Lóòtọ́ ni mo fi iṣẹ́ pásítọ̀ sílẹ̀, àmọ́ mo ti di Olùṣọ́ àgùntàn fún gbogbo ìlú Ogbomoso - Ọba Ghandi

Oba Ghandi Olaoye ati gomina Seyi Makinde

Ṣọun tuntun nilẹ Ogbomọṣọ, Ọba Ghandi Afọlabi Laoye, Orumagẹgẹ III, ti ni botilẹ jẹ pe oun ti fi iṣẹ Pasitọ silẹ ni ọkan lara awọn ẹka ijọ irapada, RCCG, to tobi julọ lorilẹede Amẹrika, oun ti di Oluṣọ Aguntan fun gbogbo ilu Ogbomọṣọ bayii.

Ọba Laoye fi ọrọ yii lede lẹyin ti o gba ọpa aṣẹ lati ọwọ Gomina Ṣeyi Makinde nibi ayẹyẹ igbọpa aṣẹ to waye ni papa iṣere Ṣọun ti ilẹ Ogbomọṣọ.

O ni Ọba ti oun jẹ kii ṣe fun awọn ẹlẹsin Kristẹni nikan, bikoṣe Musulumi, awọn Ẹlẹsin abalaye ati gbogbo ẹni ti ko ṣe ẹsin kankan.

Ṣọun tuntun ni botiwu ki ẹda lakaka to, Ọlọrun nikan lo le fini jẹ ọba.

O parọwa si awọn ti wọn jọ du ipo naa pe ki wọn gbagbe ọrọ ana, ki wọn si sowọpọ lati gbe ilẹ Ogbomọṣọ de ibi giga.

Ọba Laoye ni gbogbo imọ ati iriri ti oun ni nipasẹ iṣẹ Pasitọ ati okoowo nilu Amẹrika ni oun yoo papọ lati mu ilu Ogbomọṣọ gun oke agba.

O ni oun yoo ṣe agbekalẹ eto idagbasoke ọlọdun marundinlọgbọn fun ilẹ Ogbomọṣọ lati di ilu to ṣee mu yagan ju bayii lọ.

O dupẹ lọwọ gomina ipinlẹ Ọyọ, Gọmina Ṣeyi Makinde lorii bi o ti fi ọmọniyan ṣe lati mu ki ifẹ Olodumare ṣẹ lori iyansipo oun gẹgẹ bii Ṣọun ikọkanlelogun nilẹ Ogbomọṣọ.

Oba Ghandi

Wo awọn eeyan jankan-jankan to ti wa niluu Ogbomoso nibi ayẹyẹ gbigba ọpa aṣẹ Ọba Afolabi Ghandi Olaoye

Skip Facebook post, 1
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post, 1

Awọn eeyan jankanjankan kaakiri orilẹede Naijiria lo balẹ si ilu Ogbomoso bayi ni bi ayẹyẹ gbigba opa asẹ Ọba Afolabi Ghandi Olaoye gẹgẹ bi Soun ti ilu Ogbomoso.

Skip Facebook post, 2
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post, 2

Lara wọn ni, igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, Igbakeji Gomina ipinlẹ Kwara, Kayọde Alabi, alakoso iroyin fun aarẹ tẹlẹri, Lai Mohammed ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Awọn Ọba Alade naa ko gbẹyin.

Lara wọn ni, Ọọniriṣa Ile Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja II, Olu ilẹ Warri, Ogiame Atuwatse III, awọn aṣoju Olubadan ilẹ Ibadan, Oba Mohood Olalekan Balogun Alli, Olugbọn ile Igbọn, Ọba Francis Alao, Ọrangun Oke Ila Ọrangun, Oba Adedokun Abolarin, Ọwa Ajero tilu Ijero, Oluwo ilẹ Iwo, Oba Adewale Akanbi, Ọba Joseph Adebayọ, Timi Ilẹ Ẹdẹ, Oba Munirudeen Lawal, Laminisa I ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Soun Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, @Soun

Òní ni Oba Ghandi yóò gba ọ̀pá àṣẹ ní Ogbomọṣọ

Oni, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kejila, ọdun 2023 ni Oba Afolabi Olaoye Ghandi yoo gba ọpa aṣẹ lọwọ Gomina Seyin Makinde ni eyi ti yoo fi di Oba Soun ti ilu Ogbomoso ni ipinlẹ Oyo ni kikun.

Ori ti yoo d’ade, ko ni ṣalai de ade, ori ti yoo ba si jọba, ko ni ṣalai de ipo ibọ.

Bẹ gan an lọrọ ṣe ri pẹlu Afolabi Ghandi Olaoye ti Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ṣẹṣẹ kede gẹgẹ bi Soun Ogbomoso tuntun ṣe ri.

Bi Olaoye ṣe di ọba yatọ si bi ọpọlọpọ ṣe jẹ ọba nitori o jẹ ọkan lara awọn ori ade nilẹ Yoruba ti wọn ti fi igba kan ṣiṣẹ iranṣẹ gẹgẹ bi alufaa ijọ ri.

Gẹgẹ bi akọsilẹ ti ri, Ghandi kẹkọọ gboye ninu ede Gẹẹsi ni Naijiria ki o to rinrin ajo lọ si oke okun lati tẹsiwaju lẹnu ẹkọ rẹ nibi to tii kẹkọọ sii nipa ibaṣepọ laarin awọn oṣiṣẹ ati ileeṣẹ.

Ọdun 1992 ni Ghandi di pasitọ ijọ Redeemed, ko da ohun ti a gbọ ni pe kii ṣe ifẹ ọkan rẹ gan an lati jẹ ọba bi o tilẹ jẹ pe ipo naa tọ si i.

Ọ̀pọ̀ ori ade lo wa si Ogbomoso wa yẹ Oba Ghandi sí

Awọn miiran ni Olu tí ìlú Warri, Ogiame Atuwaise, Olugbọn tí orile Igbọn, Ọba Francis Alo, Ọba Oke Ila Ọrangun, Oba Adedokun Abolarin.

Aworan
Aworan
Aworan
Aworan
Aworan
Aworan