Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn #EndSars, ṣe ìfìyàjẹni lọ́nà àìtọ́ lọ́wọ́ àwọn agbófinró dínkù?

Ní bí ọdún mẹ́ta sẹ́yìn ni àwọn ọ̀dọ́ káàkiri orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ṣe ìwọ́de láti fi ẹ̀hónú wọn hàn lórí bí àwọn ọlọ́pàá ṣe máa ń dá àwọn ọ̀dọ́ lọ́nà tí wọ́n sì máa ń pá wọn lára yálà lọ́nà gbígba owó tàbí ohun ìní mìíràn lọ́wọ́ wọn.
Lásìkò náà, àwọn ọ̀dọ́ tó bá jẹ́ ọkùnrin tó bá ní irun dàda tàbí irùngbọ̀n tó pọ̀ máa ń wọ gàù lọ́wọ́ àwọn ikọ̀ ọlọ́pàá Special Anti Robbery Squad, SARS.
Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló máa ń fẹ̀sùn kàn pé àwọn ọlọ́pàá kàn máa dédé da ọ̀dọ́ dúró lójú títì tí wọ́n sì máa gba gbogbo owó tó bá wà nínú akoto owó báńkì rẹ̀.
Àwọn mìíràn máa ń sọ bí ikọ̀ SARS ṣe dá ọgbẹ́ sí àwọn lára tàbí ṣekúpa ènìyàn tó sún mọ́ wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan yìí ni àwọn ènìyàn ń kọ sórí ayélujára.
Lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣokùnfà tí ìwọ́de náà fi wáyé ni bí ẹ̀mí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin kan tó wà ní ipele tó kẹ́yìn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Nnamdi Azikwe lọ́wọ́ ọlọ́pàá kan ní ọjọ́ Kẹrin oṣù Karùn-ún ọdún 2020.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àtàwọn mìíràn jẹ́ ohun tó mú àwọn ọ̀dọ́ dìde tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de káàkiri Nàìjíríà pé kí ìjọba wọ́gilé àwọn SARS kí àwọn ọ̀dọ́ lè rí imú mí.
Lẹ́yìn ìwọ́de tó ṣokùnfà kí ọ̀pọ̀ ènìyàn pàdánù káàkiri orílẹ̀ èdè yìí, ìjọba Nàìjíríà kéde tútú ikọ̀ SARS ká àti pé àwọn máa ṣe àfọ́mọ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò ọlọ́pàá láti ri dájú pé ìfìyàjẹni lọ́nà àìtọ́ kò wáyé látọwọ́ àwọn ọlọ́pàá mọ́.
Ǹjẹ́ àyípadà ti bá títẹ ẹ̀tọ́ àwọn ènìyàn lójú mọ́lẹ̀ látowọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn ọdún mẹ́ta?

Láti ìgbà tí ìwọ́de #EndSars ti wáyé, tí ìjọba sì ti kéde àwọn ìgbésẹ̀ kan tó fi mọ́ fífikún owó oṣù àwọn ọlọ́pàá ni àwọn ènìyàn Nàìjíríà ti ní èròńgbà pé àwọn ọ̀dọ́ kò ní máa kojú títẹ ẹ̀tọ́ wọn lọjú mọ́lẹ̀ bíi àtẹ̀yìnwá.
Amòfin Abdulfatah Adabaale tó bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ní bí àwọn ṣe máa ń gba ẹjọ́ láti ọ̀dọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń fẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá ti dínkù jọ́jọ́ ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ìwọ́de #EndSars.
Adabaale ní òun kò lè sọ pé àwọn ìwà títẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀ tàbí pa ènìyàn lọ́nà àìtọ́ látọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti dópin pátápátá àmọ́ àyípadà tó lòòrìn ti wà dáadáa.
“A ṣì ń rí pé àwọn ọlọ́pàá ń wọlé àwọn ènìyàn lọ́nà àìtọ́ ṣùgbọ́n àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ti dínku gidi.”
