Mọ̀lẹ́bí Mr Ibu ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ lórí ìròyìn tó gbòde pé wọ́n tún ti padà gé ẹsẹ̀ rẹ̀ kejì

Aworan Mr Ibu

Oríṣun àwòrán, Mr Ibu

Mọlẹbi ilumọọka adẹrinposonu oṣere tiata Naijiria nii John Okafor ti tan imọlẹ si iroyin to gbode lori ipo alaafia rẹ.

Okafor ni ọpọ eeyan mọ si Mr Ibu.

Ni ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kejìlá ni iroyin gbode pe ilera rẹ ti buru ju tatẹyinwa lọ ati pe awọn dokita ti ge ẹsẹ rẹ kan toku.

Awọn ileeṣẹ iroyin labẹle kan gbe iroyin sita pe ààrẹ ẹgbẹ awọn oṣere,Actors Guild of Nigeria (AGN), Emeka Rollas sọ pe wọn ti ṣe iṣẹ abẹ mii lati ge ẹsẹ Mr Ibu ati pe ko le sọrọ.

Amọ ṣa, mọlẹbi rẹ kan, Valentine Okafor, ninu ọrọ to fi soju opo Instagram Mr Ibu ti wa tan imọlẹ si ipo ilera rẹ.

Okafor sọ pe wọn ko ge ese Mr Ibu ati wi pe ẹsẹ alakọkọ ti wọn ge ni wọn tun ti ṣe iṣẹ abẹ mii.

“Akọkọ ni pe a fẹ sọ di mimọ pe wọn ko ṣe iṣẹ abẹ lori ẹsẹ baba wa mejeeji bi kii ṣe pe ẹyọkan pere ni wọn ṣe. Iṣẹ abẹ alakọkọ kú die tori naa ni wọn fi tun ṣe lori ẹsẹ ti wọn ti ge tẹlẹ ki a ma ba padanu ẹmi rẹ."

Bẹẹ ni arabinrin Okafor salaye.

O ni mọlẹbi tun salaye pe ẹjẹ didi ati awọn ailera mii ni aisan to n daamu Mr Ibu, kìí ṣe àìsàn itọ ṣuga tàwọn eeyan n gbero.

O fikun ọrọ rẹ pe idi tawọn ko tii gbe Mr Ibu lọ si oke okun ni pe awọn dokita sọ pe ko le koju irinajo lọ silẹ okere.

O ni iwe ti wọn fi ti alaye yi lo mu ki o nira lati ri ileeṣẹ ọkọ ofurufu tí yoo gbe lọ si oke okun lọ gba itọju.

"Lọwọ bayii ile iwosan to tobi julọ to si dara ju ni a gbe Daddy si ti wọn si pese awọn dokita to péye lati tọju wọn."

Mọlẹbi wa fi da awọn ololufẹ Mr Ibu loju pe ara rẹ ti n ya ki wọn si ma tẹti si ahesọ ọrọ to n ja kaakiri nipa ilera rẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ni ọjọ Kẹfa oṣù Kọkànlá ni mọlẹbi Mr Ibu kede pe wọn ge ẹsẹ rẹ lẹyin to foju wina iṣẹ abẹ meje.

Ninu atẹjade mọlẹbi sọ pe ko si nkan tàwọn dokita le ṣe fun ju wi pe ki wọn ge ẹsẹ rẹ yi nigba naa lọ.

Oṣere tiata ẹni ọdun mejilelọgọta yi ti kopa ninu aimọye ere sinima to fi mọ Keziah,9 wives ati Mr Ibu in London.

Igba akọkọ kọ ni yi ti ailera oṣere yi yoo deti igbọ araye.

Ni oṣu Kẹta ọdun 2022 Mr Ibu kede pe oun jẹ ounjẹ to sakoba fun ilera rẹ.

Ọmọ ipinlẹ Enugu ni John Okafor, oṣere adẹrinposonu ati soro sọrọ yi jẹ.

Odu lo jẹ l'agbo tiata ni Naijiria to si ni ọpọ ololufẹ to ma n wo ere sinima rẹ.