Ayé dorí kodò! ọ̀gá àgbà iléẹ̀kọ́ fi ipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin lòpọ̀ pẹlú ''scissors''

Aworan ọmọde to joko

Oríṣun àwòrán, AFP

Ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Delta ti mu ọga ile ẹkọ girama kan lori ẹsun pe o lọ fi ipa ba akẹkọbinrin ọmọ ọdun mẹrin kan lo pọ.

Agbẹnusọ ọlọpaa ni ipinlẹ Delta, SP Bright Edafe fi idi ọrọ yii mulẹ fun BBC pe afurasi naa wa ni ahamọ ati pe awọn ko ni pẹ gbe e lọ si ile ẹjọ kete ti iwadii ba pari.

Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, afurasi yi jẹ ọga agba nile ẹkọ girama kan ni Agbor nipinlẹ Delta ti wọn si lo fi scissors ja abale ọmọdebinrin yi kobaa le ribi fipa baa lopọ.

Nigba ti ọmọde yi de ile, o bẹrẹ si ni ke irora fun iya rẹ nigba ti uiya rẹ si ṣayẹwo ara rẹ lo ba ri wi pe ẹjẹ wa loju ara rẹ.

Bibeere to beere lọwọ rẹ pe boo ni tẹjẹ ti ṣe jẹ lọmọ ba sọ pe ọga ileẹkọ lo gbe oun lọ si ile igbọnsẹ to gun oun labẹrẹ ko to fi scissors ja abale rẹ.

Kia ni iya ọmọ yi mu ẹjọ de ọdọ awọn ọlọpaa ti wọn si lọ mu ọga ileẹkọ taa n wi yi.

Iya ọmọ yi fi kun pe awọn eeyan ti n daamu oun pe ki wọn yanju ọrọ naa ni bonkẹlẹ amọ o ni oun ko gba ati pe idajọ ododo loun fẹ fun ọmọ naa.

Iwa ifipabọmọde lopọ n peleke si lawujọ

Ni nkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin niṣe laa n gbọ iroyin lorisi nipa awn to n fipa ba ọmọde lopọ jakejado Naijiria.

Ni ipinlẹ Rivers ẹka to n risi ọrọ ẹtọmọniyan nileeṣẹ ọlọpaa mu arakunrin ẹni ọdun mejlelogoji kan lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdọ ọmọ ọdun mọkanla kan lopọ nipa lagbegbe Eneka ni ijọba ibilẹ Obio-Akpor,ipinlẹ Rivers.

Ni ọjọ Aje ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹwaa ni awọn agbofinro mu baba yi to bi ọmọ mẹta tiẹ lẹyin tawọn araadugbo kan ta awọn agbofinro lolobo.

Iroyin taa gbọ ni pe oṣiṣẹ ileeṣẹ to n pọnpo rọbi ni arakunrin yi ti kii si saba wa nile.

Lawọn igba to ba wa nile ti iyawo rẹ ko si si nile a maa fipa ba ọmọ-ọdọ ton gbe lọdọ wọn lo pọ.

Ọjọ tiakara tu sepo, ọmọ ọdọ naa sa jade nigba to fẹ fipa baa lo p to si lọ fẹjọ ohun ti oju rẹ n ri fawọn alabagbe to wa ni itosi ọdọ wọn.

Bakan naa lawọn oṣiṣẹ ajọ aabo ara ẹni laabo ilu taa mọ si Nigeria Security and Civil Defence Corps to wa ni ipinlẹ Jigawa mu baba gba ẹni ọdun mẹrindinlọgọta kan lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ obinrin ọdun mẹrinla lajọṣepọ.

Unguwar Mani Quarters, ni ijọba ibilẹ Roni larakunrin yi n gbe.

Ninu atẹjade kan, agbẹnusọ ajọ naa CSC Adamu Shehu sọ pe awọn mu afurasi naa lọjọ Kẹrin oṣu Kẹwaa 2023 lẹyin ti ẹgbọn ọmọdebinrin naa fẹjọ sun pe afurasi yi fipa ba aburo oun to n ṣiṣẹ ọmọọdọ lọdọ rẹ lopọ.

O lo tun n fi okun mu mọlẹbi ọmọ naa lọrun pe ki wọn jẹ kioun ṣẹ oyun fun ọmọ ọhun.

Ayẹwo ti wọn ṣe nileewosan fihan pe oyun oṣu mẹrin ati ọsẹ meji lo wa ninu ọmọ naa.

Ajọ NSCDC ti wọ arakunrin yi lọsiwaju ileẹjọ ti iwadii si n tẹsiwaju lori awọn afurasi meji mii lati le mọ iru ipa tawọn naa ko ninu ẹsun to wa nilẹ yi.