Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ìyá àgbà tó n ta ẹ̀yà ara èèyàn nípìnlẹ̀ Ogun

Ọkan lara awọn afurasi

Oríṣun àwòrán, Screenshot/TVC

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti tẹ iya agba kan, ati awọn mẹrin mii fun ẹsun pe wọn n ta ẹya ara eniyan.

Nigba to n fi oju awọn afurasi ọdaran naa han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abeokuta, kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Abiodun Alamutu, sọ pe abule kan ti wọn n pe ni Joju, nipinlẹ naa ni ọwọ ti tẹ wọn.

O ni awọn bẹrẹ igbesẹ lori ọrọ wọn nigba ti awọn sakiyesi pe ọpọ eeyan n di awati nipinlẹ naa.

Iya agba naa sọ pe o ti to ọdun meji ti oun ti n ṣe okoowo tita ati rira ẹya ara eniyan.

O ni ṣugbọn, ori eeyan mẹwaa pere ni oun ti ta laarin ọdun meji naa.

Lara awọn ẹya ara eeyan ti wọn ba ni akata awọn afurasi naa ni kindinrin, ori, ẹdọ ati awọn ifun.

Ọkan lara awọn ọlọpaa lo dibọn bi onibara to fẹ ra ẹya ara eniyan, pẹlu adehun lati ra ori eeyan ni ẹgbẹrun lọna ọgọfa Naira, ko to o di pe ọwọ tẹ wọn.

Kọmiṣọnna ọlọpaa sọ pe pupọ ninu awọn ẹya ara ti awọn ba lọwọ awọn afurasi naa lo ṣi tutu.

Lara awọn afurasi marun-un naa naa ni awọn meji to ma n gbẹ iboji oku.

Ọkan lara awọn afurasi naa sọ pe ẹgbẹrun mẹwaa Naira ni oun ma n ra ori eeyan lọwọ obinrin naa. O ni oun fi ma n joogun ni.

Bakan naa ni ẹni to ma n ba wọn gbẹlẹ ni iboji oku sọ pe awọn ma n ge ẹya ara oku, ẹgbẹrun mẹta Naira si ni wọn ma n gba.

Nigba ti ọwọ awọn ọlọpaa tẹ , iroyin sọ pe obinrin kan ṣoṣo to wa laarin wọn sare ju ẹran kan sẹnu, lati mu ki awọn ọtẹlẹmuyẹ ro pe ẹran eeyan kọ ni wọn ka mọ wọn lọwọ.