ìjọba Naijiria kéde ẹ̀dínwó 50% lórí owó ọkọ̀ àti ìrìnàjò ọ̀fẹ́ nínú rélùwè lásìkò ọdún

Oríṣun àwòrán, reuters
Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu adinku ida aadọta lori iye owo ọkọ ti awọn ọmọ Naijiria to ba rinrinajo lasiko ọdun.
Eto ẹdinwo naa yoo waye laarin ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila, ọdun 2023, si ọjọ kẹrin, oṣu Kinni, ọdun 2024.
Ninu ikede ti oludamọran fun aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, fi sita, wọn ni awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ rinrin ajofun ọdun, le bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelogun, ki wọn o si san ilaji owo to yẹ ki wọn o san.
O ni ijọba apapọ ni yoo san ida aadọta to ku fun awọn ileeṣẹ ọkọ to ba ko ero.
Bakan naa ni wọn le rinrinajo wọn lai san owo kankan ti wọn ba wọ ọkọ reluwe lasiko ọdun.
Ọgbẹni Onanuga ṣalaye pe irinajo lati ipinlẹ kan si ipinlẹ miran ni anfaani yii wa fun.
“Ijọba apapọ yoo ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ ọkọ to jẹ aladani, ẹgbẹ awọn awakọ, ati ileeṣẹ ọkọ reluwe ni Naijiria, lati fun awọn ọmọ Naijiria ni awọn anfaani yii lai mu inira dani
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post








