Àwọn èèyàn jáde lónìí fún ayẹyẹ ọdún Ifa nílùú Shao

Oni, ogunjọ osu Kẹwaa lo pe ọjọ karun un ti ayẹyẹ ọdun Ifa bẹrẹ niluu Shao, nipinlẹ Kwara.
Oni bakanna si ni gbogbo eniyan yoo tu yaya lati sajọyọ Ifa pẹlu oriṣiriiṣi awon orisa ilẹ Yoruba.
Ọjọ kẹẹdogun tii se ọjọ akọkọ ti eto naa bẹrẹ ni ọjọ ibo Esu, Ogun, Obaluaye, Orisala ati Egungun.
Wọn ṣe eleyii ''kí ìdáwọ́lé wa lè lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀, kí àwọn ajogun burúkú má ba wà dá ètò wa rú. ''
Egúngún ti o jade ni ọjọ naa duro fún kì ayé eeyan lè gún, ati pe kí àwọn tì wón tẹ ayé àti ìlú lè má jẹ́.
Ọjọ keji ni, ayẹyẹ Iyemoja ati Aje tẹle pẹlu ọpọlọpọ eto iwure ati gbigbe asa larugẹ.
Ajé wa fun ki ajé lè má bá wa fawọn olutaja.
Iyemọja wa fun kí òògùn lè máa jẹ́ fún gbogbo oloogum tí kìi ṣèké.
Ọjọ kẹta ni, ibọ Ọṣun kí ire tí ó bá nú wá lè kó lè padà bọ̀, tó bá d'ọjọ́ ogun, kó lè ba dìde.
Sango ati Ọya ni ọjọ kẹrin kí afẹ́fẹ́ ibi má ba fẹ́ wọ̀lú, kí ó lè fẹ́ ibi gbogbo lọ, kò lè fẹ́ ire gbogbo wá.
Ni toripe, tí wọn bá ń se ǹkan èeèwọ̀ ni ìjífi má ń ja
Ọjọ o tẹlee ni Ẹgbẹ́, ki àṣírí àwon ọmọ emèrè lè ba à tú. Kí wọn má bá kú ikú ìlemèrè, àti ikú àwọn ẹgbẹ́ ọ̀rùn lè má bo àṣírí àwọn tó bá ń bọ̀ wọn
Àwọn ayẹyẹ ti o tun ku ni, bíbọ Ògún láti fi lànà fún àwọn irúnmọlẹ̀ tí a fẹ́ rúbọ fún, kẹ́bọ lè fín, kẹ́bọ lè dà
Sànpọ̀nnán:(Ọbalúayé): kí ìgbónán àti àìsànkáìsàn má bá ja ìlú
Ọbàtálá (Òsà ńlá) kí ìpín olúkúlùkù lè ba sẹ sí rere gẹ́gẹ̀ bí àyànmọ́n rẹ ti rí















