Wo gbogbo ohun tí o ní láti mọ̀ nípa ìdìbò ààrẹ orílẹ̀-èdè DRC

Aworan awọn alatilẹyin olori alatako Moise Katumbi gada for im rally for Goma, North Kivu

Oríṣun àwòrán, EPA

Awọn oludibo bii ogoji miliọnu ni yoo jade lati dibo yan aarẹ tuntun ni orilẹede Democratic Republic of Congo (DRC), ni ogunjọ, oṣu Kejila, ọdun 2023.

Aarẹ Felix Tshisekedi lo n dije fun saa keji, ti yoo jẹ igba ikẹyin fun-un, ninu saa ọlọdun marun lori aleefa.

Democratic Republic of Congo lo wa ni ipo keji ninu awọn orilẹede to tobi julọ ni Africa. Awọn eeyan inu rẹ si to miliọnu mejilelaadọfa pẹlu oriṣiriṣi ohun alumọni.

Botilẹ jẹ pe awọn kan n pe fun ki wọn sun ibo naa siwaju, olori ajọ eleto idibo orilẹ-ede naa nigbagbọ pe ohun gbogbo yoo lọ bo ṣe yẹ.

Ki ni pataki idibo yii?

Aworan Aarẹ Felix Tshisekedi bo ṣe n ba awọn alatilẹyin rẹ sọrọ

Oríṣun àwòrán, AFP

DR Congo lo ni ida aadọrin ninu ọgọrun ohun alumọni coltan, to jẹ eroja pataki ninu awọn elo ti wọn fi n ṣe foonu, lagbaye.

Bakan naa ni wọn ni ida ọgbọn ninu ọgọrun okuta olowo iyebiye ‘diamond’ lagbaye, yatọ si ọpọ cobaly, copper ati bauxite to sodo sibẹ.

Bo tilẹ jẹ pe o yẹ ki awọn ohun alumọni yii atawọn ero to wa lorilẹede naa o mu agbega nla ba ọrọ aje wọn, rogbodiyan, iwa jẹgudujẹra ati iṣejọba ti ko dara lati igba ijọba amunisin ko jẹ kaye o rọrun nibẹ.

Ila-oorun DR Congo to ni eyi to pọ julọ ninu awọn ohun alumọni yii ni ko sinmi rogbodiyan lati bii ọgbọn ọdun sẹyin.

O ṣoro lati mọ oye awọn to ti ba rogbodiyan naa lọ – iwadii kan ti ‘International Rescue Committee’ ṣe lọdun 2008 wi pe awọn bii miliọnu marun ati egbẹrun lọna irinwo lo ti padanu ẹmi wọn, paapaa julọ latari ebi ati aisan, eyi to lagbara julọ lẹyin ogun agbaye keji, amọ awọn iwadii miran ti fihan p eyi ko fi gbogbo ara ri bẹẹ.

Lẹyin ọpọ ọdun ti wọn ti n koju wahala oṣelu ati iditẹgbajọba, DR Congo n ṣeto idibo fun igba akọkọ lẹyin ti Aarẹ Joseph Kabila gbejọba sile fun Tshisekedi lọdun 2019.

Awọn wo lo n dije?

Awọn alatilẹyin Dokita Denis Mukwege nibi ipolongo ibo

Oríṣun àwòrán, AFP

Lẹyin tawọn mẹfa, to fi mọ Olootu Ijọba Augustin Matata Ponyo, yọwọ nibi idije naa, oludije ogun lo ku bayi ti Tshisekedi si wa lara wọn.

Awọn to jẹ gbajumọ to lee fun Tshisekedi ni wahala ni:

  • Martin Fayulu ti ọpọ nigbagbọ pe oun lo jawe olubori lọdun 2018, bo tilẹ jẹ pe esi ti ajọ eleto idibo fi lede wi pe ipo keji lo ṣe.
  • Moïse Katumbi, oniṣowo to figba kan ri jẹ gomina lẹkun Katanga. Oun naa lo ni ikọ agbabọọlu TP Mazembe.
  • Dokita Denis Mukwege, ẹni to gba amiẹyẹ ‘Nobel Peace Price’ lọdun 2018 fun iṣẹ to n ṣe pẹlu awọn ti wọn fipa ba lopọ.

