Ọmọ mi sọ pé nígbà tí òun jẹ oúnjẹ ní ilé ẹ̀kọ́ ni inú bẹ̀rẹ̀ sí ní ro òun - Obi

Àkọlé fídíò, Ọmọ ní nígbà tí òun jẹ oúnjẹ ní ilé ẹ̀kọ́ ni inú bẹ̀rẹ̀ síní ro òun - Obi

Ni ọjọ Aje ọsẹ to kọja, ọjọ kọkanla oṣu kejila ni iroyin jade pe awọn akẹkọọ kan lati ile ẹkẹ akọbẹrẹ St James niluu Osogbo dero ile iwosan lẹyin ti wọn jẹ ounjẹ ti ijọba pase fun wọn.

Awọn Obi awọn akẹkọọ naa ba BBC Yoruba sọrọ lori bi awọn ọmọ naa se n diwọmọnu lẹyin ti wọn de si ile lati ile ẹkọ.

Fatia Kudirah, to jẹ obi ọkan lara awọn akẹkọọ ni kete ti ọmọ oun de lo ni oun jẹ ẹyin kan ti ko dara lati jẹ.

“Ọmọ ni bi oun ṣe jẹ ẹyin naa ni inu bẹrẹ si ni ro. Mo ni nigba ti o mọ pe ounjẹ naa ko da kilode ti o fi jẹ.

“Ohun ti a ri niyen ti ọmọ si bẹrẹ si ni ma bi.

Aworan

Irewumi Omolara, to jẹ obi si akẹkọọ mẹta ni ile ẹkọ naa ni bi awọn oun se pada de ni wọn bẹrẹ si kigbe pe inu n ro wọn, ti wọn si bẹrẹ si ma yagbẹ, ti wọn si tun bi.

“Mo bere pe ki wọn jẹ, awọn ọmọ ni ile ẹkọ awọn ni awọn ti jẹ irẹsi ati ẹwa pẹlu ẹyin sugbọn a wọn ri pe ẹyin ti awọn jẹ o run si awọn.

“Bi awọn ọmọ se n bi ni wọn yagbẹ ti wọn dẹ tun ti sọ gbogbo ara nu silẹ nitori pe o ti rẹ wọn.

“Bi mo se bọ sita pe ki maa pariwo ni mo ri awọn akẹgbẹ wọn kan ti awọn naa pariwo pe ki wọn gba wọn.

“A sare gbe awọn ọmọ naa lọ si ile iwosan.

Kọmiṣọnna eto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Osun, Kolapo Alimi, sọ fun BBC Yoruba sọ pe kii ṣe ounjẹ tawọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ St. James Primary school, l’Osogbo jẹ lo mu wọn dero ile iwosan.

Họnọrebu Alimi fikun ọrọ rẹ pe ''awọn ọga ile ẹkọ yẹn sọ pe gbogbo ounjẹ ti wọn maa n gbe wa sile ẹkọ naa lawọn maa n yẹwo kawọn ọmọ to bẹrẹ si ni jẹ ẹ,''

Awọn alaṣẹ ile ẹkọ yii tun ṣalaye pe laarin ago mọkanla si mejila lawọn ọmọ ile ẹkọ maa n jẹun, ko si si ọmọ to sọ pe inu n run oun ti wọn fi lọ sile nibi ago meji.''

Kọmiṣọnna ni ''pẹlu gbogbo iwadii ati ayẹwo awọn dokita, kii ṣe ounjẹ tawọn ọmọ yii jẹ lo ṣe okunfa inu to bẹrẹ si ni run lalẹ.