Ẹ wá gbọ́ nípa ìjọ kan ní Kenya tó f’ààyè gba àlùfáà àti ọmọọ̀jọ tó bá n ṣe ìbálòpọ̀ akọ s’ákọ àbí abo s’ábo

Ijọ kan to n faaye gba awọn to ba n ṣe ibalopọ akọ si akọ ati abo si abo lorilẹede Kenya lo ti lo ọdun mẹwaa nipamọ nitori pe wọn kii kede isin wọn.
John, to jẹ alufaa nijọ kan tẹlẹ ko too darapọ mọ wọn sọ fun BBC pe “lọjọ akọkọ ti mo wọnu ijọ naa, niṣe ni mo bu sẹkun”.
Ọkunrin naa lo kuro ninu ijọ to wa tẹlẹ tori wọn sọ fun-un pe irufẹ ibalopọ to nifẹ si lo jẹ ẹṣẹ tori pe o lodi si ofin Ọlọrun.
“N ko nigbagbọ nile aye mi pe mo le sọrọ mẹta kan nibi kan leyi tawọn eeyan yoo ro pe wọn tako ara wọn. Eeyan dudu ni mi, alufaa ni mi, mo si nifẹ ibalopọ akọ si akọ.”
John, to di alufaa ninu ijọ naa bayii, lo gbọ nipa rẹ lori ẹrọ ayelujara – bo tilẹ jẹ pe ọrọ ẹnu ni ọpọ ninu wọn fi mọ nipa ijọ naa.
Awọn ọmọ ijọ naa ni kii dede sọ nipa rẹ fun ẹnikẹni ayafi ti wọn ba ti fidi rẹ mulẹ pe ara wọn ninu ẹni naa.
Asọyepọ to wa laarin gbogbo wọn nipe aabo ara wọn ṣe pataki.
Orilẹede Kenya fofin de ibalopọ akọ s’akọ amọ ileẹjọ to gaju lorilẹede naa yi ifofinde kan pada lọdun yii to mu ki wọn faaye gba wọn lati fi orukọ silẹ gẹgẹ bii ẹgbe ti kii ṣe ti ijọba.
Ẹwẹ, ijọ yii ko lero lati fi orukọ silẹ nitori ogun ti awọn araalu gbe ti wọn ati aba aṣofin kan lati tunbọ maye nira fun wọn.

Pauline to jẹ olufẹ ibalopọ abo si abo to si maa n lo ọrọ arọpo orukọ bii ‘awa’, ‘ẹyin’ ati ‘awọn’ wa lara awọn to kọkọ bẹrẹ ile ijọsin ọun to bẹrẹ bii kiko awọn ọrẹ jọ ko too di pe wọn gbooro sii.
Lati ọmọ ọdun mejila ti baba rẹ ti jade laye ni Pauline ti n koju ikorira nitori kokoro HIV to pa baba rẹ.
Pauline wi pe “lẹyin ti baba a mi ku,awọn eeyan bẹrẹ si nii korira wa. Wọn ro pe gbogbo wa lo ni kokoro naa. Abọ ati ife ọtọ ni wọn fi n fun iya mi lounjẹ, ti wọn ko si gba ka wọ awọn aaye kan mọ. Lara awọn aaye naa ni ile ijọsin tori pe wọn ri iya a mi bii ẹni eeri”.
Pẹlu ọpọ ibeere nipa igbesi aye e wọn , Pauline atawọn ọrẹ rẹ bẹrẹ sii pade lọjọ isinmi lati wo iwaasu loju opo YouTube, ti wọn si n pe awọn miran bii tiwọn lati darapọ mọ wọn.
Gbogbo eleyii lo n waye lakoko ti igbogun ti ibalopọ akọ s’akọ lagbara gan lapa ila-oorun Afirika.
Akoko yii ni orilẹede Uganda to mule ti wọn gbe ofin to lagbara kan kalẹ to tako ibalopọ ako s’akọ nilẹ naa.
Awọn ọmọọjọ yii ko nigbagbọ pe ohun ti awọn kereje kora jọ lati bẹrẹ lọdun mẹwaa sẹyin yoo ni ju igba eeyan bayii.
Pupọ ninu wọn ni wọn le kuro nile ijọsin ti wọn wa tẹlẹ
Ariyanjiyan kan laarin Regina ati ọkan lara awọn ti wọn jijọ n ṣeto ninu ijọ lo da wahala silẹ leyi to mu ki awọn ti wọn jọ n ṣeto naa ni ko fọwọ mo ọkan ninu awọn abi ololufẹrẹ rẹ, lẹyin ti wọn gbọ pe o ni ọrẹbinrin.
Regina fọwọ mu ọrẹbinrin rẹ amọ o ni “o dabi gba ti wọn ba fi ọbẹ ẹyin jẹyan niṣu nitori emi ni mo kọ gbogbo wọn ki wọn too sọ pe mi o le si laarin wọn mọ”.
Lẹyin ọpọ ọdun, Regina n wa bi oun yoo ṣe pada sagbo igbagbọ ti yoo gba bi oun ṣe ri. Eyi lo muu de inu ijọ yii.
O wi pe “o ni akoko kan to dabi ẹni pe n ko ri aaye ba Ọlọrun sọrọ mọ. Gbogbo nkan ti mo n gbọ ni pe ẹlẹṣẹ ni mi. To ba si jẹ pe adura la fi n ba Ọlọrun sọrọ, bawo ni n o ṣe gbaa?
“Dide ti mo de aarin agbo igbagbọ yii ti mu mi gbagbe gbogbo ọgbẹ ọkan atẹyinwa.”
Ijọ naa ti ri ọpọ ipenija

