Báwo lo ṣe leè dá ayédèrú ohun mímu mọ̀ lákokò ọdún yìí?

Oríṣun àwòrán, NAFDAC/TWITTER
Ajo to n moju to ounjẹ ati oogun lorilẹede Naijiria (NAFDAC) ti rọ awọn araalu lati la oju wọn daadaa ki wọn too ra ohun mimu kọkan lakoko ọdun yii, yala o jẹ ọlọti abi ẹlẹrindodo.
Ajọ naa ni ki wọn maa wo ohun mẹrin to ṣe pataki bii ibi ti wọn ti fẹẹ raja, oye ti wọn n ta ọja naa, bi ọja naa ṣe ri ati irufẹ ọja to jẹ, ki wọn to ra ohunkohun.
Amọran yii lo wa latọwọ NAFDAC lẹyin ti ajọ naa pẹlu atilẹyin awọn agbofinro wọ ọja Eziukwu (ti a mọ si ọja Cemetry) nilu Aba, nipinlẹ Abia, lapa ila-oorun guusu Naijiria.
Ajọ naa lo wọ ibutaja to le ni ojilelugba ninu ọja naa ti wọn ti sọ di aaye ipọti, nibi ti wọn ti n ṣe ayederu ohun minu leyi to n fa ipalara fun araalu.
O le ni ẹẹdẹgbẹjọ paali ayederu ohun mimu ti ajọ na bajẹ ninu ọja naa, ti wọn si ko ọọdunrun paali lọ agọ wọn.
Oye ti wọn lee ta awọn ọti ti wọn bajẹ ati eyi ti wọn ko lọ lo le ni aadọtalelẹẹdẹgbẹrin miliọnu naira.
Ajọ naa wi pe awọn mẹwaa ni wọn mu ninu ọja naa ti yoo foju ba ileẹjọ lẹyin ti iwadii ba pari.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Seaman Schnapps, Hennesy atawọn nkan mimu loriṣiriṣi ni wọn ṣe ninu ọja naa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi NAFDAC ṣe wi ninu atẹjade wọn, “lara awọn ohun buruku ti wọn n ṣe ninu ọja yii ni ṣiṣe ayederu oniruuru ọti bii Seaman Schnapps, Henessy, Four Cousins, Carlo Rossi, Jenney, Chelsea London Dry Gin, Schnapp Dry Gin, McDowells, Black Labels, Gordons, Martell, Campari, Smirnoff ice, Eva Non-Alcoholic Drink, Evra Non-Alcoholic Drink, Cartel ati bẹẹbẹẹ lọ.
“Bakan naa ni wọn tun n yi ọjọ ti awọn ọja bii peak milk, miliki oniyẹfun, ketchups, yoghurt ati Coca Cola yoo bajẹ pada, ti wọn n sun-un siwaju.
“Gbogbo ọja ayederu yii ni wọn maa n ṣe lọjọ ti wọn si maa n ta fun awọn araalu ti ko nimọ nipa ohun ti wọn n ṣe.”
Ajọ naa ni awọn ibutaja ti wọn sọ di ile ipọti naa lo dọti, ti wọn si n lo omi ti ko dara, kẹmika buruku, awọn aloku igo ti ko mọ, ayederu ọra, atawọn nkan miran.
“Kẹmika buruku ni wọn npo pọ fawọn araalu”
Ninu atẹjade ti ajọ NAFDAC fi lede, ọga-agba ajọ naa, Ọjọgbọn Moji Adeleye, ṣalaye ọna ti wọn fi n ṣe awọn ayederu ọti yii.
O wi pe niṣe ni wọn maa n po oriṣiriṣi kẹmika oloro pọ mọ awọn pọkulowo orisun ṣuga ati sitaaṣi, atawọn nkan miran ti ko dara fun agọ ara.
Eyi lo n waye lakoko ti ọpọ ọmọ Naijiria, paapaa julọ awọn gbajugbaja olorin ati oṣere n kede lori ẹrọ ayeluja pe ayederu ohun mimu ti pọ nigboro.
NAFDAC waa rọ awọn araalu lati bun ajọ naa gbọ ti wọn ba kẹẹfin ẹnikẹni abi aaye ti wọn ti n pọn ayederu ohun mimu lagbegbe wọn.
Ṣe ajọ to n moju to eto ilera lagbaye, WHO, lo ti fi lede ṣaaju ninu ijabọ wọn lori ọti ati eto ilera pe o le ni miliọnu mẹta eeyan to padanu ẹmi wọn jakejado agbaye latari mimu ohun oloro latara ọti.
Bakan naa ni ajọ to n ṣe iwadii arun jẹjẹrẹ lagbaye, IARC, wi pe ọkan ninu awọn mẹwa to ba ni arun jẹjẹrẹ ni Naijiria lo nii ṣe pẹlu ọti, to si jẹ pe o le ni ida mẹrin ninu ọgọrun awọn to ni arun jẹjẹrẹ ni Naijiria lọdun 2019 to jẹ pe ayederu ọti lo ṣe okunfa rẹ.
Ọna ti o le fi da ayederu ohun mimu mọ ree

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ NAFDAC ni ki awọn araalu o maa wo awọn orukọ ati nkan miran ti wọn kọ sara ohun mimu ti wọn ba fẹẹ ra daadaa ki wọn too raa.
Lara ohun ti wọn ni ki wọn maa wo ni:
Aaye ti wọn ti fẹẹ raja: Awọn oriko itaja ti ajọ NAFDAC ba fọwọ si nikan ni ki wọn ti maa raja.
Oye ti wọn n taa: Ti ohun ti ẹ ba fẹẹ ra ba ti wa ni ẹdinwo ju bo ṣe yẹ lọ, abi wọn ko fi owo-ori ọti to yẹ ki wọn fi lee, ẹ funra.
Apoti abi ami ara rẹ: Awọn ohun ti wọn kọ sara apoti ati beba ti o wa lara ohun mimu naa lo gbọdọ ba ara wọn mu, to si gbọdọ yatọ si ayederu. Orukọ ileeṣẹ ati nọmba ẹrọ ilewọ awọn to ṣee gbọdọ wa nibẹ. Ki wọn si tun woo daadaa pe wọn ko tii ja ori ọti naa. Bakan naa ni wọn le fi foonu wọn wọ ila ami idanimọ to wa lara rẹ ti yoo fihan lori ayelujara boya ojulowo ni abi ayederu.
Ọja naa funra rẹ: Awọn ọja teeyan ba fẹe ra ti oorun rẹ ba da bii ti ohun ti wọn fi n ṣi ọda lara ile abi eekanna lo jẹ ayederu dajudaju.
Kini awọn ewu to rọ mọ mimu ayederu ọti?
Ajọ NAFDAC wi pe lara awọn ohun ti ayerederu ohun mimu lee fa ni:
- Inu riru
- Eebi
- Inu didun
- Ki oju o maa ṣu
- Ki ooyi o maa koni
- Eeemi ti ko delẹ
- Ki awọ ara o ṣi
- Ki ara o tutu lodi abi ki eeyan o ma mọ ibi to wa mọ
- O lee ba kidinrin ati ẹdọ jẹ, o si lee fa iku
- Methanol to jẹ ọkan lara awọn ohun ti wọn lee lo fun ayederu Vodka lee fa ifọju.












