Benin Republic

Aworan awon eeyan Ohori

Awọn ọmọ ilu Ohori nile loko lẹyin ko ara wọn jọ pọ lati ṣe ajọdun wọn ni orilẹ-ede Benin Republic.

Ilu yii ni itan sọ pe lati Ile Ife to jẹ orirun ẹya Yoruba ni ilu naa ti ṣẹ wa.

Itan tun fidi rẹ mulẹ pe ilu Oyo ni wọn kọkọ sẹ lọ ki wọn to lọ sí Benin Republic.

Ayẹyẹ ati igbelarugẹ aṣa awọn eeyan Ohori Ije ti n waye nibi ajọdun naa to ti bẹrẹ lati ọjọ Ẹti tii ṣe ọjọ kẹẹdogun oṣu Kejila yii.

Ayẹyẹ naa si tun tẹsiwaju lonii ọjọ Abamẹta.

Ijo ibilẹ, afihan ounjẹ awọn Ohori at'awọn nkan mii yoo waye nibi ajọdun yii.

Fun apẹẹrẹ, awọn ọmọ Ohori gbagbọ pe Iran awọn lo kọkọ se ẹkọ àgbàdo.

Awọn ọmọ Ohori ṣetan lati ṣe afihan bi wọn ṣe n kọla at'awọn nkan mii nibi ajọdun yii.

Ilu Ohori Ije wa labẹ aṣẹ ijọba ibilẹ Ikpobe ni Benin Republic.