Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Bukola Saraki sanwó ìtọ́jú Mr Ibu nílé ìwòsàn?

Aworan Bukola Saraki ati Mr Ibu

Oríṣun àwòrán, Instagram/Saraki ati Mr Ibu

Saaju ni iroyin kan jade pe Aarẹ ile igbimọ asofin tẹlẹri lorilẹede Naijiria, Dokita Abubakar Bukola Saraki ti san gbogbo owo ile iwosan ti wọn fi maa tọju gbajumọ oṣere, John Okafor, ti ọpọ mọ si Mr Ibu.

Bakan naa ni Martins Black Vincent ti ọpọ mọ si Verydarkman naa bọ sita pe irọ ni iroyin to ṣo pe Saraki san gbogbo owo ile iwosan naa.

Ileeṣẹ BBC News Yoruba kan si Ileeṣẹ Abubakar Saraki Foundation ati mọlẹbi John Okafor ti wọn si fidi ohun to wa waye mulẹ fun wa.

Ileeṣẹ ABS salaye pe o titọ ni pe awọn ti san owo ile iwosan Mr Ibu sugbọn owo ile iwosan eyi to wa tẹlẹ ni awọn san, ti wọn si ti gbe kuro nibẹ bayii lọ si ile iwosan miiran.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Yinka Otukoko ba ileeṣẹ BBC News Yoruba sọrọ, salaye pe fọnran to jade eyi ti VeryDarkMan ti ni irọ ni pe Saraki san gbogbo owo ile iwosan ni ko kuna to ati pe ile iwosan ti Mr Ibu wa tẹlẹ ni awọn ti san owo rẹ, ti awọn si fi ẹri sita.

“Ko le sọ pe irọ ni, ti ẹ ba gbọ ohun to sọ ninu fọnran naa, o ni ile iwosan ti Mr Ibu wa tẹlẹ ni Saraki ti san owo ile iwosan rẹ.

“Ko si nnkan to jẹ mọ pe Bukola Saraki ko san owo ile iwosan Mr Ibu, Ile iwosan to ba bayii ni wọn ti n ṣe awọn ayẹwo mii lo n sọ, sugbọn mo n fidi rẹ mulẹ pe a san owo ile iwosan.

“Ti ẹ ba ri aworan ti a gbe sita, a fi fọnran sita ati ẹri ti a fi san owo ile iwosan Mr Ibu.”

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Ki ni mọlẹbi sọ lori ọrọ yii?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa ni ileeṣẹ BBC News kan si mọlẹbi John Okafoe ti ọpọ eeyan mọ si Mr Ibu pe ṣe lootọ ni Adari ile igbimọ aṣofin tẹlẹri, Bukola Saraki san owo ile iwosan Mr Ibu.

Ọkan lara awọn mọlẹbi to ba Ileeṣẹ BBC sọrọ ni Ileeṣẹ ABS kan si mọlẹbi pe awọn fẹ san gbogbo owo ile iwosan, ti wọn si fesi pe ko ṣeeṣe lati san gbogbo owo ile wosan eeyan to ba si wa ni ile iwosan.

O ni oun to ya mọlẹbi lẹnu nibi Ileeṣẹ ABS ṣe kede lori ayelujara pe awọn ti san gbogbo owo ile iwosan Mr Ibu, to si jẹ pe diẹ lara rẹ ni wọn san

"O ṣeeṣe koko ka sọrọ nipa iroyin yii, awọn Ileeṣẹ yii kesi wa pe awọn fẹ san gbogbo owo ile wosan baba wa. a dẹ sọ fun wọn pe wọn ko le san gbogbo owo ile wosan nigba ti eeyan ba si wa ni ile iwosan.

"A sọ fun wọn pe wọn ti ni ka ma lọ si ile wosan miiran, ti a ko si mọ iye owo ti a ma san nibẹ. Ile iwosan ti a n lọ bayii jẹ ile wosan to tun ga ju ti tẹlẹ lọ, ti wọn si ni gbogbo ohun itọju ti baba wa nilo ki wọn to gbe lọ si oke okun fun itọju.

"Nigba ti wọn pe wa, owo ti a jẹ ni ile wosan yẹn jẹ ọpọlọpọ milọnu, emi gan ti san owo diẹ nibẹ.

"Owo ti n ko ri san yii ni ni ile iwosan ti tẹlẹ yii ni Ileeṣẹ ABS san fun wa, iyẹn owo ti jẹ silẹ ni ile iwosan, ti a dẹ sọ fun wọn pe a ko mọ iye ti a ma san ni ile iwosan tuntun yii.

"Ninu owo ti awọn eeyan da fun wa ni ati san ọpọlọpọp milọnu mii fun pe ki wọn ma ba itọju lọ ni ile iwosan tuntun ti a wa bayii.

"Ohun to ya wa lẹnu ni pe Ileeṣẹ ABS gbe sita pe awọn ti san gbogbo owo ile iwosan baba wa, to si jẹ pe ohun ti wọn ṣe ni pe wọn san owo ti jẹ ni ile iwosan ti tẹlẹ.

"Eri sisan owo ti wọn gbe sita lo jẹ ti ile iwosan ti tẹlẹ, ko ki ṣe eyi ti a wa bayii.

"Ko ki n ṣe pe a ko dupẹ lọwọ wọn sugbọn pe wọn san gbogbo owo ile iwosan baba wa, iyẹn ni ọrọ to jina sotọ."

Ki ni ABS Foundation gbe jade sita?

Ileeṣe to maa ran awọn eeyan lọwọ to jẹ ti Dokita Abubakar Bukola Saraki Foundation, ni ọjọ Ẹti ọjọ kejidinlogun osu kẹwa ọdun 2023 ni ajọ naa ti san gbogbo owo ti wọn maa nilo lati ṣe itọju Mr Ibu ni ile iwosan naa.

“Inu wa dun lati le ṣe iranlọwọ fun Ọgbẹni John Okafor ti ọpọ mọ si Mr Ibu, adẹrinposonu to ti n mu inu wa dun lati ọpọlọpọ ọdun.

“Nigba ti a gbọ nipa ilera rẹ ati a i ri owo fun itọju ara rẹ, a ri pe ohun to yẹ ni ki a pese iranlọwọ fun un ni gbogbo ọna ti a le gba ṣe iranlọwọ. A ti san gbogbo owo ti yoo nilo lati ṣe itọku ara rẹ.

“A tun wa kesi awọn ọmọ Naijiria lati tun bọ ṣe iranlọwọ fun Mr Ibu nipasẹ owo, adura ati awọn ọna miiran.”

Tebagbagbe pe awọn irawọ orin ni Naijiria pẹlu awọn gbajumọ lawujọ bi Davido, P-Square ati Tunde Ednut ti ṣe ileri lati ṣe amojuto awọn inawo Ile-iwosan Mr Ibu.

Awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ni gbogbo agbaye ti bẹrẹ lati ṣe alabapin ninu didawo lati ṣe atilẹyin fun oṣere ti o ni ailera naa.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Ohun to yẹ ko mọ nipa Mr Ibu

  • Wọn bi John Ikechukwu Okafor ni ọjọ kẹtadinlogun ọdun 1961, ti ọpọ si mọ si Mr Ibu
  • O jẹ adẹrinposonu ati oṣere tiata.
  • O wa lati ijọba ibilẹ iwọ oorun Nkanu nipinlẹ Enugu.
  • O ti kopa ninu sinima toto igba niye bakan naa, o tun fi igba kan kọ orin.
  • O gbe orin’The Girl’ ati ’Do you know’ jade lọdun 2020.