Ko rọrun fun ijọ yii atawọn olujọsin nibẹ nitori ọpọ idujukọ ti wọn ri bii igba ti baba onile le wọn kuro nile ati bi awọn alabagbe ko ṣe dunnu si wọn.
Wọn ti tiwọn mọta ri nigba kan pẹlu pe wọn sanwo ile, wọn ti jawọn lole ri, ọlọpa ti ko wọn lọpọ igba ti wọn si n beere abẹtẹlẹ lọwọ ọ wọn fun idaabobo, nigba miran wọn tun maa n ti wọn mọle lẹyin ti wọn ba na wọn.
Igba mẹsan-an ni wọn ti sa kuro lati oriko kan si omiran laarin ọdun mẹwaa lojuna ati farapamọ.
Ọkan lara ohun to le julọ fun wọn lati ṣe ni mimu awọn ọmọ ijọ duro ninu igbagbọ.
Fun apẹẹrẹ, ijọ naa ni ẹda “ijẹwọ igbagbọ” ti wọn maa n ka ni ibẹrẹ isin leyi to bẹrẹ pẹlu “mo nigbagbọ ninu Ọlọrun, baba wa alagbara, oluda ọrun ati aye” ati bẹebẹe lọ.
Pauline wi pe “gbogbo wa la nifẹ si ijẹwọ igbagbọ yii amọ o ni awọn nkankan ti ko si ninu rẹ.
“Ko si idanimọ awọn obinrin ninu rẹ to si jẹ pe a ni lati fi sii. A ri Ọlọrun baba ati Ọlọrun ọmọ. Eyi faaye gba gbogbo eyan.”
Ila akọkọ ninu ijẹwọ igbagbọ ti wọn ka pe “a nigbagbọ ninu Ọlọrun, aṣẹda wa, to da wa bii ayanfẹ ọmọ rẹ to n ṣe ibalopọ akọ s’akọ ati abo s’abo”.
Bakan naa ni ilana isin wọn faaye gba ki awọn ti ko lee foju han lara wọn o lọ ile ijọsin nigboro ki wọn too darapọ mọ wọn.
Pauline wi pe “nigba ti a bẹrẹ, gbogbo wa lo n bẹru taa si dakẹ nipa awọn iṣoro ti a n dojukọ.
“Eyi lo mu ka da ẹgbẹ “chat and chew” silẹ, nibi ti awọn olujọsin ti n sọrọ nipa bi wọn ṣe n la idojukọ wọn kọja gẹgẹ bii onibalopọ akọ s’akọ lorilẹede Kenya.”
Amọ bi igbogun ti awọn eeyan bii Pauline ṣe n gberu sii ni Kenya, o wi pe pupọ ninu wọn ni ko lee jade sita mọ bo tilẹ jẹ pe wọn fẹ ki ijọ naa tẹsiwaju.
Gbogbo orukọ taa lo ninu iroyin ni a yipada nitori aabo awọn ti ọrọ naa kan












