Olórin àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí wọ́n jígbé rí ìtúsílẹ̀ gbà

Aworan Ọmọọba ati awọn elegbe rẹ

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bayebest

Olorin juju, Omooba De Jombo Beats ti awọn ajinigbe gbe lọ pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ ti ri itusilẹ gba.

Saaju ni awọn ajinigbe kan ji De Jumbo Beats ati awọn ẹgbẹ rẹ lẹyin ti wọn pari ere, ti wọn si lọ lati ipinlẹ Kogi lọ si olu ilu Abuja.

Ninu ọrọ agbajugbaja olorin ẹmi, Adegbodu Twins fi sori opo ayelujara wọn lati kede itusilẹ De Jumbo, wọn dupẹ lọwọ Ọlọrun bi o gba silẹ lọwọ awọn ajinigbe naa.

Bakan naa ni wọn tun dupẹ lọwọ olorin fun bi wọn se da owo lati gba De Jumbo silẹ lọwọ awọn Ajinigbe.

Bẹẹ ba gbagbe, awọn ajinigbe naa bere milọnu mẹwaa naira fun ẹni kọọkan ti wọn jigbe ki wọn to le gba itusilẹ.

“A dupẹ lọwọ Jehofa, A dupẹ El shadai, Ọba awọn ọba, a dupẹ lọwọ awọn olorin to su gba wa lati da owo

”Gbogbo wa o ni sọnu, Ọmọọba ati awọn ẹgbẹ rẹ ti gba itusilẹ.”

Àwọn ajínigbé jí Olórin àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ gbé lọ nílùú Abuja

Olorin juju kan ti ọpọ mọ si Omooba De Jombo Beats ati awọn elegbe rẹ ni wọn ti kosọwọ awọn ajinigbe lasiko ti wọn ti ode bọ niluu Abuja.

Isẹlẹ yii lo waye ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu kejila ọdun 2023.

Olorin Juju mii, Adeyinka Adeboye ti ọpọ mọ si Boyebest lo kede isẹlẹ naa ninu ọrọ kan to gbe soju opo ayelujara Instagram ati Facebook rẹ.

“Gbogbo ẹgbẹ olorin ni wọn jigbe, nnkan ti se Naija.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

“Mo n gba ladura pe ki gbogbo pada de ni aaye.”

Awọn ẹgbẹ olorin yii ni wọn bọ sọ awọn ajinigbe lẹyin ti wọn sere tan nibi ayẹyẹ kan to waye niluu Abuja lopin ọsẹ.

Gẹgẹ Boyebests se salaye, o ni milọnu mẹwaa naira ni awọn ajinigbe na n bere fun lọwọ mọlẹbi.

“Ọmọọba ati awọn elegbe rẹ n irinajo lọ ipinlẹ Kogi lati ilu Abuja lẹtin ti wọn sere tan.

“A nilo iranlọwọ yin, awọn ajinigbe naa n bere fun milónu mẹwaa fun ẹni kọọkan wọn.”

Ọpọ awọn ololufẹ olorin naa ni wọn ti n fi adura ransẹ si wọn lakata awọn ajinigbe ti wọn wa.