Iléeṣẹ́ ológun Israel ṣèèṣì ṣekúpa àwọn ẹlẹ́wọ̀n mẹ́ta ní Gaza

Oríṣun àwòrán, Mọlẹbi
Ileeṣẹ ologun orilẹede Israel ti kede pe awọn seesi sekupa awọn ẹlẹwọn mẹta kan ti wọn jẹ ọmọ orilẹede Israel to wa ni ahamọ ni Gaza lọjọ Ẹti.
Atẹjade to jade lati ọdọ ileeṣẹ ologun ni awọn ikọ ologun ro pe awọn agbebọn ni awọn ẹlẹwọn mẹta.
Yotam Haim, Alon Shamriz ati Samer El Talalqa ti wọn le diẹ ni ẹni ogun ọdun ni ileeṣẹ ologun sina bolẹ fun, ti wọn si jẹ pe Ọlọrun.
Awọn oloogbe mẹta yii wa lara awọn eeyan ti ikọ Hamas jigbe lọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2023.
Ileeṣẹ ologun ni ọkan lara ọmọ ologun ri awọn ẹlẹwọn mẹta naa ni ile afọku kan, ti wọn ko wọ ẹwu sara, ti wọn si fi asọ funfun kọ igi.
“Ẹru ba ọmọ ologun naa to si sina bolẹ lẹsẹkẹsẹ, to si n pariwo pe awọn agbebọn niwọn.
“Meji laarin awọn ẹlẹwọn naa ku lẹsẹkẹsẹ, ti eeyan kan to farapa si fẹsẹ fẹ.”
Ileeṣẹ ologun ni ko pẹ ni awọn gbọ ariwo ẹgbawa ni ede Hebrew, ti Ọga ologun to lewaju si palasẹ pe ki wọn dawọ duro.
Ẹlẹwọn to pariwo fun iranlọwọ naa pada jade laye.
Ileeṣẹ ologun ni o seese ki awọn ẹlẹwọn mẹta naa ri aye lati saa kuro ni ahamọ ikọ ologun Hamas ti wọn wa.
Ọkan lara osisẹ ileeṣẹ ni nnkan to waye lodi si ofin ati ilana ileeṣẹ ologun pe ki wọn sian bolẹ lai se iwadii to tọ.
O ni isekupani jẹ ohun to banilọkan jẹ pupọ, to si jẹ ko di mimọ pe iwadii to yẹ yoo bẹrẹ lori isẹlẹ naa.
O fikun pe awọn ti kọ ẹkọ pẹlu nnkan to waye yii, ti awọn si ti fi iwe ofin ati ilana ransẹ si awọn ọmọ ologun kaakiri.















