Iléẹjọ́ Supreme kéde Peter Mbah gẹ́gẹ́ bí ẹni tó borí ìbò gómìnà ní Enugu

Aworan Gomina Peter Mbah

Oríṣun àwòrán, Others

Ileẹjọ to ga julọ lọrilẹede Naijiria ti gbe idajọ rẹ kalẹ lori ipe to tako iyansipo Peter Mbah gẹgẹ Gomina ipinlẹ Enugu.

Igbimọ ẹlẹni marun un lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ Ẹti, ti wọn si wọgile ipe oludije sipo ẹgbẹ oṣelu Labour, Chijioke Edeoga, to ni magomago wa ninu bi Mbah se bori eto idibo gomina ninu oṣu kẹta ọdun 2023.

Saaju ni ileẹjọ to n gbọ awuyewuye nipa eto idibo ati ileẹjọ kotẹmilọrun ti gbe idajọ kalẹ pe Mbah gẹgẹ bi ẹni to bori ninu eto idibo gomina.

Sugbọn eyi ko tẹ ẹgbẹ oṣelu LP ati Edeoga, ti wọn si mori lọ ileẹjọ.

Adajọ Muhammed Garba lo lewaju awọn igbimọ ẹlẹni marun un awọn adajọ naa.

Bakan naa ni ileẹjọ tun wọgile ẹsun iwe ẹri agunbanirọ NYSC, eyi ti Edeoga gbe wa si ileẹjọ lati fi tako esi idibo to gbe Mbah wọle gẹgẹ bi gomina.

Mbah lo jẹ oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ninu eto idibo to waye ni Ọjọ kejidinlogun oṣu kẹta ọdun 2023.

Ni ọjọ kẹwaa oṣu kọkanla ọdun 2023, Ileẹjọ kotẹmilọrun gba idajọ kalẹ pe, to si pẹlu idajọ ileẹjọ to n gbọ awuyewuye lori esi idibo pe Mbah kọ lo wọle gomina ipinlẹ Enugu.