Afenifere ké gbàjarè sí Ààrẹ Tinubu: Wà ojútùú sí ìṣẹlẹ ìjínígbé tó ń peleke sí ní àwọn ìpínlẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, ÀWÒRÁN,TWITTER/D.OLUSEGUN
Ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ ọmọ Yoruba, Afenifere, ti figbe ta lori bi ijinigbe ti ṣe gbalẹ láwọn ipinlẹ Eko,Ogun,Oyo, ati lawọn ipinlẹ mii ni iwọ oorun Naijiria ati Naijiria lapapọ.
Agbẹnusọ ẹgbẹ naa Jare Ajayi, lo rọ aarẹ Bola Tinubu lati koju awọn ipenija oṣelu ọrọ aje ati awọn mii tí agbẹnusọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ Peter Afunaya tọka si gẹgẹ bi okunfa ìṣẹlẹ ijinigbe ati iwa janduku to gbode.
Bẹẹ naa ni Afenifere bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ikọlu tàwọn adigunjale ṣe s'awọn ile ifowopamọ meji ni Ikere ipinlẹ Ekiti.
Ninu iṣẹlẹ yi awọn ẹsọ Amọtẹkun mẹta kan padanu ẹmi wọn t'awọn mii si farapa.
Wọn tun mẹnu ba iṣeku pani adari eto inawo kan to n ba ijọba ipinlẹ Ogun ṣiṣẹ,Taiwo Oyekanmi ni ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣù Kọkànlá 2023 ni Abeokuta.
Afenifere sọ pe awọn tun gbọ iroyin pe wọn ji awọn eeyan meje kan pe lọjọ Aje ti wọn si pa eeyan kan ni Fidiwo lopopona marose Eko si Ibadan.
O tun fikun pe lọwọ ipari oṣu Kẹwaa awọn ijinigbe labẹle kan waye ni Ikotun,Okota,Ejigbo Alomosho,Egbeda,Agege ati Amuwo Odofin ni ipinlẹ Eko.
Afenifere fi ẹdun ọkan wọn han pe ni bi ọ ṣe ku ọsẹ diẹ ki ọdun Keresimesi to waye ninu ipaiya l'awọn arinrinajo fi n bọ soju popo tori ìbẹru ki wọn ma ko si ọwọ ajinigbe.
"Awọn ilu nla nikan kọ ni iṣẹlẹ ijinigbe yi ti n waye tabi ni awọn opopona nla
Ti aba foju wo bi nkan ṣe n lọ yi. Ni paapa awọn ijinigbe lapa Oke Ogun lẹnu ọjọ mẹta yii.Lara awọn aaye yi ni Saki, Okaka, Otu, Komu ati Offa n'ipinlẹ Kwara"
Afenifere sọ pe awọn alaṣẹ ko mọ bi nkan ṣe n lọ bayii tori naa o ṣe dandan ki ààrẹ koju ọrọ yi pẹlu gbogbo agbara to wa ni ikapa rẹ.
Lakotan wọn sọ pe awọn ajinigbe yi n gbe laarin awọn eeyan to wa ni agbegbe wọnyii












