Ta ni Àmbásádọ̀ Sarafa Tunji Ishola, Aṣojú Nàìjíríà ní UK tí Ààrẹ Tinubu pàṣẹ pé iṣẹ́ rẹ̀ tó gẹ́ lẹ́yìn ọdún méjì tí Buhari yàn án?

Tunji Ishola

Aarẹ ana lorilẹede Naijiria yan Ambasadọ Sarafa Tunji Ishola ninu Oṣu Kinni ọdun 2021.

Amọ ninu lẹta kan ti minisita fun ọrọ ilẹ okere, Ambasadọ Yusuf Maltama Tuggar fi sita to si kọ ranṣẹ si Ọgbẹni Ishola bakan naa ni ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹjọ ọdun 2023, o fi lede pe ipinu yii ṣe ikede pe opin ti de ba saa Ishola gẹgẹ bi aṣoju ara ọtọ fun orilẹede Naijiria si ilẹ United Kingdom.

“Nipasẹ ọrọ yii, ireti wa pe koo bẹrẹ si ni kogba wọle bayii lẹnu iṣẹ rẹ ki o si gba aye fun isinmi lẹnu iṣẹ latọdọ ijọba to gba alejo rẹ laarin ọgọta ọjọ ki o si pada si orilẹede Naijiria titi ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹwa ọdun 2023,” atẹjade naa ka bẹẹ.

O tẹsiwaju pe: “Mo lo akoko yii lati fi idupẹ Aarẹ han fun iṣẹ ti o ti ṣe ni ipa tirẹ gẹgẹ bi aṣoju orilẹede Naijiria nilẹ United Kingdom.

“Bi a ṣe n reti lati ki ọ kaabọ ni ilu Abuja bi o ba pada de, dakun gba mi laye lati pawọpọ pẹlu aarẹ lati dupẹ lọwọ rẹ, Ọlọlajulọ fun jijẹ adari to ṣee fi ṣe awokọṣe ati iṣẹ takutakun rẹ fun orilẹede Naijiria. Mo gbadura ki Ọlọrun tubọ maa ṣọ ipasẹ rẹ ninu ohun gbogbo too ba n ṣe lọjọ iwaju.”

Aarẹ Tinubu ati Ambasadọ Tunji Ishola

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ohun to yẹ koo mọ nipa Ambasadọ Sarafadeen Isola Tunji

Wọn bi Sarafadeen Ishola Tunji ni ọjọ Kẹẹdọgbọn Oṣù Kọkànlá Ọdun 1960 n'ilu Abeokuta Ìpínlẹ̀ Ogun si idile àgbà oyè ilu Egba kan, Alhaji Ibrahim Isola Tairu ati iyawo rẹ Alhaja Amudalat Ajiun Isola.

Ishola ẹni ti ọpọ mọ si "STI" lọ si ile ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ Oke-Ona United Primary School ni ilu Ilugun, Abeokuta to si jẹ ọkan lara awọn ẹgbẹ́ oṣere ile ẹ̀kọ́ rẹ.

O ka ẹ̀kọ́ girama ni Nawair-ud-Deen Grammar School, Obantoko, Abeokuta.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lẹyin to pari Girama, Isola bẹ̀rẹ̀ iṣẹ gẹgẹ bi ontaja ni Ileeṣẹ ti wọn ti n ta ogun, Welcome Nigeria Limited.

Nigba to di ọdun 1978, o rinrinajo lọ si United Kingdom lati lọ ka iwe sii.

Isola kọ ẹ̀kọ́ gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ olupolowo ọjà.

Bakan naa ni o pari ẹ̀kọ́ ninu imọ idokoowo ni ile ẹ̀kọ́ South West London College ni Toothing Broadway, London lọdun 1981.

Oloye Isola padà si Naijiria lọdun 1982.

Ọdun 1983 lo sinru ilu gẹgẹ bi Agjnbanirọ ni ilu kan ni Ìpínlẹ̀ Kaduna nigba naa lọhun amọ to ti wa lara Ìpínlẹ̀ Katsina bayii.

Lasiko yii, o ṣe agunbanirọ gẹgẹ bi olùkọ́ni nile ẹ̀kọ́ awọn olùkọ́ni ti Katsina to si kọ oniruuru ẹ̀kọ́ bii ẹ̀kọ́ nipa ọrọ aje, Itaja, owo ṣíṣe ati onka.

Lọdun 1986 ni Ọgbẹni Ishola di oludari ẹ̀ka itaja ni Ileeṣẹ igbohunsafẹ́fẹ́ Ìpínlẹ̀ Ogun ni Abeokuta (OGBC).

Ẹwẹ, lọdun 1990, Oloye kọwe fi iṣẹ silẹ ni OGBC lati kara bọ idokoowo to nifẹ si to si mu ọgbọn rẹ gbooro síi.

Nigba to ya lo di alaga ati oludari Ileeṣẹ Taist Nigeria Limited.

Ọpọlọpọ iṣẹ takuntakun lo ti gbe ṣe lẹyin naa, lẹ́nu eyi si ni Ààrẹ ana, Muhammadu Buhari ti ri awọn iṣẹ ọwọ rẹ.

Ní ọdún meji sẹ́yìn ni Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Buhari wa yan an gẹgẹ bi aṣojú orileede Naijiria si ilẹ̀ United Kingdom amọ ti Ààrẹ tuntun Bola Tinubu ti dupẹ lọwọ rẹ bayii to si ni o ti gbìyànjú, ko maa bọ wale pe iṣẹ rẹ ti to.