Mẹrin ninu awọn ti wọn yọwọ ninu idije naa lo ti kede atilẹyin wọn fun Katumbi ati ẹgbẹ ‘Together for the Republic’ to n ṣe, tawọn meji miran si atilẹyin fun Aarẹ Tshisekedi.

Awọn miran to tun n dije ni olootu ijọba tẹlẹri, Adolphe Muzito, Aṣofin Delly Sesanga, ajafẹtọmọniyan Floribert Anzuluni ati Constant Mutamba.

Obirin kan ṣoṣo to dije lọdun 2018, Marie-Josée Ifoku Mputa, lo tun pada dije lẹyin ti Omidan Bile jawọ nibi idije naa.

Kikopa ninu idije naa lo gba owo gọbọi.

Gbogbo oludije lo ni lati san ọgọjọ miliọnu owo ilẹ Congo ti wọn pe ni Congolese Francs, leyi to je ẹgbẹrun lọna ọgọta dollar.

Ẹwẹ, eyi ko to ẹgbẹrun lọna ọgọrun dollar ti wọn san lakoko eto idibo to kọja.

Bawo ni eto idibo naa ṣe ri?

Oludije to ba ni ibo to pọ julọ ni yoo di aarẹ, yala o ni to idaji gbogbo ibo ti wọn ba di abi ko nii. Eyi tumọ si pe ko nii si abala keji tabi atundi ibo.

Ẹni to ba di aarẹ ni yoo wa nipo fun saa ọdun marun, to si lee ṣe ẹẹkan pere sii.

Idibo yoo waye ni aadọrun ọjọ ṣaaju ọjọ ti saa aarẹ to wa lori aleefa yoo dopin.

Lọdun yii, eto idibo aarẹ ni yoo waye pọ mo idibo aṣofin apapọ ati ẹlẹkunjẹkun, to fi mọ tawọn ijọba ibilẹ.

Kini awọn ohun to wa nilẹ ṣaaju eto idibo yii?

Aworan ilu Bukavu lati oke

Oríṣun àwòrán, AFP

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Eto idibo ọdun yii lo n waye bo tilẹ je pe rogbodiyan n ṣẹlẹ ni ila-oorun orilẹede naa, idaamu nipa ọrọ aje ati ede aiyede laarin ijọba ati ẹgbẹ alatako.

Awọn ẹgbẹ alatako ni, awọn fura pe ijọba fẹe ṣe magomago ninu eto idibo naa, ati pe ijọba ko faaye gba oṣelu to bo ṣe yẹ to si n fungun mọ wọn, amọ ijọba ti sẹ ọrọ naa.

Gbogbo idaniloju tajọ eleto idibo (Ceni) n fi lede ni ko tilẹ mu ọkan awọn alatako walẹ rara.

Awọn biṣọọbu ijọ aguda nilẹ naa, atawọn adari ijọ ECC lo fi lede laipẹ pe ọkan awọn papọ mọ nkan tawọn alatako sọ.

Wahala bi awọn nkan ṣe gbowo lori naa ṣi wa nlẹ. Covid-19 to rekọja ati ogun to n ja ni Ukraine lo ni ipa to pọ lori inawo awọn olugbe ilẹ naa.

Afikun lori owo ọja ni ko jẹ kawọn eeyan o lee ra nkan bii ti atẹyinwa, bi wọn ṣe ni lati san ju oye ti wọn n san tẹlẹ lori ohun elo ati ounjẹ.

Ijakulẹ ti ba owo Congolese Franc pẹlu ida mẹẹdogun si ogun si owo dollar lati ibẹrẹ ọdun yii, gẹgẹ bi ijọba ṣe wi.

Aarẹ Tshisekedi lo ti gbe oniruuru igbesẹ lati koju eleyi, to fi mọ ẹkọ ọfẹ nileẹkọ alakọbẹerẹ ati ilera ọfẹ fawọn obinrin to baa fẹẹ bimọ nileewosan ijọba.

Ẹwẹ, ero awọn eeyan yatọ si ra wọn jakejado orilẹede naa lori bi awọn igbesẹ yii ṣe munadoko si.

Rogbodiyan lapa ila- oorun

Awọn ologun lati orilẹede Kenya ti wón n mura lati kuro ni DR COngo

Oríṣun àwòrán, AFP

Ijoba ti fofin de lilọ-bibọ awọn ero kaakiri ẹkun Ariwa Kivu ati Ituri fun bii ọdun kan amọ rogbodiyan ṣi n tẹsiwaju nibẹ.