Ó ní ó jọ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Nàìjíríà ti ń fi ìyà tó tọ́ jẹ àwọn ọlọ́pàá nígbà tí wọ́n bá ti wu àwọn ìwà tí kò bá òfin iṣẹ́ wọn àti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà mú.
Ó wòye pé láìpẹ́ yìí ni ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Eko dájọ́ ikú fún ọlọ́pàá tó pa amòfin kan ní agbègbè Ajah ní oṣù Kejìlá ọdún 2022 lọ́nà àìtọ́.
Bákan náà ló ní ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́pàá ló ti pàdánù iṣẹ́ wọn látàrí ìwà tí kò tọ́ tí wọ́n ti wù sí àwọn ènìyàn.
Ó wòye pé bí àwọn ènìyàn ṣe ń gbé gbogbo àwọn nǹkan tó bá ń ṣẹlẹ̀ láàárín wọn àtàwọn ọlọ́pàá sórí ayélujára ti ń jẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá náà máa ti ọwọ́ ọmọ wọn bọ aṣọ.
Adabaale ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò lè ṣe kí àwọn kàǹda kọ̀ọ̀kan má sì nínú ìrẹsì pẹ̀lú gbogbo ìgbésẹ̀ tí ìjọba ń gbé yìí láti ṣe àfọ̀mọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá, àwọn kọ̀ọ̀kan ṣì wà tí wọ́n ń da àwọn ará ìlú láàmú.
Ó rọ àwọn ará ìlú náà láti máa ri dájú pé gbogbo àwọn nǹkan tó tọ́ kí wọ́n sì ri pé àwọn ń tẹ̀lé òfin nínú gbogbo àwọn nǹkan tí wọ́n bá dágbálé.
Ó fi kun pé òun gbàgbọ́ pé pẹ̀lú bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń ṣiṣẹ́ lásìkò yìí, ohun gbogbo máa bọ̀ sípò láìpẹ́ jọjọ tí kò sì ní sí ìwà títẹ ẹ̀tọ́ ènìyàn lójú mọ́lẹ̀.
Àwọn nǹkan wo ni ènìyàn gbọdọ̀ ṣe tí ó bá pàdé ọlọ́pàá?

Adabaale ní òfin Nàìjíríà fi ààyè gbà wọ́n láti fi òfin gbé ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá fura sí pé ó wùwà lòdì sí òfin tàbí tí wọ́n fura pé ó ní ẹrù tó lòdì sófin lọ́wọ́.
Ó ní fún ìdí èyí kò yẹ kí ènìyàn máa bá ọlọ́pàá ṣe àríyànjiyàn tí wọ́n bá dá ènìyàn dúró.
Ó ní ó dára kí ènìyàn báwọn sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tútù, kí ènìyàn sì dá wọn lóhùn gbogbo nǹkan tí wọ́n bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.
Bákan náà ló ní tó bá jẹ́ àwọn tí kò wọ aṣọ ni àwọn ọlọ́pàá ló dá ènìyàn dúró, kí ènìyàn fi ọ̀rọ̀ tútù bèèrè káàdì ìdánimọ̀ láti fi mọ ẹni tí wan jẹ́ gan.
Ó tẹ̀síwájú pé tí ọ̀rọ̀ tí àwọn ọlọ́pàá náà bá ń sọ bá ti ń kọjá àwọn nǹkan tó yẹ, ó gba àwọn ènìyàn lámọ̀ràn láti fi ẹ̀rọ́ ìbánisọ̀rọ̀ wọn ká ohun tó bá ń ṣẹlẹ̀ sílẹ̀, kí wọ́n sì máa fi sórí ayélujára.
Ó rọ àwọn ọlọ́pàá náà láti ri pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn lọ́nà tó wà ní ìbámu pẹ̀lú bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń ṣiṣk ní àgbàyé.
Ìwọ́de EndSARS pé ọdún mẹ́ta lónìí, a ò lè gbàgbé láéláé - Mr Macaroni

Oni ogunjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2023 ni o pe ọdun mẹta ti iwọde tawọn ọdọ ṣe lati tako iwa ipa awọn ọlọpaa sawọn araalu ti ọpọ mọ si EndSARS waye ni Lekki Tollgate niluu Eko.
