Olórí ìjọ àti àwọn márùn-ún míràn rí ẹ̀wọ̀n he l’Ondo

Aworan Oluwambe Ojagbohunmi

Oríṣun àwòrán, The Holy Apostles' Church, Ayetoro/Facebook

Ileẹjọ giga ipinlẹ Ondo kan, to filu Akure ṣe ibujoko, lo ti ran awọn mẹfa kan lẹwọn ọdun meji fun dida omi alaafia ilu Ayetoro nijọba ibilẹ Ilajẹ nipinlẹ naa ru.

Awọn mẹfa naa ni Oluwambe Ojagbohunmi, to jẹ olori ijọ The Holy Apostles' Church, Aiyetoro, to si tun pera rẹ ni adari ilu naa, Victor Akinluwa, Isaac Ikuyelorimi, Lawrence Lemamu, George Eyekole ati Segun Okenla.

Awọn mẹfẹẹfa naa ni ọlọpaa mu ni ọjọ kọkanla oṣu kini, ọdun 2018 lori ẹsun pe awọn ni wọn wa nidii rogbodiyan to bẹ silẹ nilu Ayetoro leyi to fa ipalara fawọn kan, ti ọpọ dukia si bajẹ.

Ni ibẹrẹ igbẹjo, ẹsun mẹwa ni agbẹjọro olupẹjo, Babatunde Falodun ka si wọn lẹsẹ nileẹjọ to fi mọ iwa ipa, idaluru, idigunjale ati biba dukina onidukia jẹ.

Gẹgẹ bi Falodun ṣe wi, awọn ẹṣẹ yii lo tako alakalẹ abala kọkanleaadọtalenirinwo ninu ofin ọdaran, idi kẹtadinlogoji, apa kini, ninu ofin ipinlẹ Onodo ti ọdun 2026.

Ẹwẹ, ọkan ninu awọn ọdaran naa, George Eyekole, ni wọn fi ẹsun igbiyanju lati paniyan kan nitori o yinbọn mọ ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Olu Obolo, ti eleyi si tako alakalẹ abala okoolelọọdunrun ninu ofin ọdaran, idi kẹtadinlogoji, apa kini, ninu ofin ipinlẹ Onodo ti ọdun 2026.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọdaran naa wi pe awọn ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan wọn, ileẹjọ dẹbi ru wọn lori mẹta ninu awọn ẹsun naa to nii ṣe pẹlu biba dukia jẹ.

Ninu idajọ rẹ, Onidajọ David Kolawole wi pe awọn ọdaran naa jẹbi biba dukia onidukia jẹ, o si ni ki wọn lọọ fi ẹwọn ọdun meji gbara abi ki wọn sanwo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta naira.

Bakan naa lo ni ki onikaluku wọn o san ẹgbẹrun lọna ọọdunrun naira gẹgẹ bii owo gba ma binu fun awọn dukia ti wọn bajẹ.

Ẹwẹ, Eyekole ni ko nii ni anfaani lati san owo itanran ti awọn ẹgbẹ rẹ fẹe san ni bi adajọ tun ṣe fun-un ni ọdun marun miran pẹlu iṣẹ aṣekara nitori igbiyanju lati paniyan lakoko laasigbo naa.

Gbogbo awọn ọdaran naa ni Onidajọ Kolawole ni ki wọn tọwọ bọ iwe adehun lati gba alaafia laaye ninu ilu naa.

Kolawole fi kun pe, awọn ọdaran naa ni yoo foti faya ti idarudapọ kọkan ba tun waye ninu ilu naa lẹyin ti wọn ba sanwo itanran ti wọn si pada saarin ilu, ati pe owo itanran naa ni yoo di didapada fun wọn.