Awọn ẹgbẹ ọlọtẹ bii M23, ADF ati Codeco ni wọn ṣi n ṣakọlu sawọn araalu atawọn ibudo ologun.

Latari iwa-ipa yii, DR Congo wa lara awọn orilẹede to ni awọn ogunlende julọ lagbaye. Awọn bii miliọnu mẹfa ati ẹgbẹrun mẹsan-an nigbagbọ wa pe wọn ti sa kuro nile lati oṣu Kẹta, ọdun 2022.

Ajọ iṣọkan agabaye, UN, wi pe ida mejidinlọgbọn awọn olugbe Ariwa Kivu ati ida mọkandinlogoji ni Ituri logun ti le kuro ni ile.

Awọn agbegbe miran tun ti foju han fun laasigbo abẹle bii ẹkun Tshopo nilaoorun-ariwa ati Maï-Ndombe ni iwọoorun-guusu orilẹede naa.

Eto abo to mẹhẹ lo ṣeeṣe ko ma nipa lori eto idibo lawọn aaye kan lorilẹede naa. Ninu oṣu kẹsan, ajọ eleto idibo wi pe awọn ti padanu oṣiṣẹ bii si akọlu awọn agbebọn ati ki wọn ba odo lọ lakoko iforukọsilẹ.

Ijọba orilẹede naa lo ti kede pe kawọn ologun lati apa ila oorun Africa o fi ilu wọn silẹ lopin ọdun yii, nitori wọn kuna lati fopin si ikọlu awọn agbebọn lati igba ti wọn ti de ni ọdun kan din diẹ sẹyin.

Amojuto eto idibo

Aworan ipolongo ibo fun Moise Katumbi to jẹ ọkan lara awọn alatako gboogi fun Aarẹ Tshisekedi

Oríṣun àwòrán, AFP

Ajọ eleto idibo orilẹede naa lo yẹ ko da duro, ko wa lominira, ko si maa ṣe ojuṣe rẹ nibamu pẹlu ofin ilẹ naa.

Igbimọ ẹlẹnimẹẹdohun ọhun lo ye mu ipese eto idibo to ba ilana oṣelu awaarawa mu bii afojusun wọn.

Ẹwẹ, ajọ naa ni awọn araalu ti n bẹnu atẹ lu pe aarẹ rẹ, Denis Kadima, sunmọ ijọba ju boṣe yẹ lọ. Wọn n bẹru pe bi oun ati Aarẹ Tshisekedi ṣe jijọ wa lati ẹya kan naa lee mu i ajọ naa o maa le duro ṣinṣin.

Ni tirẹ, Ọgbẹni Kadima lo n ṣe atẹnumọ rẹ pe ajọ naa yoo ṣe ohun to yẹ.

Ajọ iṣọkan ilẹ Europe lo ti yọwọ ninu amojuto idibo naa latari aigbọraẹniye to wa laarin awọn ati ijọba DRC lori ohun ibaraẹnisọrọ ti wọn nilo. Awọn onwoye ibo mẹjọ pere ni ajọ naa yo fi moju to idibo ọhun ni Kinshasa nikan.

Tẹlẹ ri, ajọ iṣọkan ilẹ adulawọ, awọn ẹlesin atawọn ajọ to n ja fẹtọ ilu ni wọn maa n ko awọn onwoye ibo sigboro.

Igba wo ni esi ibo yoo jade?

Aworan Martin Fayulu tawọn kan nigbagbọ pe oun lo jawe olubori nibi idibo ọdun 2018

Oríṣun àwòrán, AFP

Gẹgẹ bi ajọ eleto idibo ṣe fi lede, esi ibo lo yẹ ko jade ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila.

Ti esi ba jade ṣaaju ọjọ yii, wọn yoo kede rẹ. Amọ ninu awọn eto idibo to ti waye sẹyin, ajọ eleto idibo kii kede esi idibo laabọ – wọn maa n duro ti wọn yoo fi ka gbogbo ibo tan jakejado orilẹede naa ki wọn too kede ẹni to jawe olubori ni.

Aarẹ to ba gbegba oroke ni wọn yoo bura wọle fun ni ogunjọ, Oṣu kini, ọdun to n bọ.