Awọn ọdọ naa tu jade lọpọ yanturu fun bi ogunjọ lati fi ẹhonu han tako iwa ibajẹ awọn ọlọpaa SARS naa, ti wọn si n beere pe ki ijọba tu wọn ka.
Idi ree ti wọn fi pe akori iwọde naa ni EndSARS.
Gbogbo awọn olu ilu awọn ipinlẹ to wa ni guusu Naijiria atawọn ilu nla nla miran ni awọn ọdọ naa kora jọ si lati fi ẹhonu han.
Oriṣiriiṣi awuyewuye lo jẹyọ lati nibi iwọde naa eleyii to da họwu-họwu silẹ laarin awọn oluwọde ati ijọba.
Ijọba ipinlẹ Eko kọkọ sọ pe awọn sọja ko yinbọn pa ẹnikan ni Lekkitoll gate ni iwọde naa ti waye, ṣugbọn awọn oluwọde atawọn eeyan mii sọ pe ọpọlọpọ eeyan lawọn sọja ṣekupa nibi iṣẹlẹ ọhun.
Lara awọn alẹnulọrọ to ṣagbatẹru iwọde naa ni Adebowale Adedayo ti ọpọ mọ si Mr Macaroni WA.
Mr Macaroni ti sọ lawọn oju opo ayelujara pe o ti pe ọdun bayii ti iwọde naa waye.
O ni ''a o le gbagbe laelae.''
Mr Macaroni wa rọ awọn eeyan lati jade ki wọn si ṣe iranti awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ nipa rinrin loju titi lonii.
Ki lo ṣẹlẹ ni Lekki Tollgate?
Ni ogunjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2020 ni iṣẹlẹ yii waye ni agbegbe Lekki ni ilu Eko nibi tawọn ọdọ ti fẹhonuhan tako iwa ifiyajẹni awọn ọlọpaa si araalu papaa julọ awọn ọdọ.
Iwọde yii lo pada di ranto kaakiri awọn ipinlẹ lapa iwọ oorun guusu orilẹede Naijiria ti gbogbo agbaye si mọ sii.
Ọpọ eeyan lo sọ pe awọn sọja yinbọn nibẹ, amọ ijọba apapọ sọ pe ko si ẹri lati fidi rẹ mulẹ pe ẹnikan kankan ku nibi iwọde naa.
Ohun lo mu ki awọn ọdọ tun bọ sigboro lonii lati saami ọjọ naa.
Ajọ Amnesty International sọrọ lori iranti iwọde EndSARS
Ajọ aja fẹtọ ọmọniyan, Amnesty International sọrọ loju opo ayelujara X rẹ pe o ti pe ọdun mẹta ti iwọde awọn ọdọ tako iwa ipa awọn ọlọpaa SARS si araalu eleyii ti ''o kere tan awọn oluwọde tawọn ọlọpaa mu si tun wa ni ahamọ lọgba ẹwọn Kirikiri ati Ikoyi niluu Eko lai ti gbewọn lọ si ile ẹjọ titi di oni.
Ijọba orilẹede Naijiria naa ti fẹsun ole jija, didanusun dukia, gbigbe ohun ija oloro ati ipaniyan kan ọpọ awọn oluwọde.
Ọpọ ninu awọn to wa lahamọọ yii lo sọ pe wọn n fiya jẹ wọn.
Lasiko iwọde EndSARS yii, ijọba orilẹede Naijiria kuro oju si ikojọpọ awọn eeyan eleyii to mu ki awọn ọlọpaa atawọn oṣisẹ eleto abo mii ko ṣe nkan kan lori awọn janduku to n kọju ija sawọn olufẹhonuhan.
Nigba mii gan an, ọkọ ijọba lo maa n gbe awọn janduku yii lọ sawọn ibi ti iwọde ti n waye.''












