Adẹ́rìnínpòṣónú Mr Ibu bẹ̀bẹ̀ ìrànwọ́ ọmọ Nàìjíríà lórí àìsàn tó lè mú kí wọ́n gé ẹsẹ̀ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, realmribu/Instagram
Gbajugbaja oṣere adẹrininpoṣonu nni, John Ikechukwu Okafor, ẹni ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Mr Ibu lo ti pariwo sita lori bẹẹdi ile iwosan to wa pe ki awọn eeyan, paapaa awọn ẹlẹyinju aanu ti wọn jẹ ololufẹ oun dide iranlọwọ fun oun, latari aisan kan to da a gunlẹ.
Oṣere naa, ẹni ọdun mejilelọgọta naa lo pariwo yii sita lẹyin ti apa kun un pẹlu bi o ti na owo pupọ sori aisan ọhun.
Ninu fọnran ti o gbe jade loju opo ayelujara Instagram rẹ lo ti ni adura ati iranlọwọ loun nilo bayii, ki wọn mọ ba ge ẹsẹ oun, nitori pe ko si ibi toun tun fẹẹ gba mọ.
Mr Ibu sọ lori ibusun aisan to wa pe "bi ẹ ṣe n wo mi yii, mo ti wa lori idubulẹ aisan fun ọpọlọpọ ọsẹ bayii, ohun ti mo n reti lati ọdọ yin ni adura ati iranlọwọ yin.
Mo ṣi wa ni ọsibitu bi mo ṣe n ba a yin sọrọ yii.
Alakoso eto ilera ni ọsibitu ti mo wa yii ba mi sọrọ, o si jẹ ki n mọ pe bi gbogbo ọgbọn toun n da lori aisan mi ko b ṣiṣẹ, ohun ti yoo dara ni lati ge ẹsẹ mi.
Ẹ kan wo mi bi mo ṣe wa yii, bi wọn ba ge ẹsẹ mi, nibo ni mo fẹẹ lọ bayii?
Ẹ jọwọ, ẹ gbadura fun mi, ẹ ba mi ba Ọlọrun alagbara sọrọ, nitori pe mi o fẹ ki wọn ge ẹsẹ mi.
Ẹ ṣeun mo dupẹ. Ọlọrun a bukun fun yn yin."
Ẹ ṣaanu baba mi - Jasmine, ọmọ Mr Ibu bẹbẹ
Ẹwẹ, Jasmine Okafor to jẹ ọmọ agba oṣere naa sọ pe o ti to ọsẹ meji bayii ti baba oun ti wa lori idubulẹ aisan ni ọsibitu.
O rawọ ẹbẹ si awọn ẹlẹyinju aanu lati dide iranlọwọ, ki wọn le gbe ọkunrin naa lọ si oke okun fun itọju to pe ye.
Ninu ọrọ rẹ, o ni "gẹgẹ bii mọlẹbi, a fẹẹ fi wakati yii rawọ ẹbẹ si ẹyin eeyan lati ṣaanu baba mi.
Lati igba aisan yii ti bẹrẹ ni mo ti n na owo loriṣiriṣi, nitori ti mo ro pe ohun ti mo le da ṣe ni.
Gbogbo ohun to wa ni ikawọ wa laa ti ṣe, gẹgẹ bii mọlẹbi, nitori ti a ro pe ohun ti a le da ṣe ni, ṣugbọn sibẹ, ara baba mi ko ya.
Ko si iyatọ rara lori aisan yii; ni awọn ọjọ kan, yoo dabi ẹni pe ara ti ya ni, ṣugbọn awọn ọjọ miran, yoo tun dabi ẹni pe niṣe ni aisan naa n peleke sii.
Ọkan lara awọn ọsibitu to dara julọ niluu Ekoo ni a wa, wọn si fẹẹ sọ pe ka lọ si ọsibitu miran, nitori pe gbogbo itọju ti wọn n ṣe ko yatọ nibi.''
Kii ṣe igba akọkọ ree ti Mr Ibu yoo wa lori dubulẹ aisan.
Ninu oṣu kẹta, ọdun 2022 ni agba oṣere naa dubulẹ aisan, ti wọn si daa duro si ọsibitu kan niluu Abuja.
Nigba naa lo sọ fun awọn akọroyin pe awọn ara abule oun lo fun oun ni majele jẹ ni igba meji ọtọọtọ, iyẹn lakoko toun lọ ṣe abẹwo siluu abinibi oun to wa ni apa iwọ oorun Nkanu nipinlẹ Enugu.












