Portable àti Pasuma rọ òjò àlùjó àti Zaazuu lé àwọn olùjọ́sìn lórí nínú ìjọ Cele

Portable ati Pasuma n krin nile ijọsin

Oríṣun àwòrán, CCC Land of Goshen/Facebook

Gbajumọ olorin takasufe, Habeeb Okikiola, ti ọpọ tun mọ si Portable, kọrin ninu ijọ Cele lọjọ Ẹti to kọja.

Portable patẹ alujo ninu ile ijọsin Celestial Church of Christ, Land of Goshen Cathedral, to wa ni agbegbe Ogudu, nipinlẹ Eko, lasiko ti wọn n ṣe isin aṣalẹ iyin, ti awọn elede Gẹẹsi n pe ni Praise Night.

Ọjọ diẹ sẹyin ni iroyin ti kọkọ gba ori ayelujara nipa bi ijọ awọn ọmọlẹyin Kristi ọhun ṣe fi iwe pe Portable to jẹ olorin ‘Aye’, ati akọrin mii, Pasuma to n naa jẹ akọrin Fuji.

Ọjọru, ọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu Kọkanla ọdun 2023 ni iwe ipe to n kede Aṣalẹ iyin naa jade sori opo ayelujara Facebook.

Yatọ si Pasuma ati Portable ti wọn jẹ olorin aye, awọn eleto naa tun pe ọmọbinrin olorin kan torukọ rẹ n jẹ May-Shua.

Ẹfanjẹliisi Sunday JP, tawọn eeyan tun mọ si De Governor, (Eebudọla 1 of Lagos) ni pasitọ to han ninu iwe ipe ọhun.

Ikede naa fa ariyanjiyan, paapaa laarin awọn Kristiẹni to gbagbọ pe ko bojumu fun iru awọn akọrin bẹẹ lati kọrin ninu ile ijọsin.

Olori ijọ Sele lapapọ Olatosho Oshoffa ni nkan bi ọsẹ kan sẹyin lo kede pe Portable ko ni kopa nibi isin aṣalẹ tawọn fẹ ṣe.

O ni oun ti ba ẹfanjẹlisti ijọ to fi ikede yi sita sọrọ ti o si ti gbọ agbọye pe awọn ko faaye gba olorin aye lati wa sibi eto isin ijọ naa.

Nigba ti ariwo ko rọlẹ lori ọrọ naa, adari ijọ kan tun pada kede pe Portable ko ni i wa sibi isin aṣalẹ iyin naa mọ, ṣugbọn akọrin naa ni dandan ni ki oun yoo kọrin bibẹ.

Iyalẹnu si lo jẹ nigba ti akrin takasufe ọhun gunlẹ sibi eto isin naa ni alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ karundinlogun, oṣu Kejila, to si kọrin lori itage.

Ninu fidio kan ti Ọgbẹni Portable fi si ori ayelujara Facebook rẹ, la ti ri i to n kọ lara awọn orin rẹ bi Zazoo, fun ẹgbẹẹgbẹrun eeyan to pejọ lati gbọ́, ti awọn naa si n kọrin tẹle e.

Yatọ si eyi, aṣọ funfun ti wọn n pe ni ‘Sutana’, eyi to jẹ aṣọ ti awọn ọmọ ijọ Cele ma n wọ, ni Portable wọ lati fi kọrin.

Skip Facebook post
Allow Facebook content?

This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Facebook post

Pasuma naa kọrin nibi aṣalẹ iyin

Portable nikan kọ lo kọrin nibi ipejọpọ awọn ọmọ ijọ naa, ogbontarigi akọrin Fuji, Wasiu Alabi ti gbogbo eeyan tun mọ si Pasuma, naa kọrin.

Ninu fidio kan ti ijọ CCC Land of Goshen fi si ori ayelujara Facebook wọn, ni Pasuma ti kọ awọn orin 'ẹmi' ati alujo Fuji.

Bo ṣe n kọ awọn orin naa ni awọn eeyan n gbè é.

Koda, nigba to to asiko kan, awọn kan ninu agbo jade si ori itage lati na owo fun akọrin naa.