Adájọ́ bínú dìde kúrò níbi ìgbẹ́jọ́ ‘Tani Olohun’, àlàyé rèé

Aworan ile ẹjọ majisireeti ti igbẹjọ Tani ọlọhun ti n waye

Igbẹjọ Abdulazeez Adegbọla ti ọpọ mọ si Tani Ọlọhun?’ tun tẹsiwaju ni ọjọ Ẹti ni ile ẹjọ Majisireeti nilu Ilọrin lori ẹjọ ibanilorukọjẹ ti awọn alfa ẹsin musulumi kan n fi kan an.

Koko ohun ti igbẹjọ ọjọ Ẹti da le lori naa ni lati mọ boya ile ẹjọ naa ni aṣẹ lati joko gbọ ẹjọ naa ati ọrọ bi wọn yoo ṣe gba beeli ilumọọka oniṣẹṣe naa ṣugbọn iṣẹlẹ to waye laarin awọn agbẹjọro rẹ mu ki adajọ majisireeti to n gbọ ẹjọ naa, Ibrahim Muhammed, binu dide to si sun igbẹjọ siwaju.

Amọṣa, gẹgẹ bi ọrọ ti ṣe n lọ lẹnu ọjọ mẹta yii laarin awọn agbẹjọro mejeji – Amofin Muftau Olobi ati Ademola Banks - to n pe awọn n ṣoju fun olujẹjọ naa, aigbọraẹniye tun waye laarinawọn mejeeji nile ẹjọ.

Ninu ile ẹjọ majisireeti to n gbọ ẹjọ 'Tani Ọlọhun?'

Bi ọrọ ṣe ṣẹlẹ nile ẹjọ

Awon mejeeji ni o peju si ile ẹjọ loni, agbẹjọro Olobi si lo kọkọ dide lati fi ara rẹ han, osi tun fi Ademola Banks han fun ile ẹjọ.

O ni iwe méjì ni awon ti gbe si ile ẹjọ, ọkan fun beeli, ekeji si jẹ atako pe ile ẹjọ ko ni asẹ lati gbọ ẹjọ naa.

Amofin Olobi tẹsiwaju pe awon ti fi ẹnu ko lati fa iwe ti awọn pe takoboya ile ẹjọ naa ni aṣẹ lati tẹsiwaju lori igbẹjọ naa,

O ni ohun ti awọn fẹ gbajumọ bayii ni ti titẹsiwaju pẹlu igbesẹ beeli ati gbigba oniduro fun olujẹjọ naa.

Bi o se n sọ ọrọ yi ni Amofin Ademola Bank ti wọn jọ n ṣoju fun ‘Tani Ọlọhun?’ dide, o ni oun lo yẹ ko sọrọ nipa jijọwọ iwe atako ti oun pe fun niwon igba ti oun wa ni ile ẹjọ.

O fi kun un pe, oun lo ti n ba ẹjọ naa bọ, ti o si yẹ ki Amofin Olobi to sẹsẹ de sinu ẹjọ fara balẹ lati gbọ agbọye lori rẹ.

Eleyi lo di awuyewuye laarin awọn mejeji.

Adajọ binu dide nitori aigbọraẹniye awọn agbẹjọro mejeeji

Ninu ile ẹjọ majisireeti to n gbọ ẹjọ 'Tani Ọlọhun?'

Adajọ Muhammed Ibrahim dasi ọrọ naa , o ni ki wọn gbiyanju lati gbọ ara wọn ye ki wọn si se ohun gbogbo ni ibamu pẹlu ofin.

Ọrọ yii ko tu irun kankan lara awon agbẹjoro onisẹse mejeeji yi pẹlu bi wọn ṣe kuna lati jami lori ariyanjiyan wọn niwaju ile ẹjọ naa.

Eyi lo mu ki Adajọ Ibrahim binu dide, o ni ki wọn mu ọjọ miran fun igbẹjọ laarin arawon o si wọ inu iyẹwu rẹ lọ.

Iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ lẹyin gbogbo eyi ni pe awon agbẹjọro olupẹjọ ati olujẹjọ fori kori, wọn si mu ọgbọn ọjọ oṣu kẹwaa fun itẹsiwaju igbẹjọ naa.