Hard Drugs: Ṣé lóòótọ́ ni pé àṣìlò oògùn lè la ikú lọ? Àbọ̀ wa rèé

Àkọlé fídíò, Hard Drugs: Ǹ jẹ́ ṣé lóòótọ́ ni pé àṣìlò ògùn le lakú lọ? Àbọ̀ wa rèé

Ọpọ awọn ọdọ lorilẹede Naijiria lo ti dero ọrun nitori wọn fẹran lati ma lo awọn oogun kan lati mu ara wọn da tabi lati yara si isẹ.

Bẹẹ naa si ni awọn ọdọ ti sọnu ninu aye latari isẹ buruku ti awọn oogun kan se ninu agọ ara wọn

BBC bọ si igboro lati bere lọwọ awọn araalu paapa awọn ọdọ pe ki lo fa ti wọn fi fẹran lati mu awọn oogun wọn yii.

Ninu alaye wọn, ọkan lara awọn ọdọ yii salaye pe orukọ orisirisi ni orukọ ti awọn n pe igbo, eyi ti yoo fun awọn ni anfani lati ma jẹ ki awọn eeyan mọ nipa nnkan ti wọn n mu.

Yusuf sọ BBC pe yatọ si Igbo ti ọpọ mọ si, awọn orukọ miiran fun igbo ni ‘Ọja’, ‘eskay’, ‘Janja’ ati awọn mii.

Aworan

Oríṣun àwòrán, BBC/Getty images

O ni igbo mimu lo ma jẹ ki oun le jẹun daada.

“Ti mo ba ti mu igbo yẹn tan, ma le jẹun daadaa.

“Ti n ko ba ti mu igbo, mo le ma jẹ irẹsi #200 tan, sugbọn ti n ba ti mu igbo yẹn, mo le jẹ irẹsi #600, mo le jẹ ju iyẹn gan lọ.

Ismail ni oun fẹran igbo minu, ti oun ko si le lọ lojumọ kan lai ma mu igbo.

O ni ki oun to jade, oun ma mu igbo, ti oun ba dẹ tun de ni alẹ, oun ma tun fa ki oun to sun

“Iru emi, lojumọ kan, ti mi o ba mu, isẹ ti mo n se ko ni wa si mi lara daada.”

Ki ni dokita sọ nipa asilo oogun?

Sunday Amosun, Dokita agba ni ẹka ile iwosan aisan ọpọlọ salaye ohun to n jẹ asilo oogun lilo ati awọn ipele ti awọn oogun wa

Amosun ni gbogbo ohun ti eeyan ba mu lọ si ẹnu, to jẹ pe to ba de inu ọpọlọ, a nise pẹlu isesi, ihuwasi ni ohun ti a n pe ni oogun Psychoative Substance.

“Awọn oogun yii pin orisirisi meji, Licit ati illict, ipele keji ni awọn illict, eyi ti ko ba ofin mu, Igbo, ohun lo se pataki ninu ibẹ, Cocaine, Heroin, Gbana ati awọn mii.

“Sewari ninu awọn eyi to ba ofin mu ni awọn oogun bi oogun oorun, bi oogun ara riro, ibẹ ni a ti ri Diazepam, Valium, Lexotan, ibẹ ni awọn iyẹn wa, dokita le kọ fun wọn nitori pe wọn ri orun sun.

“Sugbọn ti eeyan ba lọ da ara oogun fun ara rẹ, iyẹn ni a n pe ni asilo,”

Ẹ wo fọnran yii lati mọ nipa asilo oogun ati ohun ti ofin orilẹede Naijiria sọ lori oogun lilo