Àwa máa gba ọkọ̀ SUV tí ìjọba fẹ́ rà fún wa, iṣẹ́ ìlú la fẹ́ fi ṣe - Àwọn aṣòfin Labour Party fún alága lésì

Ilé aṣòfin àpapọ̀ àti àwọn ọkọ̀ SUV

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party tí wọ́n jẹ́ ọmọ aṣòfin ní ilé ìgbìms aṣòfin àgbà ní Abuja ti kọtí ọ̀gbọ̀in sí ìkílọ̀ alága ẹgbẹ́ náà, Julius Abure láti má gba ọkọ̀ bọ̀gìnì tí ìjọba ń gbèrò láti rà fún àwọn aṣòfin.

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kérìndínlógún oṣù Kẹwàá ni Abure fi àtẹ̀jáde kan síta pé níbi tó ti ní àwọn adarí ilé aṣòfin ń gbèrò láti ra ọkọ̀ bọ̀gìnì SUV tí iye rẹ̀ tó ọgọ́jọ mílíọ̀nù náírà fún aṣòfin kọ̀ọ̀kan.

Abure tó júwe èròńgbà náà láti ra ọkọ̀ fún àwọn aṣòfin náà bí ìgbà tí ìjóba kò mọ ohun tó kàn pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe rí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní àsìkò yìí.

Ó ní kò yẹ kí àwọn aṣòfin náà le ronú láti ra ọkọ̀ olówó iyebíye lásìkò tí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ti dẹnu kọlẹ̀ pátápátá, tó sì rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Labour Party tó wà ní ilé aṣòfin náà láti má gba ọkọ̀ náà.

Àmọ́ nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn bá àwọn aṣòfin tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party láti mọ ìhà tí wọ́n kọ sí àrọwà alága wọn yìí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ní àwọn máa gba ọkọ̀ náà.

Aṣòfin Ngozi Okolie tó ń ṣojú ẹkùn àríwá àti gúúsù Delta Aniocha nílé aṣòfin àgbà ní nǹkan tí Abure sọ kò lè ṣeéṣe nítorí kò sí bí àwọn yóò ṣe máa ṣe iṣẹ́ àwọn láìsí ọkọ̀.

Okolie ní ọkọ̀ SUV tí wọ́n fẹ́ rà fún àwọn wà fún pé kí àwọn lè máa ṣiṣẹ́ àwọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ́ àti pé tí Abure kò bá fẹ́ kí àwọn gba ọkọ̀ náà ó ní láti pèsè ọkọ̀ mìíràn fún àwọn.

“Lóòótọ́ ni ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà dẹnu kọlẹ̀ àmọ́ ọkọ̀ kan fún aṣòfin kò ì tíì pọ̀ jù, ohun tí a nílò ni.”

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó fi kun pé àwọn ọmọ Nàìjíríà máa ń bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn aṣòfin tí ìjọba àpapọ̀ tí wọ́n bá fẹ́ ra nǹkan tí yóò mú iṣẹ́ wọn gbèrú si tó sì ní nǹkan tí àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ ń jẹ àǹfàní rẹ̀ ju ti àwọn lọ.

Bákan náà ló fi kun pé ó rọrùn àti pé owó ti àwọn máa fi ra ọkọ̀ kéré dípò kí àwọn lọ máa yá ọkọ̀ lásìkò tí àwọn bá fẹ́ jáde lọ ṣiṣẹ́ lọ.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀, aṣòfin tó ń ṣojú ẹkùn Igbo Etiti àti Uzo-Uwani ìpínlẹ̀ Enugu, Stainless Nwodo ní ààrẹ Bola Tinubu yẹ lẹ́ni tó yẹ kí wọ́n máa gbóríyìn fún pẹ̀lú bí ó ṣe buwọ́lu ọkọ̀ náà fáwọn aṣòfin.

Nwodo ní kò sí ẹnikẹ́ni nílé aṣòfin àpapọ̀ tó lòdì sí ríra àwọn ọkọ̀ náà àti pé àwọn máa gbà á tí wọ́n bá ti kó wọn dé láti fi mú ìgbàdún ìṣèjọba bá àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣojú fún.

“Tí a bá wò ó dáadáa, ẹkùn kọ̀ọ̀kan wa ni àwọn ọkọ̀ náà wà fún kìí ṣe fún àwa aṣòfin.”

Ó fi kun pé òun kò gbàgbọ́ pé alága ẹgbẹ́ àwọn le sọ fún àwọn láti má gba ọkọ̀ nítorí kò fún àwọn ní ọkọ̀ mìíràn tí àwọn yóò máa lò láti fi ṣiṣẹ́.

Ó ṣàlàyé nítorí àwọn ọ̀nà Nàìjíríà tí kò dára ni ààrẹ ilé aṣòfin àgbà àti abẹnugan ilé aṣòfin ṣe ní kí àwọn ra SUV láti lè máa gbe wọ àwọn ọ̀nà ẹkùn ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn.

Sẹ́nétọ̀ Neda Imasuen tó ń ṣojú ẹkùn gúúsù Edo nílé aṣòfin àgbà ní ó dìgbà tí àwọn náà bá dé kí òun tó lè sọ bóyá òun máa gba ọkọ̀ náà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Imasuen ní àwọn aṣòfin mẹ́jọ péré ló jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ní ilé aṣòfin àgbà àti aṣòfin márùndínlógójì nílé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin nítorí náà kò lè sí ìyàtọ̀ kankan tí àwọn kò bá gba ọkọ̀ ọ̀hún.

Ó ní òun kò rò pé sísọ fún àwọn aṣòfin láti má gba ọkọ̀ látọwọ́ alága le da ohunkọhun.