Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko pàṣẹ ìyọnípò DPO lórí ẹ̀sùn jìbìtì

Oríṣun àwòrán, Benjamin Hundeyin/X
Ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki wọn yọ ọga ọlọpaa ẹkun Meiran lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan oun ati awọn ọlọpaa abẹ rẹ.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Benjamin Hundeyin lo kede iroyin naa lori ikanni ayelujara X rẹ, to si ni awọn ko le gboju fo iwa ibajẹ nidi iṣẹ naa.
Ọkunrin onimọ ẹrọ kan, Ibrahim Saliu lo fi ẹsun kan ọga ọlọpaa ẹkun Meiran naa wi pe wọn gba owo ti ko din ni ẹgbẹrun lọna igba naira lọwọ oun, lẹyin ti wọn ti oun ati aburo oun, Ọlaiya Murtala mọle, iyẹn ni opin ọsẹ to kọja.
Saliu sọ pe ẹsun ti wọn fi kan awọn ni pe wọn n beere kaadi idanimọ aburo oun, ati pe wọn tun n beere iwe ti aburo oun fi ra foonu ọwọ rẹ.
Idi ree ti ọkunrin naa fi sọ pe awọn ọlọpaa yii fi ti oun ati aburo oun mọ atimọle, ko to di pe wọn gba ẹgbẹrun lọna igba naira lọwọ oun.
Salisu loun tun ṣalaye fawọn ọlọpaa pe foonu ni oun n ta, ati pe ṣọọbu oun ko jina si agọ ọlọpaa gan an ṣugbọn wọn kọ eti ikun.
Hundeyin ninu ọrọ to kọ si ojo opo ayelujara X rẹ, pe kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Idowu Owohunwa ni DPO ọlọpaa ẹkun Meiran naa ko yẹ lẹni to n dari.
Bakan naa lo sọ pe ọga ọlọpaa naa ati gbogbo awọn ti ọrọ kan lori ẹsun ilọnilọwọgba naa ti wa ni olu ileeṣẹ wọn, nibi ti wọn yoo ti foju wina ofin.















