Àwọn agbébọn jí Baálẹ̀ àtàwọn mẹ́tàlélógún míràn gbé ní Taraba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilu Pupule nijọba ibilẹ Yorro, nipinlẹ Taraba lo gbalejo awọn agbebọn lọjọ Iṣẹgun nibi ti wọn ti ji adari ilu naa atawọn mẹtalelogun miran gbe.
Awọn agbebọn naa ni wọn ni wọn ya wọ ilu naa loru ọganjọ, ti wọn si yii ka.
Olugbe ilu naa kan to ba BBC sọrọ wi pe awọn ko moye awọn agbebọn naa nitori pe wọn pọ gan.
Ọkunrin naa wi pe “oru ni wọn de ti wọn bẹrẹ si nii yinbọn, ti wọn si n wọ ile si ile lati mu awọn ti wọn fẹẹ mu.
“Wọn mu baalẹ wa atawọn kan ninu aafin rẹ. Wọn tun mu lemamu kan ati alufaa ijọ meji.
“Igba akọkọ ti wọn maa wa kọ leleyii, a ti to igba mẹrin ọtọọtọ ti wọn ti n wa.”
O fi kun pe awọn agbebọn naa ja awọn ibutaja kan ti wọn si ji ounjẹ ati ohun mimu ko lọ pẹlu.
Agbẹnusọ ajọ ọlọpaa nipinlẹ naa, Abdullahi Usman, wi pe ni kete ti wọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni kọmiṣọna ajọ ọlọpaa nipinlẹ ọhun paṣẹ ki awọn aṣayan ọlọpaa o bẹrẹ si nii tọ ipasẹ awọn ajinigbe naa.
O wi pe awọn ọlọpaa naa lo n sa gbogbo ipa wọn lati doola ẹmi awọn ti wọn ji gbe ọun.
Ẹwẹ, awọn olugbe ilu naa ti juwe ijinigbe yii bii eyi to buru ju mẹta to ti ṣẹlẹ sẹyin lọ, to si tun kọ wọn lominu gidi.
Ọrọ eto aabo lo ti dẹnukọlẹ lawọn aaye kan lapa ariwa orilẹede Naijiria nibi ti ijinigbe ati iwa ipa awọn agbebọn ti n peleke sii lojoojumọ.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba n gbiyanju lati dẹkun gbogbo iwa kotọ yii, ipa wọn ni ko i tii so eso rere.












