Ọmọ ọ̀dọ̀ fipá bá ọmọ ọdún márùn-ún ọmọ ọ̀gá rẹ̀ lòpọ̀, ìwádìí bẹ̀rẹ̀

Omo ti won fi owo bo lenu

Oríṣun àwòrán, Others

Ọwọ́ ṣìnkún òfin ti tẹ ọmọ ọ̀dọ̀ kan, ẹni ọgbọ̀n ọdún fẹ́sùn wí pé ó fipá bá ọmọkùnrin, ọmọ ọdún márùn-ún tó jẹ́ ọmọ ọ̀gá rẹ̀ lopọ.

Ìròyìn ní ilé ìgbé wọn tó wà ní Mihango, ní Nairobi, orílẹ̀ èdè Kenya ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Ẹ̀sùn ìfipábánilopọ̀ ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà ń kojú níwájú ilé ẹjọ́ Makadara, tí wọ́n sì ti ní kí wọ́n fi sí àhámọ́ lórí ìwà tó wù.

Ní ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹjọ, ọdún 2023, ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé lẹ́yìn tó mú ọmọ náà kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Ọmọ ọdún márùn-ún náà sọ fún àwọn ọlọ́pàá lásìkò ìwádìí pé òun lọ sí yàrá òun lẹ́yìn tí òun kúrò ní ilé ẹ̀kọ́ láti pàrọ̀ aṣọ òun tí ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì wá bá òun nínú yàrá náà.

Ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ náà sọ fún òun pé òun ní nǹkan tí òun fẹ́ kí òun ṣe àti pé òun kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni.

Ó ṣàlàyé pé lẹ́yìn náà ni ọmọ ọ̀dọ̀ náà bọ́ aṣọ òun, gbé òun sí orí ibùsùn tó sì fipá bá òun lò pọ̀.

Ọmọ náà padà sọ fún àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí wọ́n padà délé.

Nígbà tí àwọn àwọn ọlọ́pàá ń ṣèwádìí, Akware ní lóòótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé àmọ́ tó yí òun padà nígbà tó dé ilé ẹjọ́ níwájú Adájọ́ Hellen Okwani.

Akware sọ fún ilé ẹjọ́ pé òun kò fi ipá bá ọmọ náà sùn, pé òun kàn ṣan ìdí fun lásán ni, pé òun kò ṣe nǹkan tí wọ́n kà sí òun lọ́rùn.

Ó sọ fún ilé ẹjọ́ gba ẹnu agbejọ́rò rẹ̀ pé ìyàwó ilé, tó ní ọmọ mẹ́ta ni òun, pé kí ilé ẹjọ́ jẹ́ kí òun máa jẹ́jọ́ láti ilé.

Adájọ́ Májísíréètì náà, Okwani ní kí wọ́n fi Akware sí àhámọ́ títí tí wọ́n fi máa gbọ́ ẹjọ́ gbígba béèlì rẹ̀ àti pé bóyá wọ́n máa gbé ẹjọ́ rẹ̀ lọ sílé ẹjọ́ gíga.

Lẹ́yìn náà ló sún ọjọ́ ìgbẹ́jọ́ mìíràn sí ọjọ́ Kejìlélógún oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023.