Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ariwo, Ààrẹ Tinubu yọ ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún tó yàn sípò alága Ferma

Oríṣun àwòrán, Imam Ibrahim Kashim Imam
Aarẹ Bola Tinubu ti yọ orukọ Onimọẹrọ Imam Ibrahim Kashim Imam to ti kọkọ fi orukọ rẹ ṣọwọ fun ipo adari igbimọ akoso ajọ to n mojuto atunṣe opopona apapọ FERMA kuro.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun aarẹ lori ọrọ iroyin ati ipolongo fi sita lỌjọbọ, o ni ni kiakia ni iyọnipo yi yoo waye.
Anjuri Ngelale sọ pe yiyọ alaga yi ko fọwọ kan awọn ọmọ igbimọ ti aarẹ yan pẹlu rẹ si atiu awọn mii to wa ni igbimọ alaṣẹ Ferma.
'' Aarẹ Tinubu ti paṣẹ ka yọ orukọ Onimọ ẹrọ Imam Kashim kuro gẹgẹ bi alaga ajọ to n mojuto iṣẹ Ferma.''
Atẹjade naa ko sọ idi ti aarẹ fi yọ orukọ onimọ ẹrọ to ṣẹṣẹ kẹkọ jade ni yunifasiti yi.
Lọjọ Aiku yi ni aarẹ yan ẹni ọdun mẹ́rinlelogun yi sipo alaga ajọ Ferma ti iyansipo yi si mu ọpọ awuyewuye wa loju opo ayelujara.
Loju opo agbẹnusọ aarẹ́ Ajuri Ngelaleto fi ọrọ yi sita, o ni Imam Kashim yoo dari akoso igbimọ Ferma fun saa ọlọdun mẹrin ti anfaani wa fun latitun ṣe saa mii lẹyin to ba pari.
Kashim di ọdọ keji ti aarẹ yoo yọ orukọ wọn lẹyin to ti ṣaaju kede iyansipo wọn labẹ ijọba rẹ.
Gẹgẹ bi ti arabinrin Maryam Shettima ti aarẹ yọ orukọ rẹ kuro lẹyin to fi sọwọ lara orukọ awọn to fẹ yan ni Minisita ariwo pọ lori iyansipo Kashim kete ti ikede jade lori rẹ.
Ta ni Imam Ibrahim Kashim Imam
Ọjọ Kẹtadinlọgbọn oṣu Kejila ọdun 1998 ni wọn bi Imam Ibrahim Kashim Imam
O kẹkọ jade ni fasiti Brighton ni ilẹ Gẹẹsi to si gba ami ẹyẹ First Class nidi imọ ẹrọ ọkọ.
O tẹsiwaju ni fasiti yi kanna nibi to ti kawe gbopye giga.
Ọdun 2022 lo pari eto isinru NYSC to si jẹ amugbalẹgbẹ fun Minisita to n ṣakoso iṣẹ David Umahi.
Kashim Ibrahim-Imam ni orukọ baba rẹ to si jẹ alaga lọwọlọwọ fun ajọ to n mojuto akoto idagbasoke ile ẹkọ giga Naijjiria taa mọ si TETFUND
Lọdun 2003 to dije dupo Gomina ni ipinlẹ Bornolabẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Peoples Deocratic Party, o fidirẹmi lọwọAli Modu Sheriff ti ẹgbẹ oṣelu All Nigeria Peoples Party ANPP.
Bakan naa ni baba yi tun fidirẹmi ninu idibo ọdun 2007 labẹ ẹgbẹ oṣelu kan naa lọwọ Sheriff to fẹyin rẹ janlẹ lọdun 2003.
Amọ ṣa labẹ ijọba aarẹ Tinubu, a yi ri awọn ọdọ miran to yan ti araalu ko si tako iyansipo wọn.
Koda ninu wọn, minisita wa ninu rẹ bi ti Jamila Bio Ibrahim to yan sipo Minisita fọrọ ọdọ ati Ayodele Olawande gẹgẹ bi Minisita keji fun ileeṣẹ to n mojuto ọrọ ọdọ.
Aarẹ ti burawọle sipo fun awọn mejeeji ti wọn si ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu.














