NDLEA mú ìyà 75 pẹ̀lú oògùn olóró l'Eko

Aworan

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/NDLEA

Ọwọ ajọ to n gbe ogun ti oogun oloro lorilẹede Naijiria, NDLEA ti tẹ iya, ẹni ọdun marundinlọgọrin to n ta oogun oloro nipinlẹ Eko.

Afurasi ọhun ti orukọ n jẹ Sekinat Soremekun ni ọwọ tẹ lọjọ Ẹti, Ọjọ kẹdogun oṣu kejila ọdun 2023 ni agbegbe Oshodi nipinlẹ Eko pẹlu ọpọlọpọ oogun oloro ati lita ogun oloro oni mimu ni akata rẹ.

Agbẹnusọ NDLEA, Femi Babafemi ni iya naa salaye pe ọmọ rẹ ti orukọ rẹ n jẹ Segun, ẹni to ti fẹ sẹ fẹ bayii lo n ko oogun oloro wa fun iya naa lati ta.

“Awọn osisẹ NDLEA nipinlẹ Eko, lọjọ Ẹti, ọjọ kẹdogun, oṣu kejila mu iya agbalagba kan, ẹni ọdun marindinlọgọrin, Sekinat Soremekun pẹlu oogun oloro.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

“Lasiko ti ọwọ ofin ba iya naa ni agbegbe Oshodi nipinlẹ Eko, ọpọlọpọ oogun oloro Canabis ati lita ogun mimu codeine ni wọn gba lọwọ iya naa.

“O ni ọmọ oun, Segun, ẹni to ti salọ bayii ni o ma ko awọn oogun oloro naa wa fun oun lati ta.

Bakan naa ni NDLEA tun ni awọn gbe ẹsẹ le ile kan to wa ni agbegbe Victoria Garden City ni Lekki ti wọn n lo lati fi pe lo oogun oloro methamphetamine.

NDLEA kede pe ọwọ tẹ afurasi kan, Okenwa Chris Nzewi, to si foju ba ile ẹjọ nibi ti ileẹjọ si ti palasẹ pe ki ijọba apapọ gbe ẹsẹ le dukia naa.

“Ọwọ tẹ Okenwa pẹlu akẹgbẹ rẹ Sunny Okeh Ukah ni ọgbọnjọ oṣu keje ọdun 2022, ti wọn si ti ka ẹsun mẹrin si wọn lẹsẹ ni ileẹjọ giga to n joko nipinlẹ Eko.”